Ko ti i pe oṣu kan ti wọn gba Solomon siṣẹ lo ji mọto ọga ẹ gbe sa lọ

Spread the love

Bi Yoruba ba n powe pe ijimere ṣọgi gun, kó o ma baa gungi aládi, iyẹn ni pe bi eeyan ko ba kiyesara daadaa ko too gbe igbesẹ kan, ohun aburu le tẹyin igbesẹ naa yọ. Eyi lo difa fun ọga ileeṣẹ kan, Abilekọ Olufunkẹ Ọbada, ẹni ti ọkan ninu awọn eeyan to gba siṣẹ ja lole, ọkọ olowo nla ẹ niyẹn fẹẹ gbe sa lọ.

 

Ọdaju oṣiṣẹ ọhun to n jẹ Solomon Boniface Okon ko ti i lo oṣu kan lẹnu iṣẹ to fi fẹẹ sọ ọga ẹ di ẹdun arinlẹ.

 

Jagunlabi ko duro nitosi, ilu wọn nilẹ Ibo lọhun-un lo fọ̀n ọ́n si, o n fi mọto onimọto ọhun ti nọmba idanimọ rẹ jẹ LSR 782 DF (LAGOS) jaye ọlọba, awọn araalu ẹ si ro pe niṣe lo ti yara ri taje ṣe n’Ibadan to ti lọọ ṣiṣẹ lo ṣe n fi jiipu ṣe ẹsẹ rin, laimọ pe jiji lo ji i gbe.

 

Gẹgẹ bi ọga ẹ ṣe fidi ẹ mulẹ fawọn oniroyin n’Ibadan, “ko ti i pe oṣu kan ti mo gba ọmọkunrin yii siṣẹ. Lọjọ to huwa buruku yii, mo ni ko gbe mi lọ si Ọsibitu UCH lati lọọ ṣayẹwo ilera mi ni.  Bi mo ṣe jade sita lẹyin ti mo ri dokita tan ni mo ri i pe ko si mọto nibi ta a paaki si mọ.

 

“Mo pe ọmọkunrin yii titi, ṣugbọn nọmba rẹ ko lọ. Bi mo ṣe wa oun ati mọto tì niyẹn ko too di pe ọwọ awọn ọlọpaa tẹ ẹ, ti wọn si gba mọto mi pada fun mi.”

 

Nigba to n ṣafihan afurasi ọdaran naa fawọn oniroyin lolu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ to wa laduugbo Ẹlẹyẹle, n’Ibadan, lọsẹ to kọja, ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Abiọdun Odude, ṣalaye pe ilu Ikot Ekpene, ni ipinlẹ Akwa-Ibom, lawọn ọlọpaa to n gbogun ti idigunjalẹ nilẹ yii (FSARS), ti lọọ hu Solomon jade lẹyin ti ọga ẹ fi iṣẹlẹ ọhun to awọn agbofinro leti.

 

Solomon to pera ẹ lẹni ọdun mejidinlọgbọn (28), jẹwọ pe, “loootọ ni mo ji mọto ọga mi gbe, jiipu Honda CRV ni. Mo fi mọto yẹn gbe wọn lọ si UCH lọjọ yẹn, ṣugbọn mo waa gbe mọto yẹn lọ ko too di pe wọn ti ọdọ dokita de.

 

“Akwa-Ibom ni mo gbe mọto yẹn lọ. Mo fẹẹ ta a ni, ṣugbọn mi o ti i ri ẹni ta a fun ti awọn ọlọpaa fi waa mu mi.

“Mo fẹ ki ọga mi atawọn ọlọpaa ṣiju aanu wo mi, nitori ko wu emi naa lati ṣe nnkan ti mo ṣe yẹn, Iṣẹ eṣu ni.”

 

Abilekọ Ọbada fi ẹmi imoore han si awọn ọlọpaa fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe lati ri ẹni to ja a lole mu, ti wọn si gba mọto oun pada fun oun.

 

 

 

(9)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.