Lẹyin ti wọn ba a lo pọ fun odidi ọjọ meji, ori ko Bọsẹ yọ lọwọ awọn ajinigbe n’Ibadan

Spread the love

Ọmọdebinrin kan, Adeniyi Abọsẹde, ko le da rin funra ẹ mọ, awọn ajinigbe ti fẹẹ fi ibasun han an leemọ, fun odidi ọjọ meji to lo lọdọ wọn, awọn gende ọkunrin mẹrin ni wọn n fipa ba a laṣepọ. O ku diẹ ki ẹmi ẹ bọ mọ wọn lọwọ lori ko o yọ.

 

Abọsẹde, ẹni ta a fi ojulowo orukọ ẹ bo laṣiiri lọga ẹ ran lati lọọ tọju owo kan to jẹ miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna irinwo Naira (N1.4M) sileefowopamọ kan  to wa laduugbo Dugbẹ, n’Ibadan, lo ko sọwọ awọn ajinigbe ọhun ni nnkan bii aago mọkanla aabọ aarọ ti wọn si ji i gbe e lọ lẹyin ti wọn ti fi oogun abẹnu gọ̀ǹgọ̀ mu un níyè lọ.

Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Shina Olukolu, fidi ẹ mulẹ pe Aboṣẹde ko ti i ko owo naa de banki to ti kagbako awọn ẹniibi naa, ti wọn si gbowo ọhun lọwọ ẹ ki wọn too tun gbe oun funra rẹ lọọ de mọlẹ nibuba wọn.

 

Iwadii Alaroye fidi ẹ mulẹ pe laduugbo ti wọn n pe ni Ireakari, nitosi Nalende, nigboro Ibadan, lawọn ọlọpaa teṣan Mọkọla, n’Ibadan, ti lọọ tu Bọsẹ silẹ ninu ide awọn ajinigbe. Awọn ọdẹ adugbo naa lo fi iṣẹlẹ ọhun to wọn leti.

Ṣugbọn awọn to sun mọ Bọsẹ, ẹni to n ṣiṣẹ nileetaja kan laduugbo Ogunpa, n’Ibadan, sọ fakọroyin wa pe lẹyin ti ọmọbinrin naa ti tọju owo ti ọga ẹ ni ko tọju si banki tan lo ko sọwọ awọn ọbayejẹ eeyan ọhun.

 

Obinrin naa, ẹni to ni ka forukọ bo oun laṣiiri ṣalaye pe, “lọjọ kẹfa, oṣu karun-un, ọdun yii (2019), ọga Bọsẹ ran an niṣẹ. O ni bi oun ṣe n pada sile lẹyin to tọju owo yẹn si banki tan ni ọga oun pe oun lati mọ boya oun ti jiṣẹ naa. Ko si pẹ sigba yẹn loun ba ara oun ninu ile kan to ṣokunkun lẹyin ti ẹnikan fi ara nu oun lara nitosi ileefowopamọ naa.

 

“O sọ pe awọn eeyan yẹn lu oun gan-an, wọn si fẹẹ fipa ba oun laṣepọ. Ṣugbọn bi mo ṣe n wo o yẹn, o da bii pe wọn fipa ba a laṣepọ gan-an, ko kan fẹẹ maa fi gbogbo ẹnu sọrọ ni.”

 

Gẹgẹ b’Alaroye ṣe gbọ, lalẹ ọjọ ti Bọsẹ de ahamọ awọn ajinigbe, inu ahamọ awọn ọlọpaa  lawọn obi ẹ atawọn ọrẹ ẹ kan sun mọju ọjọ keji. Ọga Bọsẹ lo fi ọlọpaa gbe wọn nigba ti ko ri i ko pada waa jiṣẹ fun un ni ṣọọbu, o lọmọbinrin naa ti gbe owo oun sa lọ, bi wọn ko ba si tete wa a jade nibi to ba wa, wọn maa pẹ latimọle kanrin kese ni.

 

Yatọ si awọn obi Bọsẹ, ọkunrin naa tun fi ọlọpaa mu ọrẹ ẹ kan pẹlu ọrẹkunrin ẹ. Gbogbo wọn ni wọn jọ sun inu atimọle ko too di pe ori ko wọn yọ.

 

Ọkan ninu awọn Hausa adugbo naa to n ji lọ si mọṣalaṣi ni idaji lo gbọ ohun ẹkun ẹ to fi lọọ sọ fun awọn ọdẹ to n ṣọ adugbo yẹn loru moju. Awọn ọdẹ ni wọn lọọ fi iṣẹlẹ ọhun to awọn agbofinro leti.

Bo tilẹ̣ jẹ pe wọn ti gba beeli awọn eeyan Bọsẹ lọjọ keji ti wọn ji i gbe, riri ti wọn pada ri i lẹyin ti awọn ọlọpaa yọ ọ kuro nigbekun awọn ajinigbe, lo fọ oun atawọn obi ẹ mọ kuro ninu ẹsun ole ti ọga ẹ fi kan wọn. Idi ni pe wọn ni wọn ba tẹla, iyẹn iwe akọsilẹ owo ti ọmọbinrin naa san ninu apamọwọ to gbe kọpa lọ si banki ki wọn too ji i gbe.

Ni gbogbo asiko naa, bi ọga Bọsẹ ṣe n fi oju ole wo ọmọọṣẹ ẹ, to si n pe awọn obi ẹ ni baba ole ati iya gbéwiri, bẹẹ lawọn eeyan Bọsẹ paapaa n fura si ọkunrin Ibo oniṣowo naa gẹgẹ bii ọdaran, wọn ro pe oun lo ṣeto awọn ajinigbe lati lọọ da ọmọọṣẹ ẹ lọna ni, paapaa  nigba to jẹ pe ni kete ti ọmọbinrin naa sanwo si banki tan lọga ẹ bi i leere lori foonu pe ṣe o ti jiṣẹ ti oun ran an, to si jẹ pe nigba ti awọn aladuugbo rẹ too beere ọmọọṣẹ ẹ lọwọ ẹ ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ lo too ranti pe ko ti i de lati ibi ti oun ran an to fi lọọ fi ọrọ naa to awọn agbofinro leti.

Gẹgẹ bi iwadii akọroyin wa, Bọsẹ ko ti i mọ ọkunrin. Eyi lo si mu ko farapa pupọ nigba ti wọn ba a laṣepọ ni tipatipa.

Ileewosan aladaani kan to wa laduugbo Mọkọla, n’Ibadan, ni wọn gbe ọmọ ọdun mejilelogun naa lọ fun itọju. Odidi ọsẹ kan lo lo nileewosan ọhun, nnkan bii ọsẹ meji ni wọn si fi tọju ẹ.

(84)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.