Kọntena wo lu mọto ayọkẹlẹ mọlẹ ni marosẹ Eko s’Ibadan, lo ba pa obinrin kan

Spread the love

Tirela kan to gbe kọntena, ti ẹru kun inu ẹ bamu lo ṣubu le mọto ayọkẹlẹ ti wọn paaki silẹ jẹẹjẹ lọjọ Aiku ijẹta yii, to si ṣe bẹẹ pa obinrin kan loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan
Ohun ti ALAROYE gbọ latẹnu Ọgbẹni Babatunde Akinbiyi, Alukoro ajọ TRACE nipinlẹ Ogun, ni pe ni nnkan bii aago kan ọsan ọjọ Aiku nijamba ọhun waye.
O ni tirela ti nọmba ẹ jẹ KRD 199XW n bọ niluu Eko ni, ṣugbọn ere buruku lo n sa bọ bo ṣe tobi to. Nibi to ti n sare ọhun lo ti ko si koto kan ti wahala fi de, to di pe kọntena to gbe ru yẹ gẹrẹ, to si re lu ọkọ ayọkẹlẹ Honda ti nọmba ẹ jẹ BDG 669 FK to wa lẹgbẹẹ kan ọna.
Obinrin kan wa ninu mọto yii gẹgẹ bi alukoro ṣe ṣalaye, o ni mọto naa yọnu ni wọn ṣe paaki, ti wọn si ṣe e. Lẹyin ti wọn tun mọto naa ṣe tan ni dẹrẹba n rọmi si i, obinrin to n gbe lọ si wa ninu mọto ni tirẹ, ibẹ ni ẹru ori tirela naa ti yẹ, to si lọọ re ba ọkọ ti obinrin yii wa ninu rẹ.
Eyi lo fa a to jẹ bi kọntena naa ṣe wo lu mọto yii mọle lo pa obinrin to wa ninu ẹ lẹsẹkẹsẹ. Eeyan mẹta nijamba to waye nibi ileepo Amo, ni marosẹ Eko s’Ibadan, naa kan, awọn naa ni dẹrẹba to wa tirela, ọmọ ẹyin ọkọ ẹ ati obinrin to doloogbe yii.
Teṣan ọlọpaa Warewa ni wọn mu dẹrẹba to wa tirela naa lọ, ibẹ naa ni wọn si ko awọn ọkọ mejeeji ti wahala naa kan lọ. Ẹka to n ri si iṣẹlẹ pajawiri ni wọn gbe oku obinrin ọhun lọ gẹgẹ bi alaye alukoro TRACE

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.