Lẹẹkan si i, ẹ ro kinni yii wo daadaa kẹ ẹ too ṣe e

Spread the love

Awọn ti wọn fẹẹ du ipo gomina ipinlẹ Ọṣun lorukọ ẹgbẹ APC ti n lọ bii ọgbọn bayii o. Iyanu lo tiẹ jẹ pe gbogbo wọn lo ri owo ti wọn ni ki wọn san lati fi gba fọọmu, ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta (500,000) Naira. Owo kekere kọ ni, iyẹn si fihan pe awọn ti wọn fẹẹ ṣe gomina naa ko mu kinni naa ni kekere, gbogbo wọn lo mura si i. Ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira ki i ṣe owo ti eeyan le fi tafala, ẹni to ba na iru owo bẹẹ mọ ohun to fi i ṣe. Bẹẹ ninu gbogbo wọn yii naa, ẹni kan naa ni wọn yoo mu. Iyiọla Omiṣore paapaa ti kuro ninu ẹgbẹ PDP nigba to roye pe oun ko fẹẹ ri ọwọ mu ninu ẹgbẹ naa, o si ti lọ sinu SDP. Ko sohun meji to wa lọ sibẹ ju ipo gomina yii naa lọ. Bẹẹ lawọn ti PDP naa ko sinmi: Sẹnetọ Ademọla Adeleke ti n pariwo kiri ipinlẹ naa bayii pe oun ko fẹ nnkan meji mọ, gomina loun fẹẹ ṣe. Ko sohun to buru ninu ki gbogbo wọn di gomina, eyi ti ko kan dara ni ki wọn di gomina tan ki wọn maa sọ katikati lẹnu. Ẹni ti ko ba mọ ko lọọ gbe iwe Ọṣun ati eto ọrọ aje ati ti inawo rẹ lasiko yii, ko wo iye gbese ti gomina to n lọ yii jẹ, ko wo iye iṣẹ ti wọn ko ti i ṣe tan to wa nilẹ, ko si wo awọn gbese ti wọn jẹ awọn araata ti wọn yoo maa fa owo rẹ yọ ninu owo to ba n wọle l’Ọṣun, lẹyin to ba wo gbogbo ẹ tan ni ki tọhun too maa leri tabi nawo lati di gomina. Ki i ṣe ki eeyan wọle tan ko waa maa pariwo pe oun ko mọ pe gbese ti wọn jẹ l’Ọṣun to bayii, oun ko mọ pe bayii ni nnkan ṣe bajẹ to. Ki onikaluku la oju rẹ silẹ bayii ko si lo ọpọlọ rẹ, ko fi wadii ohun to n lọ ati ohun to fẹẹ ṣe. Eyi ti awọn ara Ọṣun jiya yii to gẹẹ, Arẹgbẹṣọla si ti ṣe iwọnba to le ṣe, ẹni ti yoo mu nnkan dara, ti ohun gbogbo yoo bọ sipo ni ipinlẹ naa nilo bayii o. Amọ gbogbo awọn ti wọn n sare kiri yii, meloo lo mọ ohun to n ṣẹlẹ ninu wọn, meloo lo mọ ohun ti wọn n ṣe nileeṣẹ gomina, eeyan meloo lo mọ nipa ọrọ aje ati ọna ti eeyan le fi ṣejọba. Ariwo ọja lasan lawọn n gbọ: ariwo pe ẹni ba jẹ gomina yoo lowo lọwọ, yoo maa gun mọto ọfẹ, awọn ọlọpaa yoo si maa halẹ mọ awọn mẹkunnu ti wọn ba fẹẹ sun mọ ọn. Ohun ti ọpọlọpọ wọn fẹẹ tori rẹ ṣe gomina niyẹn. Ṣugbọn aye asiko yii ko ni i ri bii ti atẹyinwa, ẹni to ba de ipo gomina to sọ katikati, epe lawọn araalu yoo maa fi i ṣẹ, epe naa yoo si ja lori rẹ dandan. Ẹyin tẹ ẹ fẹẹ ṣe gomina Ọṣun, ẹ ro o daadaa o!

(36)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.