Ko ti i si gomina to mu ifasẹyin ba ipinlẹ Ọṣun bii Arẹgbẹṣọla ninu itan – PDP

Spread the love

Ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun ti sọ pe titi lae lawọn eeyan yoo maa ranti ọdun mẹjọ iṣejọba Gomina Arẹgbẹṣọla gẹgẹ bii eyi to mu ifasẹyin ba ọkọ itẹsiwaju ipinlẹ Ọṣun lati ọdun 1999 ti wọn ti da a silẹ.

Ninu atẹjade kan ti alaga ẹgbẹ naa, Sọji Adagunodo, fi sita lo ti sọ pe ko ti i si ijọba to buru to eleyii ri ninu itan nitori pe ni gbogbo ọna ni Arẹgbẹṣọla fi polukumusu gbogbo ẹka nipinlẹ Ọṣun.

Adagunodo ni iyalẹnu lo jẹ pe Arẹgbẹṣọla le maa ṣogo asan lori eto kan to ṣe laipẹ yii pe oun wẹ yan kanin-kan-in ninu iṣejọba ipinlẹ Ọṣun, nitori pe gbogbo awọn ti aye wọn dojuru lasiko iṣejọba rẹ ko le gbadura fun un rara, bẹẹ ni wọn ko ni i gbero pe kiru iṣejọba bẹẹ tun pada wa l’Ọṣun.

Gẹgẹ bi Adagunodo ṣe wi, “O ti wa ninu itan bayii pe lasiko iṣejọba Arẹgbẹṣọla ni ajọ to n ri si ọrọ gbese tijọba ba jẹ, BUDGIT, gbe e jade pe ipinlẹ Ọṣun lo wa nipo kẹrin ninu awọn ijọba ipinlẹ ti gbese rẹ pọ ju lọwọlọwọ lorileede Naijiria.

“Aarin ọdun mẹjọ yii naa ni itiju ti ko lẹgbẹ ba wa l’Ọṣun latari ipo ẹyin ti awọn akẹkọọ wa wa ninu idanwo ti wọn n ṣe pẹlu awọn lẹgbẹ wọn lorilẹede yii. Ipo kọkandinlọgbọn la wa ninu idanwo oniwee mẹwaaWAEC laarin ipinlẹ mẹrindinlogoji.

“Laye Arẹgbẹṣọla ni awọn dokita, olukọ ileewe giga atawọn oṣiṣẹ ijọba gun le iyanṣẹlodi fun nnkan bii ọdun mẹta ataabọ lapapọ, eleyii ti ko si iru rẹ ri lakọsilẹ itan ipinlẹ Ọṣun.

“Nigba ti Arẹgbẹṣọla n sọ pe awọn oju-ọna toun ṣe l’Ọṣun le lo aadọta ọdun, ẹrin ni gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun bu si, nitori pe lai ti i kuro nipo, ọpọlọpọ awọn ọna yẹn ni wọn ti di pampẹ iku. Ẹni to ba lọ kaakiri inu awọn ilu bii Ejigbo, Iwo, Ẹdẹ, Ikirun, Ila Ọrangun, Ilobu, ati bẹẹ bẹẹ lọ yoo mọ pe ẹnu opurọ Arẹgbẹṣọla ki i ṣẹjẹ.

“Koda, awọn ọna nla nla to jẹ tijọba apapọ, eleyii ti Arẹgbẹṣọla fi gba obitibiti owo jade, to si tun fi gbese silẹ de arọmọdọmọ l’Ọṣun ko ti i lojutuu, ida ogoji ninu ida ọgọrun-un ti yoo fi pari lọpọ wọn wa bayii. Awọn ọna bii Oṣogbo si Ila-Odo, Akoda si Gbọngan, Orile-Owu si Ijẹbu-Igbo, Iwo si Ejigbo atawọn miin.

“Bakan naa, awọn oluwadii fidi rẹ mulẹ pe ipinlẹ Ọṣun lo wa nipele kẹta laarin awọn ipinlẹ to dọti julọ lorilẹede yii, bẹẹ odidi ọdun mẹjọ ni Arẹgbẹṣọla fi yọ owo ijọba ipinlẹ Ọṣun ati ti ibilẹ lori ọrọ pe oun fẹẹ fi ṣeto kolẹ-kodọti.

“Bo tilẹ jẹ pe inu ẹgbẹ wa dun pe iṣẹjọba akotileta ọlọdun mẹjọ Arẹgbẹṣọla n lọ sopin bayii, o jẹ ibanujẹ fun wa pe o tun fi wahala ati idojuti lelẹ lori ọrọ oṣelu ipinlẹ Ọṣun pẹlu iwa ipa to hu lati yi ifẹ awọn araalu po lasiko idibo gomina to waye losu kẹsan-an, ọdun yii”.

Adagunodo waa sọ pẹlu idaniloju pe ile-ẹjọ yoo gba ẹtọ oludije fun ipo gomina rẹ, Senatọ Nurudeen Ademọla Adeleke, kuro lọwọ Alhaji Oyetọla ti ẹgbẹ APC lati jẹ ki akoko itura pada ba awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun.

(36)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.