Ko seni to fee pa Obasanjo o, Buhari ko ri tiẹ ro__ Lai Muhammed

Spread the love

Latigba ti aarẹ Naijiria tẹlẹ,Oloye Olúṣẹ́gun Ọbasanjọ ti keboosi lọjọ Jimọ to kọja yii pe ijọba apapọ fẹẹ mu oun ti mọ́lè, ki wọn si pa oun ni oríṣìíríṣìí ọrọ ti n ti ẹnu awọn to fẹ̀sùn kan jade. Ṣugbọn minisita fun eto iroyin, àṣà ati iṣe labẹ Buhari lo fọgba ayanga ju, oun lo ni ìjọba awọn ko tiẹ ri ti Ọbasanjọ ro, o ni iṣẹ ọwọ baba naa lo n da a laamu.

 

Ṣe lọjọ kẹjọ, oṣu kẹfà, yii, ni Oloye Ọbásanjọ́ fi ọrọ ẹnu ẹ ran akọ̀wé iroyin rẹ l’Abẹokuta, Ọ̀gbẹ́ni Kẹ́hìndé Akínyẹmí. Ohun to ni kiyẹn gbe jade ni pe ìjọba Ààrẹ Muhammadu Buhari n lepa oun, wọn fẹ́ẹ́ ti ọ̀ràn mọ oun lọ́run, ki wọn gbe oun ju satimọle ti ko ni i lọjọ ati jade.

 

Ọbásanjọ ni eto mi-in tawọn Buhari n ṣe lori oun ni bi wọn yoo ṣe gba iwe irinna oun, toun ko ni i le jade kuro ni Naijiria, ti wọn yoo waa ba orúkọ oun jẹ kari aye. O ni wọn tun dọ́gbọ́n ati dẹ EFCC soun pẹlu. Paríparí ẹ bi Ẹbọra Owu ti wi ni pe ìjọba yii n lepa ẹmi oun, wọn fẹ̣ẹ pa oun patapata koun ma le sọ ootọ́ ọrọ toun n sọ fun wọn mọ.

 

Aarẹ tẹlẹ yii loun ko ba ma gba awọn ete tijọba yii n pa lori oun naa gbọ, ṣùgbọ́n ọdọ awọn eeyan ti wọn ki i mu efo lo ti jade wa. Ọbásanjọ́ ni awọn ti wọn mọ bo ṣe n lọ nile ijọba ni wọn je koun mọ pe oke téńté lórúkọ oun wa ninu awọn ti Buhari fẹẹ da sẹria fun, ti yoo gbe ju satimọle, ti gbogbo ẹ yoo si pada yọrí siku.

Ki si ni idi ẹ toun fi dẹni ti wọn n lepa ẹmi ẹ bii eyi, Oloye Ọbásanjọ́ sọ pe nitori ootọ́ ọrọ toun n ba Ààrẹ Buhari sọ ni.

Lẹta toun kọ si Buhari lọjọ kẹtalelogun, oṣu kin-in-ni, ọdún yii, pe ko ma tun dije dupo aarẹ mọ, nitori o ti kuna ninu eyi to n ṣe lọwọ lo kọkọ fa ikoriira tijọba yii ni soun. Bẹẹ, oun ko le ri ootọ ọrọ nilẹ koun ma sọ ọ ni toun.

Ọbásanjọ́ ni ki gbogbo aye gbọ bayii pe ẹmi oun ko de lọwọ Buhari àtàwọn eeyan rẹ, wọn n lepa oun kiri.

Ẹsun nla yii ni Lai Mohammed ko jẹ ko pẹ rara toun naa fi gba ẹnu Aarẹ Muhammadu Buhari fesi lọjọ yii kan naa.

O ni ẹni ti a na lara n ta ni ọrọ Ọbásanjọ, ati pe gbogbo ohun ti baba naa fi silẹ lai ṣe nigba to fọdun mẹjọ ṣejọba Naijiria làwọn n mojuto lọwọ, iṣẹ si pọ lọ́wọ́ ìjọba Buhari ju ko jẹ ti Ọbásanjọ́ làwọn yoo maa ro lo.

Minisita yii ṣalaye pe ayajọ ‘June 12’ ti Buhari kede rẹ bii ọjọ ìjọba tiwa-n-tiwa, àtàwọn eeyan to foye to tọ si wọn da lọla, eyi ti Ọbásanjọ́ ni anfaani rẹ nigba naa, ṣùgbọ́n ti ko ṣe e lo mu baba naa maa sọrọ lasiko yii.

 

O ni o ṣe jẹ ọjọ kẹta ikede naa ni Ọbásanjọ́ n pariwo ohun ti ko ṣẹlẹ kiri.

Yatọ si eyi, agbẹnusọ aarẹ yii sọ pe aburu ti ẹgbẹ Ọbásanjọ́ fodun mẹ́rìndínlógún da silẹ ni Naijiria nijọba Buhari n gbiyanju lati tun ṣe lọwọ, awọn eeyan tọwọ wọn ko mọ níbẹ̀ bii Ọbásanjọ́ yii lẹru n ba, ìyẹn ni baba naa ṣe n sọ pe wọn n le oun kiri.

Alhaji Lai fi kun un pe aṣeyọri ìjọba Buhari tun n fọ awọn eeyan bii Ọbasanjo lori, ìyẹn ni wọn ṣe n pariwo ohun ti ko ṣẹlẹ. Ariwo ọja yii ko si le di ìjọba lọwọ gẹ́gẹ́ bi minisita yii ṣe wi, yoo maa tẹ̀síwájú ninu wiwadii awọn to kowo Naijiria jẹ ni, atawọn ti wọn ba tun n ko o jẹ lọwọ.

(50)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.