Lẹẹkan si i: ẸGBẸ PDP NAA YOO TUN FỌ SI WẸWẸ

Spread the love

Nibi ti ọrọ de duro laarin awọn oloṣelu ilẹ yii bayii, yoo ṣoro pupọ ki ẹnikẹni too sọ pe ẹni bayii ni yoo wọle gẹgẹ bii aarẹ Naijiria lọdun 2019 to n bọ yii o. Loootọ awọn oniṣẹẹyanu loriṣiiriṣii, paapaa awọn pasitọ ni ṣọọṣi ti wọn n riran, ti kede awọn orukọ kan pe awọn ni wọn yoo wọle, ṣugbọn nitori pe ọpọlọpọ awọn iṣẹ iran ti wọn n jẹ yii, pupọ ninu wọn naa kan n ronu lori ọrọ to n lọ lati fi sọ pe awọn riran ni, ọpọ eeyan ko gba wọn gbọ, paapaa nigba to di pe awọn oloṣelu n fi ẹgbẹ wọn silẹ bọ sinu ẹgbẹ mi-in. Ohun ti awọn kan n ro bayii ni pe bi ija ba doju ẹ lọdun to n bọ, ẹgbẹ PDP yoo ta biọbiọ pupọ, bi awọn APC ko ba si mura daadaa, ki wọn tun ile wọn to, afaimọ ki ẹgbẹ PDP to n tunra mu yii ma ti wọn danu, ti wọn yoo si gba ipo aarẹ lọwọ Muhammadu Buhari to jẹ tiwọn.

Ohun ti awọn ti wọn mọ nipa oṣelu n sọ bayii ree, nitori ibinu ti wọn ri ati ipinnu awọn ti wọn n rọ lọ sinu ẹgbẹ naa, ti wọn n ni ko si ohun meji ti awọn n tori rẹ lọ ju lati le Buhari danu, ki awọn si da ijọba pada si ti dẹmokiresi, yatọ si ijọba ko-moju-ẹni-kan ti APC n ṣe. Awọn ti wọn ti n woye oṣelu ilẹ yii lati bii ọjọ meloo waa sọ fun Alaroye pe eleyii ṣee ṣe daadaa, ṣugbọn kọkọrọ kan lo wa nibẹ ti yoo ba eyin aja jẹ. Awọn yii ṣalaye pe ninu PDP funra rẹ ni kinni naa yoo ti daru wa, wọn ni bi ẹgbẹ PDP ti ṣe fọ ni ọdun 2013 si 2014, to fi di pe APC gbajọba kuro lọwọ wọn, afaimọ ki ẹgbẹ naa ma tun fọ bẹẹ lẹẹkan si i. Bi ẹgbẹ naa ba si ti fọ pẹẹ ni agbara yoo tun pada sọwọ APC, ẹgbẹ PDP ko si ni i rọwọ mu ni Naijiria fun igba pipẹ. Aarin awọn ti wọn fẹẹ du ipo aarẹ lati inu ẹgbẹ naa nija yoo ti bẹrẹ.

Bi a ti n sọ yii, awọn eeyan nla nla mẹfa kan wa ti wọn ti pada sinu PDP, wọn ko si tori ohun meji pada sibẹ ju lati du ipo aarẹ lọ. Bi awọn eeyan yii yoo ti ṣe e ti ọrọ naa ko ni i dija lawọn eeyan lawọn ko ti i mọ, nitori ipo kan ṣoṣo naa lo wa, ṣugbọn awọn alagbara mẹfa ni wọn fẹẹ fa a mọ ara wọn lọwọ, ko si sohun to sọ pe awọn alagbara naa ko ni i pọ ju bẹẹ lọ bo ba ya. Ẹni akọkọ to ti tete mu irin-ajo yii rin ni Abubakar Atiku, igbakeji aarẹ ilẹ wa nigba kan. Lati ọdun 2007, iyẹn ọdun kọkanla sẹyin, lọkunrin yii ti n mura lati di aarẹ, idi si ree to fi fi ẹgbẹ PDP yii silẹ nigba naa, to rin mọ awọn Aṣiwaju Bọla Tinubu l’Ekoo, ti wọn si jọ da ẹgbẹ AC silẹ. Atiku ja raburabu nigba naa, ṣugbọn gbogbo ọna ni Oluṣẹgun Ọbasanjọ to jẹ ọga Atiku lo lati gbegidina fun un, o ni ko yẹ lẹni ti i ṣe aarẹ Naijiria.

Atiku ko pẹ to fi pada sinu PDP, nigba to si di ọdun 2011, oun ati Goodluck Jonathan ni wọn tun jọ du kinni naa lorukọ ẹgbẹ PDP, Jonathan si tun fibo da a jokoo, nigba to si di ọdun 2013 to tun ri i pe ibi kan naa ni ọrọ tun fẹẹ lọ, o ko awọn eeyan kan jade ninu ẹgbẹ yii, wọn si jọ da APC silẹ. Oun ati Buhari pẹlu awọn mẹta mi-in ni wọn jọ fa tikẹẹti ẹgbẹ APC lati du ipo aarẹ mọ ara wọn lọwọ, Atiku si na kinni kan, owo ni. O nawo naa debii pe diẹ bayii ni Buhari fi ṣaaju rẹ, ti wọn si fi fa a kalẹ. Igba ti ko tun jọ pe Atiku yoo ri nnkan kan ba jade ninu APC lo fi fibinu kuro nibẹ lọdun to kọja yii, lati igba naa lo si ti n sọ pe oun pada wa sinu ẹgbẹ naa, oun yoo si du ipo aarẹ lorukọ wọn. Itumọ eyi ni pe ko sohun meji ti Atiku n tori rẹ ti inu ẹgbẹ kan bọ sinu ekeji ju lati di aarẹ Naijiria lọ, aṣaaju si ni ninu PDP bayii.

Ki i ṣe oun nikan lo fẹẹ du ipo aarẹ yii lorukọ PDP, Rabiu Kwankwaso naa wa nibẹ o. Bi oloṣelu kan ba wa ti wọn fẹ tiẹ gan-an ni Kano ati gbogbo agbegbe rẹ, Kwankwaso ni. Ni Kano yii ni Buhari ti ni ibo to pọ julọ ni 2015, ọkunrin yii lo si ṣeto bi ibo pupọ bẹẹ ṣe jẹ ti Buhari. Oun naa ti ṣe gomina ipinlẹ Kano lẹẹmeji, o si ti ṣe minisita, ipo pataki to si ro pe o ku foun ni lati ṣe olori Naijiria. Iyẹn lo ṣe jade ni 2014, to si ba Buhari ati Atiku du kinni naa ninu ẹgbẹ APC. Igba to ri i pe ko saaye foun ninu ẹgbẹ APC lo ṣe ko ẹru rẹ pada sinu PDP, bẹẹ ẹgbẹ to n ṣe lati ọjọ yii ki wọn too jọ rọ wa sinu APC ni. Ko si ohun meji ti oun naa tori rẹ wa sinu PDP bayii bi ko ṣe lati du ipo aarẹ.

O pẹ ti Bukọla Saraki ti n le ipo aarẹ yii bo tilẹ jẹ pe ko sọ ọ sita. Gbogbo awọn ti wọn yi i ka ni wọn ti mọ pe ko sohun ti ọkunrin naa ro pe o ku ninu oṣelu oun ju ki oun di aarẹ Naijiria lọ. Ni tododo, Saraki ko ni ohun meji lọkan bayii ju bi oun yoo ṣe gba ijọba lọwọ Buhari lọ, ti oun yoo si di aarẹ tuntun. Oun naa ti ṣe gomina Kwara lẹẹmeji, ko too di igba naa, o ti ṣe amugbalẹgbẹẹ fun aarẹ Ọbasanjọ nigba ti oun fi ṣejọba. O ti wa nile-igbimọ aṣofin lati ọdun 2011, oun si ni olori ile-igbimọ naa bayii, ipo aarẹ lo si wu u, ohun to si ṣe kuro ninu PDP to bọ sinu APC tẹlẹ niyẹn, iyẹn naa lo si tun ṣe pada sinu PDP bayii.

Ọkunrin kan wa ti wọn n pe ni Ahmed Makarfi. Gomina Kaduna ni tẹlẹ, ẹẹmeji loun naa ti di ipo naa mu, lẹyin naa lo si tun ṣe minisita. Oun ni wọn ṣẹṣẹ fi ṣe adele alaga PDP laipẹ yii, o si ti  sọ pe oun naa yoo du ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ wọn. Ọrọ tiẹ tilẹ yatọ, nitori lati ọjọ to ti wa to ti n ṣe oṣelu, iyẹn lati 1999 ti oṣelu tuntun yii ti bẹrẹ, Makarfi ko kuro ninu ẹgbẹ PDP ri, ẹgbẹ to n ṣe lati ọjọ yii wa ni. Awọn aṣaaju ẹgbẹ ti waa gba pe bi ipo naa ba tọ si ẹnikẹni ju, ọkunrin naa lo tọ si, nitori ẹni kan naa to duro ṣinṣin ninu ẹgbẹ, ẹni ti ko ṣe agbere oṣelu kaakiri ni. Makarfi ti jade bayii pe oun yoo du ipo aarẹ.

Ọmọ ẹgbẹ PDP naa ni Gomina ipinlẹ Sokoto, Aminu Tabuwal, olori ile-igbimọ aṣofin kekere ni tẹlẹ. Ni 2014 lo kọyin si Aarẹ Goodluck Jonathan, to si n ba awọn Tinubu ṣe ninu ẹgbẹ alatako, bẹẹ ko ti i kuro ninu PDP nigba naa. Ọrẹ oun ati awọn Tinubu le debii pe wọn ti ro pe wọn yoo fa a kalẹ lati du ipo aarẹ ni. Ọkunrin naa ti n wa si Eko, o ti n ba awọn iyalọja jo kaakiri, ti awọn naa si ti n pariwo Tambuwal. Lojiji loun naa wọ inu ẹgbẹ APC, o ni Jonathan ko faaye gba awọn ninu PDP. Igba ti wọn dibo lo du ipo gomina ipinlẹ Sokoto, ibẹ lo si wa bi a ti n sọ yii. Ṣugbọn oun naa fẹẹ di aarẹ, o si ti kuro ninu APC, o ti wa si PDP pada, o ni oun lawọn aye fẹran julọ.

Lẹyin awọn oloṣelu nla mẹrin yii lo ku Sule Lamido, oloṣelu lati Jigawa, o pẹ toun naa ti wa lẹnu oṣelu, inu PDP lo si wa lati ọjọ yii ti ko rebikan. O ti ṣe minisita labẹ Ọbasanjọ, lẹyin naa lo si ṣe gomina ipinlẹ Jigawa lati 2007 titi di ọdun 2015. Oun naa ni oun loun lẹtọọ lati du ipo aarẹ ninu PDP, ẹgbẹ ti oun ti n ṣe lati ọjọ yii wa. Bẹẹ ni Gomina ipinlẹ Gombe to wa nibẹ bayii, Ibrahim Dankwabo, naa loun ni ohun to yẹ ki eeyan ni lati du ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ awọn. O si kawe loootọ o, awọn yunifasiti nla nla lo lọ, o si gba oye ọmọwe. O ti ṣiṣẹ ni Central Bank, bẹẹ lo si ṣe olori aṣiro owo fun gbogbo Naijiria, lẹyin naa lo di gomina Gombe ni 2011. Oun naa lọjọ ori rẹ kere ju, ọmọ ọdun mẹrindinlọgọta loun.

Lẹyin awọn yii lo tun ku awọn ogunlọgọ ti wọn ni awọn yoo dupo yii, iyẹn lawọn eeyan si ṣe sọ pe lọjọ ti wọn ba ti di ibo abẹle wọn, lọjọ naa ni ẹgbẹ PDP yoo tun fọ si wẹwẹ lẹẹkan si i. Ṣugbọn ko si ẹni to mọ bi oku aja yoo ṣe tun jẹko o, o digba naa ni!

 

(82)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.