Kwara 2019: Balogun-Fulani ni ki Buhari gbe asia APC fun Ọmọtoṣẹ atawọn toun yan bii oludije

Spread the love

Alaga ẹgbẹ APC nipinlẹ Kwara ti ile-ẹjọ fontẹ lu, Ishọla Balogun-Fulani, ti rọ Aarẹ Muhammadu Buhari atawọn adari apapọ APC lati tẹle aṣẹ ile-ẹjọ nipa gbigbe asia ẹgbẹ fun Ọnarebu Kayọde Abdulwahab (Ọmọtosẹ), gẹgẹ bii oludije gomina atawọn oludije mi-in toun yan.

Lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lọsẹ to kọja niluu Ilọrin, Balogun-Fulani loun reti ki Buhari tawọn eeyan ri bii oloootọ eeyan, to si bọwọ fun ofin lati gbọ igbe awọn, nitori pe awọn nile-ẹjọ da mọ gẹgẹ bii ojulowo adari ẹgbẹ APC ni Kwara.

O ni bi aarẹ ba kuna lati ṣe bẹẹ, to si tapa si aṣẹ ile-ẹjọ, o le sọ ẹgbẹ APC di yẹpẹrẹ loju ile-ẹjọ atawọn araalu.

Balogun-Fulani ni o ti wa lakọsilẹ pe ile-ẹjọ ti gbe idajọ kalẹ lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹsan-an, ọdun 2018, to fopin si gbogbo awuyewuye to n lọ lori akoso ẹgbẹ APC nipinlẹ Kwara.

O ni: “Ninu idajọ ọhun, ti ko ti i si atako kankan lati ile-ẹjọ to tun ga ju, adajọ kede pe awa ṣi ni adari ẹgbẹ, ati pe ikede tawọn oloye apapọ ṣe pe wọn rọ wa loye ko le fẹsẹ mulẹ laelae. O jẹ ohun to lodi labẹ ofin. Eyi si tumọ si pe igbimọ alakooso APC ti ofin mọ ni eyi ti emi, Alhaji Ishọla Balogun-Fulani n dari.

“Bakan naa pẹlu idajọ yii, o fi han pe awọn oludije ta a ba yan nikan ni ojulowo. Fun idi eyi, oludije fun ipo gomina wa ni Alhaji Abdulwahab Kayọde, a si lero pe Aarẹ Buhari yoo tẹle aṣẹ ile-ẹjọ.

“Ireti wa ni pe aarẹ yoo gbe asia ẹgbẹ fun awọn oludije ti ofin da mọ lati kopa ninu idibo to n bọ, nigba to ba ṣabẹwo si ipinlẹ Kwara. Apẹẹrẹ rere ni idajọ to waye laarin Kashamu ati Adebutu pẹlu awọn adari ẹgbẹ PDP jẹ fun ẹgbẹ wa”.

Alaga naa ni APC ṣi ni ẹgbẹ to dara ju fun orilẹ-ede Naijiria, o ke si awọn araalu, paapaa julọ nipinlẹ Kwara, lati dibo fun Aarẹ Buhari, ko le pari awọn iṣẹ ribiribi to n ṣe, ati lati fi ibo gbe awọn oludije APC yooku wọle.

O fi da Buhari loju pe ẹgbẹ APC wa nikalẹ lati ri i pe o jawe olubori ibo to maa waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji.

 

 

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.