Leyin ifehonu han, ijoba din owo ileewe awon akekoo Fasiti Adekunle ku

Spread the love

Bo tilẹ jẹ pe ijọba ti din owo ti wọn ni ki awọn akẹkọọ ileewe giga Fasiti Adekunle Ajasin maa san ku, sibẹ, awọn akẹkọọ naa ni ti ni o digba tawọn ba ṣepade laarin ara awọn kawọn too mọ boya awọn yoo gba owo tuntun naa wọle. Bẹẹ ni awọn mẹsan-an foju bale-ẹjọ lori ifẹhonu han to waye lori owo ileewe ọhun.

Ko din lawọn eeyan mẹsan-an ti wọn foju bale-ẹjọ laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii, lori ẹhonu tawọn akẹkọọ Fasiti Adekunle Ajasin, Akungba Akoko, ṣe lọsẹ to kọja nitori afikun tijọba ṣe sowo ileewe wọn.

 

Awọn mẹsan-an ti ki i ṣe akẹkọọ to n jẹjọ lọwọ naa ni: Temitọpẹ Ajayi, Ọlalẹyẹ Oluwafẹmi, Ibrahim Hammed, Oluwajọba Damilọla, Adeleke Blessing, Okechukwu Dim-Anozie, Ogundele Fẹmi, Muyideen Ọmọnigbẹyin ati Oluwaṣọla Ṣẹsan.

 

Ẹsun mẹrin ọtọọtọ, ninu eyi ti a ti ri igbimọ pọ lati pejọ pọ lọna aitọ, dida omi alaafia ilu ru, didi awọn araalu lọwọ lati lọ sẹnu iṣẹ oojọ wọn ati didi oju ọna tawọn eeyan n gba kọja pa lọna ti ko bofin mu ni wọn fi kan awọn olujẹjọ naa lasiko ti wọn n fara han nile-ẹjọ majisreeti to wa l’Oke-Ẹda, niluu Akure.

 

Ẹsun mẹrẹẹrin ti wọn fi kan awọn olujẹjọ ọhun ni ọlọpaa to n ṣoju ijọba, Insipẹkitọ Adebiyi Abiọdun, sọ pe o lodi, to si tun ni ijiya to lagbara labẹ ofin ipinlẹ Ondo tọdun 2006.

 

Agbefọba ọhun ṣọ siwaju pe ki adajọ paṣẹ pe ki wọn ṣi fi gbogbo awọn olujẹjọ naa pamọ sọgba ẹwọn na, nitori pe ti adajọ ba fi tẹti si ibeere awọn agbẹjọro mẹtẹẹta to n gbẹnusọ fun wọn lati faaye beeli wọn silẹ, igbesẹ naa le pa igbẹjọ to n waye lara. Ọjọ mẹta lo sọ pe awọn akẹkọọ ọhun fi ṣewọde wọn lọsẹ to kọja, tawọn ọlọpaa ko si yọ wọn lẹnu lọjọ kin-in-ni ati ọjọ keji.

 

Igba to di pe awọn olufẹhonu han ọhun fẹ maa ba nnkan jẹ laarin ilu lọjọ kẹta ti wọn ti bẹrẹ lo sọ pawọn ọlọpaa too gbe igbeṣẹ, ti wọn si fi panpẹ ọba gbe awọn mọkandinlaaadọta ninu awọn olufẹhonu han naa.

 

Ogoji ninu awọn ti wọn fi panpẹ ofin gbe naa lo sọ pe wọn ti yọnda ki wọn maa lọ, lẹyin ti iwadii ti wọn ṣe ti fidi ẹ mulẹ pe akẹkọọ ni wọn.

 

O lawọn mẹsan-an ti wọn ko wa sile-ẹjọ naa ki i ṣe akẹkọọ, bẹẹ ni wọn ko ni nnkan kan i ṣe pẹlu Fasiti Adekunle Ajasin, idi niyi to sọ pawọn ọlọpaa fi ko wọn wa sile-ẹjọ lati le waa foju wina ofin.

 

Lẹyin ọpọlọpọ awuyewuye laarin agbenusọ ijọba atawọn agbẹjọro to n gbẹnusọ fawọn olujẹjọ naa ni Abilekọ Mary Adeyanju to n gbọ ẹjọ ọhun faaye beeli ẹni kọọkan wọn silẹ pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira ati oniduuro kọọkan, ko too di pe o sun igbẹjọ mi-in si ọjọ keji, oṣu karun-un, ọdun ta a wa yii.

Lati aarọ kutu ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja ni ọgọọrọ awọn akẹkọọ Fasiti Adekunle Ajasin, niluu Akungba Akoko, ti tu jade lati tako bi ijọba ipinlẹ Ondo, labẹ iṣakoso Gomina Rotimi Akeredolu, ṣe deede ṣafikun owo ileewe ti wọn n san lati ẹgbẹrun marundinlogoji naira si ẹgbẹrun lọna ẹgbẹsan naira.

 

Awọn akẹkọọ to n kẹkọọ nipa imọ eto ẹkọ, ẹsin igbagbọ, ati eto iroyin ni wọn ni ki wọn maa sanwo to to bii ẹgbẹrun lọna ọgọfa naira, nigba ti wọn ni kawọn to ṣẹṣẹ fẹẹ wọle sawọn ẹka ẹkọ yii maa san ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira.

 

Ẹgbẹrun lọna aadọjọ naira ni wọn gbe owo awọn akẹkọọ imọ sayẹnsi si, nigba ti wọn lawọn to ṣẹṣẹ fẹẹ wọle lẹka ẹkọ naa yoo maa san ẹgbẹrun lọna ọgọsan-an naira.

 

Ni tawọn akẹkọọ to n kẹkọọ nipa imọ ofin, ẹgbẹrun lọna ọgọsan-an naira lowo tiwọn, nigba tawọn to ṣẹṣẹ feẹ wọle gbọdọ san ẹgbẹrun lọna igba naira.

 

Ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja lọ lọhun-un nijọba kede owo ileewe tuntun naa, ti wọn si paṣẹ fawọn akẹkọọ lati wọle pada fun saa ẹkọ tuntun lọjọ Aje, Mọnde, to tẹle e, lẹyin bii oṣu mẹrin ti wọn ti kọkọ ti ileewe ọhun.

 

Dipo kawọn akẹkọọ naa wọle gẹge bii aṣẹ tijọba pa, niṣe ni wọn kora wọn jọ si oju ọna Ọba Adesida, niluu Akurẹ, ti wọn si bẹrẹ si i fẹhonu han. Awọn ọlọpaa lo waa fi tajutaju tu wọn ka ni nnkan bii aago mejila ọsan ọjọ naa.

 

Laaarọ kutu ọjọ keji lawọn akẹkọọ naa tun bẹrẹ ifẹhonu han ọhun lọtun, eyi ti wọn ṣe titi ilẹ fi ṣu lọjọ naa ki olukuluku wọn too gba ile wọn lọ.

 

Ọgọọrọ awọn iyalọja nipinlẹ Ondo lo darapọ mo awọn akẹkọọ ọhun lati fẹhonu han lọjọ kẹta ti i ṣe Ọjọru, Wẹsidee, ọṣe to kọja, ti wọn si lọ si ọfiisi gomina.

 

Ọfiisi gomina ni wahala mi-in tun ti bẹ silẹ laarin awọn olufẹhonu han naa atawọn ọlọpaa, ko too di pe awọn ọlọpaa tun fi tajutaju tu wọn ka, ti wọn si tun fi panpe ọba gbe eeyan mọkandinlaaadọta lara wọn.

 

Lẹyin eyi ni Gomina Akeredolu ṣepade pẹlu aṣaaju awọn akẹkọọ fasiti ọhun, nibi to ti ṣeleri ati wa nnkan ṣe lori ọrọ owo ileewe naa kiakia.

Lọjọ keji ipade yii ni Ijanusi Ọlawale to jẹ aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọ fasiti ọhun kede abajade ipade to waye laarin Gomina Akeredolu atawọn alaṣẹ fasiti ọhun.

 

O fidi ẹ mulẹ pe Gomina Akeredolu ti paṣẹ pe kawọn to n kẹkọọ nipa imọ ofin, sayẹnsi ati eto ọrọ aje maa san ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan naira gẹgẹ bii owo ileewe tuntun, nigba tawọn to n kẹkọọ nipa eto ẹkọ yoo maa san ẹgberun lọna ọgọrin naira pere.

Ki owo tuntun naa baa le rọrun fawọn akẹkọọ lati san, gomina fun wọn lanfaani ati sanwo naa lẹẹmeji.

 

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lo sọ pe awọn akẹkọọ fasiti ọhun yoo pade lati jiroro lori ọrọ owo tuntun naa, lẹyin ipade yii ni wọn yoo too le sọ boya wọn faramọ ọn tabi bẹẹ kọ.

(55)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.