L’Ekiti, ohun ti a n wi gan-an niyẹn

Spread the love

Igbakeji Gomina ipinlẹ Ekiti, Oloye Bisi Ẹgbẹyẹmi, ba awọn ẹgbẹ onimaaluu ṣepade lọsẹ to kọja, o si kilọ fun wọn pe Fulani onimaaluu ti wọn ba ba ibọn lọwọ rẹ, wọn yoo gbe e janto ni, wọn yoo si fi ofin mu un daadaa debii pe ko ni i bọ ninu rẹ. Ọkunrin naa sọ pe, “Fulani to ni oun n da maaluu to n gbe ibọn AK-47 kiri, ṣe maaluu lo fẹẹ fi da ni abi awọn eeyan lo fẹẹ fi pa. A ko ni i gba iru rẹ l’Ekiti yii o …” Ko ju bẹẹ lọ. Ma fi oko mi ṣe ọna mọ, ọjọ kan leeyan i ṣofin rẹ falagidi. Ohun to si ṣe yẹ ka ya ọrọ oṣelu kuro lara eto ati iṣẹ ijọba niyi. Oṣelu n ja fun ẹgbẹ tiwọn ni, ṣugbọn iṣelu, tabi iṣẹ ilu, wa fun gbogbo ilu, ki ijọba  ṣe daadaa fẹni gbogbo, ki wọn si mu eto idagbasoke ati ilọsiwaju ibi ti wọ ba wa ni oju iṣẹ pọnnbele. Ko si ẹni ti ko gbe oriyin fun Fayoṣe nigba to gbe eto naa kalẹ nijọsi, to ni Fulani to ba n da maaluu kiri igboro yoo ṣẹwọn. Awọn Fulani onimaaluu yii sa nigba naa, wọn si gbe jẹẹ. Amọ lẹsẹkẹsẹ ti wọn ri i pe Fayoṣe lọ lẹyin ti wọn dibo tan, wọn sare ko maaluu wọn pada, wọn ti ro pe ijọba APC ko ni i da wọn lọwọ duro lati ṣe ohun yoowu ti awọn ba fẹẹ ṣe. Bi nnkan ti bajẹ to niyẹn, bi awọn eeyan yii si ti ṣe n mu wa lọbọ to naa ree. Awọn eeyan yoo ro pe wọn ko gbọn, bẹẹ ọgbọn buruku n bẹ ninu wọn. Nigba ti ẹ ba ko maaluu tiyin, ti ẹ fi n jẹ oko oloko, ti oloko sọrọ ti ẹ yọbọn si i, tabi ti ẹ dunbu ẹ, ti ẹ fi tipa mu iyawo ẹ, ti ẹ ba a sun, ti ẹ fi tipa mu ọmọ ẹ ti ẹ ba a sun, ti wọn fẹjọ sun ọlọpaa, ti ọlọpaa ni ko si ohun ti oun fẹẹ ṣe, ti ijọba apapọ si gboju sẹgbẹẹ kan bii ẹni pe ko si ohun to ṣẹlẹ, to jẹ gbogbo ilakaka wọn bi wọn yoo ṣe gba gbogbo ilu fawọn onimaaluu Fulani yii ni, igba wo ni wahala ko ni i maa ṣẹlẹ kaakiri. Ṣebi ohun ti Fayoṣe ṣe ṣe ofin to ṣe nigba naa ree, ṣugbọn awọn oloṣelu fẹẹ tọwọ oṣelu bọ ọ, wọn fẹẹ ba kinni naa jẹ. Ni bayii tijọba tuntun yii ti binu, tawọn naa si ti sọ pe ko saaye ki Fulani lọọ sọ ara wọn di amunisin l’Ekiti, ohun to daa gbaa ni. Bi Ẹgbẹyẹmi ti sọ naa ni ki ijọba wọn ṣe, ki wọn gba araalu atawọn agbẹ to n roko wọn jẹun lọwọ awọn ika buruku yii, ki wọn jẹ ki wọn mọ pe ọmọ ki i pa ọmọ jaye.

                                                                         

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.