Laarin oṣu kẹrin sikẹfa ọdun yii, eeyan mọkandinlaaadọrin lo ti ku ninu ijamba ọkọ nipinlẹ Ogun

Spread the love

 

Ajọ ẹṣọ alaabo oju popo ti a mọ si FRSC, ẹka tipinlẹ Ogun, ti fidi ẹ mulẹ pe eeyan mọkandinlaaadọrin(69), lo ti ku ninu awọn ijamba ọkọ kaakiri ipinlẹ Ogun laarin oṣu kẹrin, ọdun yii, si ikẹfa ti a wa yii.
Ọga agba ajọ naa nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Clement Ọladele, lo sọ eyi di mimọ nibi agbeyẹwo ijamba oju popo oloṣu mẹta-mẹta ti wọn maa n ṣe ni olu ileeṣẹ naa to wa niluu Abẹokuta.
Kọmanda Ọladele ṣalaye pe ọgọrun-un kan ati ogoji le mẹta(143), ni awọn asidẹnti to wa lakọsilẹ bayii pe o ṣẹlẹ labala keji ọdun yii kaakiri awọn agbegbe nipinlẹ Ogun, ko si din leeyan mọkandinlaaadọrin to padanu ẹmi wọn ninu awọn ijamba naa.
O fi kun un pe ida mẹẹẹdọgbọn(25%) ni iku awọn eeyan to doloogbe lasiko yii fi le si, iku ojiji loju popo ko dinku, niṣe lo tun le kun si i.
Awọn oju ọna ti atunṣe n lọ nibẹ lọwọ, agaga oju ọna marosẹ Eko s’Ibadan ati marosẹ Eko si Abẹokuta ni Ọladele sọ pe awọn ijamba naa ti waye ju, o ni ida aadọta ninu ọgọrun-un ni awọn to ku loju ọna yii.
Ko sohun meji to fa iku aitọjọ yii gẹgẹ bi ọga FRSC naa ṣe wi ju ere asaju latọdọ awọn awakọ, ai ni suuru, ai bọwọ fun ofin irinna.
‘To ba jẹ pe awọn dẹrẹba n tẹle ofin irinna ni, ti wọn ko gba ọna ti ki i ṣe tiwọn, ti wọn tẹle ofin to de ọkọ wiwa ati bo ṣe yẹ ki mọto sare to, awọn ijamba to n fa iku ojiji yii ko ba mọ niwọn bi wọn yoo ba tiẹ ṣẹlẹ rara. Ṣugbọn pupọ ninu wọn ki i tẹle awọn ofin to de mọto wiwa, ohun to n fa wahala niyẹn’
‘A ko ṣe akọsilẹ ijamba lati fi dẹruba ẹnikẹni, tabi lati fi ba awọn eeyan ninu jẹ. A n ṣe gbogbo eyi lati ta gbogbo eeyan ji si ewu to wa loju ọna, to si n gba ẹmi nitori ai ṣe ohun to tọ ni. Ayipada rere la n fẹ, nitori awọn ijamba yii ṣee dena bi a ba mojuto o.’
Bẹẹ ni Ọgbẹni Ọladele wi.

(62)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.