Lanlẹhin ṣeleri lati da ogo Oke-Ogun pada toun ba ti wọle ibo

Spread the love

Oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu African Democratic Party (ADC), nipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Olufẹmi Lanlẹhin ti fọkan awọn agbegbe Oke-Ogun balẹ pe gbogbo ohun amuṣọrọ ti awọn ara agbegbe naa gbọkan le ṣugbọn to ti bọ sọnu lọwọ wọn loun yoo da pada laarin oṣu mẹfa toun ba gba iṣakoso iṣejọba ipinlẹ naa.
O sọrọ yii nibi ipolongo ita gba-n-gba to ṣe nibi ti ogunlọgọ awọn ololufẹ ẹgbẹ naa peju-pesẹ si  ni awọn agbegbe bii Ado-Awaye, Iṣẹyin, Kiṣi, Igbẹti, Ogbooro ati Agọ-Amọdu, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ṣaki, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, si Ọjọbọ,Tọsidee, ọsẹ to kọja.
Ninu ọrọ rẹ niluu Ṣaki, o bẹnu atẹ lu bi iṣejọba Gomina Abiọla Ajimọbi, ṣe kọ lati pari ọna onibeji oni kilomita mọkanla laarin ilu, lasiko to da faraalu, o si ṣeleri pe kiakia loun yoo pari rẹ ti wọn ba dibo foun toun si wọle.
Nipa olu-ileeṣẹ ohun ọgbin OYSADEP, to wa niluu Ṣaki, ṣugbọn ti ijọba Ajimọbi ti gbe lọ siluu Ibadan, Lanlẹhin ni gbigbe olu-ileeṣẹ naa kuro niluu Ṣaki, lọwọ kan oṣelu ninu ati pe ileeṣẹ ọhun wulo niluu Ṣaki ju ilu Ibadan lọ. O sọ pe ọrọ nipa bi ilu naa ko ṣe ri ọba jẹ lo ni yoo je oun logun, ti ijọba oun yoo si mojuto o ni kiakia.
Ninu ọrọ alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Ọyọ Dokita Ahmed Ayinla, lo ti sọrọ lori awọn ọmọ ẹgbẹ ti ko ti i gbagbọ pe awọn oludije fun ipo gomina ti inu n bi, ti wọn si ti gba kootu lọ latari ẹni ti yoo dupo gomina lọdun yii ni wọn ti lọọ fagile ẹjọ wọn ni ile-ẹjọ, ti awọn bii Dokita Wale Adegoke, Pasitọ Fatoki, Amofin Lọwọ Obiṣẹsan, tawon naa wa sibi ipolongo ọjọ naa si jẹwọ atilẹyin wọn fun oludije naa.
Ko ṣai ṣeleri pe odo iṣẹmbaye Ado-Awaye, ni yoo di ohun awoyanu nitori ijọba oun yoo gbe e larugẹ, to si tun ṣeleri pe igbo ọba to wa niluu Igboho, naa yoo gba ipin tirẹ lọdọ ijọba, ti kikọ ileewe giga siluu Iṣẹyin naa ko ni i gbẹyin.
Lanlẹhin tẹsiwaju pe ileewe awọn ọmọ ologun ti ijọba APC, kọlati yọnda ilẹ fun wọn niluu Ṣaki, ni yoo jẹ mimuṣẹ lasiko ijọba oun, nitori pe ohun ni yoo jẹ ileewe awọn ọmọ ologun akọkọ lagbegbe Oke-Ogun, lẹyin Ibadan.
O waa rọ gbogbo ọmọ bibi ipinlẹ Ọyọ lati ri ẹgbẹ ADC, gẹgẹ bii ẹgbẹ ọmọluabi ti awọn eeyan to lẹnu nidii oṣelu wa nibẹ to si le e mu idẹrun de ba tẹru-tomo, nitori idi eyi ki wọn dibo fun awọn oludije lati ori aare titi de ori ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ gbogbo.

 

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.