Leganes le ra Omeruo patapata laipẹ

Spread the love

Lati ọsẹ to kọja tẹgbẹ agbabọọlu Leganes, ilẹ Spain, ti ra Martin Braithwaite patapata lati Middlesbrough, ilẹ England, lawọn kan ti n sọ pe ki wọn ra ọmọ ilẹ wa nni, Kenneth Omeruo.

Ẹni to ṣaaju awọn to fẹ ki igbesẹ naa waye ni Dimitris Siovas toun ati Omeruo jọ n gba ọwọ ẹyin ni kilọọbu naa. Nnkan to sọ ni pe Omeruo nikan lo ku ki ikọ ẹgbẹ naa fi duro deede, o si ke sawọn alaṣẹ lati tete wa nnkan ṣe.

Eyi waye latari bẹbẹ ti Omeruo ṣe fun Leganes laarin saa kan to lo pẹlu wọn, nnkan tawọn ololufẹ rẹ si n wa ni bi yoo ṣe jokoo si kilọọbu kan dipo ki Chelsea maa ta a kiri.

Ọdun 2012 ni Omeruo ti balẹ si Chelsea, ilẹ England, lati Standard Liege ilẹ Belgium, latigba naa ni wọn ti n ya awọn kilọọbu kaakiri. O ti ṣe bẹbẹ nilẹ Netherland, England ati Turkey ko too lọ si Spain, ko si gba bọọlu fun Chelsea ri.

O ti kọkọ gba bọọlu fun ikọ ọjẹ-wẹwẹ Naijiria ko too ṣe bẹbẹ fun Flying Eagles, 2013 ni wọn si kọkọ lo o ni Super Eagles.

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.