Ko le pẹ ko le jinna, Oshiomhole ni yoo lu APC yii fọ

Spread the love

Bo ba jẹ bi Adams Oshimhole, olori ẹgbẹ oṣelu APC, ṣe n ṣe yii lo n ṣe, ko le pẹ ko le jinna ti yoo fi fọwọ ara rẹ pa ẹgbẹ oṣelu naa, bo ba si ṣe bẹẹ tan, yau ni oju rẹ yoo mọ. Ẹni ti yoo ṣe olori ẹgbẹ oṣelu ki i ṣe oniṣokeṣodo, ẹnikan ti yoo le sọ ootọ ọrọ, ti yoo si le ba ẹdun ọkan awọn ọmọ ẹgbẹ pade lori ọrọ to ba jẹ mọ ti ẹgbẹ wọn ni. Ṣugbọn nigba ti Oshiomhole ti de yii, niṣe lo n ṣe bii ọga ileewe, hẹdimasita to mẹgba dani lati na ọmọ ileewe to ba rufin, tabi pasitọ to mura lati fi ẹmi ba awọn ọmọọjọ rẹ to ba ṣe aṣemaṣe ja, ko ṣe bii olori ẹgbẹ rara. Akọkọ iṣẹ olori ẹgbẹ ni lati ri i pe ẹgbẹ ko tuka mọ oun lori, nitori bi ẹgbẹ ba tuka mọ ọn lori, asiko rẹ bajẹ niyẹn. Ẹni ti yoo ṣe olori ẹgbẹ gbọdọ ni laakaye gidi, ko si mọ ọna ti yoo fi dari ẹgbẹ, nitori awọn ọmọ ẹgbẹ ki i ṣe ọmọ ileewe ti eeyan le halẹ mọ, wọn ki i ṣe ọmọ ile ẹni ti eeyan le ba wi nigba to ba wu u, ọpọ awọn eeyan ti wọn n ṣe ẹgbẹ ni wọn maa n lowo, ti wọn si maa n wa ni ipo pataki lawujọ ju olori ẹgbẹ lọ. Iyẹn ni ẹni to ba jẹ olori naa yoo ṣe ni owo ti yoo fun wọn, ti yoo si ni ọgbọn ti yoo maa lo. Ko jọ pe Oshiomhole ni iwa gidi bii eyi, ni tirẹ, aṣẹ onikumọ ni yoo maa pa, bo ba si ti paṣẹ naa tan, yoo ni awọn ti oun paṣẹ fun gbọdọ tẹle e ni, bi awọn yẹn ko ba waa tẹle aṣẹ rẹ, yoo ni oun ti mọ pe oniranu ni wọn, ko yẹ ki wọn wa ninu ẹgbẹ awọn tẹlẹ, aṣiṣe lawọn ṣe. O yẹ koju ti Oshiomhole pe gbogbo awọn ti oun lọọ bẹ ki wọn ma kuro ninu APC ni wọn kuro, nigba ti wọn si ti kuro yẹn, niṣe ni yoo dakẹ, ṣugbọn lati bẹ eeyan leni-in pe ẹgbẹ yin nilo rẹ, eeyan gidi ni, ki iyẹn waa fi ẹgbẹ silẹ lọla, ko waa di ọtunla ko o ni wọn ko ni anfaani kankan lara, iwa agabagebe ni, iyẹn ko si ni i jẹ ki awọn ti wọn ku ninu ẹgbẹ naa ka a si eeyan daadaa to ṣee ba sọrọ. Oshiomhole gbọdọ mọ pe ipo olori APC yatọ si ipo gomina ti oun ti ṣe tẹlẹ ti oun maa n paṣẹ, bi ko ba si lo laakaye to jinna lati fi tun ẹgbẹ naa ṣe, ko ni i pẹ ko ni i jinna ti yoo fi sinku APC, a jẹ pe tiẹ ba a niyẹn.

 

(28)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.