Ko si ireti ninu ẹgbẹ oselu APC, ati PDP__Afẹnifẹre

Spread the love

Ẹgbẹ Afẹnifẹre bu ẹnu atẹ lu eto idibo to waye nipinlẹ Ekiti lọsẹ to kọja. Wọn ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii eyi to tabuku iṣejọba awa-ara-wa, to si fi han pe ko si ireti kankan ninu ẹgbẹ oṣelu APC tabi PDP lorileede yii.

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ yii, Yinka Odumakin, sọrọ yii ninu atẹjade to fi ṣọwọ sawọn akọroyin pe apẹẹrẹ to buruku gbaa ni igbesẹ tita ibo ti awọn oludibo gbe lasiko eto idibo to waye naa. O ṣalaye pe iwa yii naa ko yọ awọn oloṣelu to n ra ibo lọwọ awọn oludibo yii silẹ, nitori pe bi wọn ko ba fi owo tu wọn loju, awọn eeyan naa ko ni i ni lọkan lati ta ibo, ti i ṣe ẹtọ wọn.

Odumakin ni awọn ẹgbẹ oṣelu meji to n lewaju ninu eto idibo naa, All Progressives Congress (APC), ati People’s Democratic Party (PDP), ni wọn jọ jẹbi ẹsun yii, fun idi eyi, ko tọ si ọkankan ninu wọn lati naka aleebu si ẹnikẹni.

O koro oju si ipo ti ọrọ aje orileede yii wa pẹlu alaye pe awọn oloṣelu yii mọ-ọn-mọ n fi iya jẹ awọn araalu nitori eto idibo. O ni ebi ti wọn fi n pa awọn araalu lo jẹ ko rọrun fun wọn lati fowo tu awọn eeyan ti iya n jẹ naa loju.

(19)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.