Ko sibi kankan ti awon omo egbe wa n lo, digbi ni won wa__Oshiomhole

Spread the love

O jo pe awon alase egbe APC ti ri i pe oro awon omo egbe naa ti won ti da egbe mi-in sile ti won pe ni R-APC, ti won fee ya kuro ninu egbe oselu naa ko see duro wo mo bayii o. Gbogbo ona ni aown alase egbe naa n wa lati ri i pe awon eeyan naa ko kuro nibe. Bi won se n sepade losan-an ni won n se loru lati mu aown tinu n bi yii wale, lati ri i pe won ko fi egbe onigbale sile.

Leyin ti aown egbe APC tuntun ti won kora won jo yii sepade pelu Olori ile Igbimo asofin, Dokita Bukola Saraki niluu Ilorin, leyii ti gomina ipinle Benue, Ortom wa nibe ni alaga egbe APC, Adams Osiomhole sepade po pelu okunrin naa, nibi to ti n ba a soro, to si n be e pe ko ma fi egbe oselu naa sile, pelu ileri ep gbogbo aigbora eni ye to wa laarin gomina ipinle Benue yii atawon asaaju egbe naa nipinle ohun lawon yoo yanju.

Oro yii ko yo awon asodin tinu n bi sile nitori ni bayii, awon asaaju egbe naa ti n wa gbogbo ona lati tu awon asofin ti won ti fee ko eru won kuro ninu egbe naa. Lara ileri ti won ni ki won se fun awon, ki won si kowo bowe lori re ni pe ko ni i si enikeni ti yoo gbapoti ibo tako won lodun to n bo, aown naa ni won yoo di ipo ti won wa yii mu. Bee ni won tun so pe Bukola Saraki ni o tun gbodo je aare ile igbimo asofin agba, nigba ti Yakubu Dogara yoo je aare ile igbimo asoju-sofin.

Yato si eyi, won fi dandan le e pe won gbodo faaye gba awon igun keji to dibo lawon ipinle kookan ninu egbe naa lasiko awon ibo abele won to koja.

Eyi nikan ko, awon omo egbe R-APC yii tun ni won gbodo gbe akoso egbe naa le awon lowo lagbegbe ti onikaluku won ba ti wa ati bee bee lo.

Won se eleyii lati dena erongba awon asofin naa ti won ti ni i lokan lati fi egbe naa sile nibi ijokoo won ti yoo waye ni Tosidee, ose to n bo, ti gbogbo won yoo si da lo sinu egbe oselu mi-in.

Die ninu awon asofin yii fidi isele ohun mule, won ni ipade ti yoo waye ni oni, Tusidee, ojo Isegun laarin awon ati awon asaaju awon to loo ba egbe APC sepade lawon n duro de, eyi ni yoo si so igbese to kan ti aown maa gbe. Won fi kun un pe ti awon asaaju egbe naa ko ba ti le se gbogbo ohun ti aown so yii, ose to n bo ni awon yoo ya kuro ninu egbe oselu naa.

ALAROYE gbo pe nibi ipade ti alaga egbe APC, Adams Osiomohle se pelu awon asoju awon eeyan ohun atawon gomina egbe ohun kan ni won ti fi da won loju pe awon setan lati se gbogbo ohun ti awon eeyan naa ba fe. Bakan naa ni won ni aare Buhari paapaa loun yoo fun won ni gbogbo ohun ti won ba fe lati ri i pe won ko lo inu egbe osleu mi in, bee lo ni oun setan lati kowo bowe adehun pelu won.

Nibi ti nnkan de duro yii, ko seni to ti i le so boya pelu gbogbo ohun ti awon asaaju egbe oselu APC fee se fun awon eeyan naa, won setan alti duro ninu egbe ohun, abi pe won yoo fi egbe yii sile gege bi won se so. Ipade ati awon igbese ti won ba gbe lose yii i yoo so ibi ti igi oro naa yoo wo si.

(39)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.