Ko si idile kankan nipinlẹ Ọṣun ti ko ti janfaani eto O’Yes – Arẹgbẹṣọla

Spread the love

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Rauf Adesọji Arẹgbẹṣọla, ti sọ pe idi ti iye awọn ọdọ ti wọn ko niṣẹ lọwọ fi kere pupọ nipinlẹ Ọṣun ko ṣẹyin ọgbọn inu ti oun fi gbe eto O’YES (Ọṣun Youths Empowerment Scheme), kalẹ lẹyin ọgọrun-un ọjọ toun di gomina ipinlẹ Ọṣun.

Arẹgbẹṣọla ni iwadii ti fi han pe ipele keje ni ipinlẹ Ọṣun wa ninu awọn ipinlẹ ti eto ọrọ aje rẹ gbounjẹ fẹgbẹ, to tun gbawo bọ lorilẹede yii, Ọṣun lo ni iye awọn ti inu wọn dun ju, bẹẹ ni iye awọn ọdọ ti ko niṣẹ lọwọ kere pupọ.

Lasiko ti awọn ọdọ ẹgbẹrun lọna ogun ti Arẹgbẹṣọla ṣẹṣẹ gba fun eto O’Yes n rin irin afaralokun lati kadii eto idanilẹkọọ wọn nilẹ niluu Oṣogbo ni gomina sọrọ idunnu yii. O ni inu oun dun fun ipa rere tijọba oun ti ko ninu aye awọn ọdọ laaarin ọdun mẹjọ ti oun lo.

O ni manigbagbe ni eto naa jẹ ninu itan iṣejọba nipinlẹ Ọṣun, nitori pe yatọ si anfaani lati le da duro to fun ogunlọgọ awọn ọdọ, o tun din iwa ipa ati jagidijagan ku nipinlẹ Ọṣun.

Gẹgẹ bo ṣe wi, “Awa yatọ si awọn ijọba ti wọn kan maa n ṣeleri lasan lai ṣiṣẹ tọ ọ, ida meji ninu ida mẹta awọn ọdọ ti wọn ti janfaani eto O’Yes ni wọn ti ni iṣẹ tara wọn lọwọ bayii, tijọba si ti gba awọn mi-in sinu iṣẹ ijọba.

“Mo layọ lati sọ pe, ko si idile kankan nipinlẹ Ọṣun loni-in, lai fi ti ẹya, ẹsin tabi ẹgbẹ oṣelu ṣe, ti ko ti i janfaani eto yii lati ọdun 2010 ti a ti gbe e kalẹ, o si jẹ nnkan iwuri fun mi nigba ti wọn ṣewadii, ti wọn si sọ pe ipinlẹ Ọṣun lo ni iye awọn ọdọ ti ko niṣẹ lọwọ to kere ju lorilẹ-ede yii.

“Idi niyi ti mo fi wa n rọ awọn eeyan wa lati dibo fun oludije ẹgbẹ oṣelu APC, Gboyega Oyetọla, ninu idibo gomina to n bọ yii, ẹni to ba mọ nipa oniruuru eto tijọba mi ti gbe kalẹ lo yẹ ko tẹ siwaju ninu ẹ.

“Akọkọ iru ẹ ni eto yii nilẹ Afrika, idi si niyii ti ajọ alakooso Banki Agbaye (World Bank), fi gboṣuba fun un gẹgẹ bii eto kan gboogi to din ainiṣẹ lọwọ ku laaarin awọn ọdọ”.

Ninu ọrọ ti oludije funpo gomina naa, Alhaji Gboyega Oyetọla, o ni ọkan pataki lara awọn oniruuru aṣeyọri tijọba Gomina Arẹgbẹṣọla ṣe laarin ọdun mẹjọ ni eto O’Yes jẹ, ti oun ba si lanfaani lati di gomina, o di dandan ki oun tẹ siwaju ninu ẹ.

Oyetọla ni ọdọ to to ẹgbẹrun lọna ọgọrin (80,000), ni wọn ti kuro ni alainiṣẹ lọwọ nipinlẹ Ọṣun nipasẹ anfaani ti eto O’Yes ti mu ba wọn, idi si niyi ti ifọkanbalẹ fi wa kaakiri lori eto aabo nigba to jẹ pe ọwọ awọn ọdọ ko dilẹ rara.

Alakooso ajọ O-YES, Ogbẹni Ẹnibukun Oyewọle, gboriyin fun Gomina Arẹgbẹṣọla fun agbekalẹ eto naa, eleyii to ni o ti ṣi aimọye ọna fun idagbasoke awọn ọdọ nipinlẹ Ọṣun.

(18)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.