Kootu gba beeli Bọlanle to ji foonu l’Ado-Ekiti

Spread the love

Obinrin ẹni ọdun mọkandinlaaadọta kan, Bọlanle Adekanmi, ni kootu majisreeti Ado-Ekiti ti fun ni beeli lori ẹsun ole jija.

Inspẹkitọ Caleb Leranmo sọ fun kootu pe ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹrin, ọdun yii, ni afurasi naa huwa ọhun ni nnkan bii aago mẹjọ aarọ lọja Ẹnu-Odi, l’Ado-Ekiti.

O ni oun atawọn kan ti wọn ti sa lọ bayii ni wọn gbimọ-pọ ji foonu Infinix Note 3 towo rẹ to ẹgbẹrun marundinlọgọta (55,000) ati ẹgbẹrun lọna aadọta (50,000) Naira to jẹ ti Chinedu Nwonu.

Ẹsun yii lo tako abala irinwo-din-mẹwaa (390) iwe ofin iwa ọdaran ọdun 2012 tipinlẹ Ekiti n lo.

Leranmo rọ kootu lati fun un laaye agbeyẹwo iwe ẹsun naa ati lati ko ẹlẹrii jọ.

Bọlanle sọ fun kootu pe oun ko jẹbi, bẹẹ ni Amofin Yẹmi Adebayọ bẹbẹ fun beeli rẹ, o ni ko ni i sa lọ

Majisreeti Taiwo Ajibade gba beeli olujẹjọ pẹlu ẹgbẹrun lọna ogun Naira ati oniduuro meji niye kan na

Igbẹjọ di ọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii.

 

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.