Laye Buhari, wọn ti fun Naijiria loye tuntun

Spread the love

Ninu awọn orilẹ-ede to kuṣẹẹ julọ laye bayii, Naijiria ni nọmba waanu. Lọsẹ to kọja yii nikan, esi iwadii meji lo jade, ṣugbọn nnkan kan naa ni mejeeji tọka si. Theresa May, olori orilẹ-ede United Kingdom, ni London, lo kọkọ ju ọrọ naa lulẹ, bo ba si jẹ awọn ti wọn n ṣejọba Naijiria lojuti ni, ko si ohun to yẹ ko ti olori ijọba kan loju ju ohun ti obinrin naa sọ nipa Naijiria lọ. O ni Naijiria ti di ile fun awọn otoṣi, awọn akuṣẹẹ ati awọn alaini. Oyinbo ki i deede sọrọ bẹẹ o, iwadii ni wọn maa n tẹle lati sọ ohun ti wọn ba sọ. Iwadii kan to jade laipẹ yii sọ pe ni gbogbo orilẹ-ede agbaye, ko si ibi ti awọn mẹkunnu ti toṣi ju Naijiria tiwa yii lọ. Wọn ni bi eeyan ba ko ọgọrun-un eeyan jọ, awọn mẹjọ ninu wọn ni wọn ko ni i le na owo bii ẹgbẹrun kan aabọ Naira (N1500) tabi dọla marun-un ($5) lojumọ kan, awọn miiran ko tilẹ le ko iru owo bẹẹ jọ laarin ọjọ meji tabi mẹta. Bẹẹ ko tun si orilẹ-ede ti awọn mẹkunnu wọn pọ to bẹẹ, ti wọn o le ni wan-taosan faifu handirẹdi lojumọ kan. Ododo ọrọ si ni, nitori ẹni ti yoo ba ni N1500 lojumọ kan, aa jẹ pe tọhun yoo ri owo to to fọti-faifu taosan, iyẹn ẹgbẹrun marundinlaaadọta lojumọ kan. Ẹni meloo ni Naijiria lo le ri iru owo bẹẹ loootọ, mẹkunnu wo lo le ri iru owo bẹẹ laarin ọdun kan paapaa. Bẹẹ ninu iṣoro agbaye, orilẹ-ede ti ọpọlọpọ awọn eeyan ibẹ ko ba ti le ni dọla maarun-un lojumọ, iṣẹ gidi lo n ṣẹ wọn. Nigba ti wọn si ṣiro awọn orilẹ-ede ti iru rẹ wa, Naijiria lawọn eeyan bẹẹ pọ si julọ ni gbogbo aye. Nnkan to si mu ọrọ naa dun awọn mi-in ni pe nnkan ko ri bayii ni ọdun mẹrin sẹyin, Naijiria ko si ni ipo buruku to wa loni-in yii rara. Ko si ohun to n fa eleyii ju pe ọpọ awọn ileeṣẹ ni wọn ti ti pa, ti awọn ileeṣẹ bẹẹ si ti da awọn ti wọn n ṣiṣẹ nibẹ silẹ. Nipa eyi, iṣẹ tijọba Naijiria n pese lojumọ ati lọdun kan ti dinku, bi iṣẹ si ti n dinku, bẹẹ ni owo to n wọle fun wa ko to nnkan mọ. Eyi lo jẹ ki awọn akuṣẹẹ pọ si i, iṣẹ naa si pọ debii pe ọpọ eeyan ni ki i fi oju ba wan-taosan laarin ọjọ mẹta si mẹrin, ẹlomiiran ki i si ri wan-taosan laarin ọsẹ kan! Nigba ti ko ri iṣẹ ti yoo ṣe! Ohun ti ijọba  Buhari yii ṣe gbọdọ mura si ọrọ to wa nilẹ yii niyi, ki wọn gbe eto ọrọ-aje dide, eto ti yoo mu ọrọ aje wa dagbasoke, ti yoo mu nnkan yatọ si bo ṣe wa yii. Bi nnkan ṣe wa yii ko dara, ọrọ naa ti le debii pe awọn ti wọn ni paapaa ko gbadun, nitori meloo ni wọn, ọdọ wọn lawọn ti ko ni si n rọ lọ. Owe Yoruba sọ pe olowo kan laarin otoṣi mẹfa, bi wọn ko ba ṣọra, otoṣi yoo kan di meje ni. Tiwa yii tilẹ le, nitori olowo kan laarin otoṣi mẹjọ ni, nigba wo ni gbogbo wa ko ni i di otoṣi. Afi ki ijọba yii dide giri si ọrọ-aje yii, ki wọn tilẹ gbe ilana kan kalẹ ti yoo jẹ ki ọrọ-aje wa dide lori idubulẹ aisan, nitori bi nnkan ti n lọ yii ko daa. Aarẹ Muhammadu Buhari, bi nnkan ti n lọ yii ko dara o, gbogbo Naijiria lo maa fẹẹ di akuṣẹẹ tan, ma ma jẹ ki nnkan tori rẹ bajẹ o!

 

(24)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.