Kin niwọ ri si ẹsun ikowojẹ ti wọn fi kan igbakeji Aarẹ, Yẹmi Ọṣinbajo?

Spread the love

Oluṣeyi Dasilva

Mo dabaa pe ki wọn wadii rẹ daadaa, bi aje iwa ibajẹ baa ṣi mọ ọn lori, ki wọn fi iya ẹsun naa jẹ ẹ. Emi o ro pe o lọwọ kan oṣelu ninu rara. Mo gbọ pe o n gba iṣẹ agbaṣe ni ipinlẹ Ọṣun latọwọ Arẹgbẹṣọla, ki i ṣe igba akọkọ rẹ niyi. N ko fẹẹ pe e ni ọdaran ni, ṣugbọn igbagbọ rẹ mẹhẹ.

Jamal  Gbadamọsi

Ọna meji naa ni ẹsun ti wọn fi n kan Ọṣinbajo yii pin si, ninu ko jẹ pe awọn alatako ẹ ninu oṣelu ni wọn wa nidii ọrọ naa, tabi ko si jẹ pe baba naa ti kowo NEMA atawọn owo mi-in jẹ loootọ bi wọn ṣe wi.

Ṣẹ ẹ mọ pe Ọṣinbajo lo n buwọ luwe lawọn asiko ti Buhari ko si nile, ti awọn owo si n jade fun iṣẹ oriṣiiriṣii ti wọn ba ni o wa la ti ṣe. O le jẹ asiko yẹn ni owo ọhun n poora, o si lẹ jẹ awọn ti Igbakeji Aarẹ ba ṣiṣẹ lasiko yẹn yẹn ni wọn ṣe owo baṣubaṣu.  Ṣugbọn lati fidi otitọ mulẹ, ẹ jẹ kawọn to n fẹsun kan an yii mu ẹri to jọju jade, iyẹn loju ọmọ Naijiria yoo fi to ọrọ naa delẹ, ti a maa fi le fi  ọpọlọ gbe e pe boya Pasitọ Ọṣinbajo naa kowo jẹ ni tabi wọn purọ mọ ọn.

Ademidun Ojo

Emi o gba pe oloṣelu kan wa ni Naijiria ti ọwọ ẹ mọ fun iwa ibajẹ, ṣugbọn Ọṣinbajo ti mo n wo yii ko jọ ẹni ti mo ro pe o le ṣe owo ilu baṣubaṣu. Mi o ro pe ootọ lẹsun ti awọn aṣofin fi kan an yẹn. Ṣugbọn to ba lọọ jẹ loootọ lo jẹbi ẹsun ikowojẹ yẹn, o maa jọ mi loju nitori mi o ro iru iwa ibajẹ bẹẹ ro Ọṣinbajo. Ohun to si buru ju nibẹ ni pe ko si nnkan kan to maa tẹyin ẹ yọ. Gbogbo wa la mọ ọrọ oṣelu Naijiria, wọn maa daṣọ bo ọrọ yẹn mọlẹ gbẹyin naa ni.

 

dunay lamiday lawale

To ba jẹ pe o ri bẹẹ loootọ, ti iwadii fi han daju pe o ṣe owo ilu baṣubaṣu, o yẹ ko waa ṣalaye ẹnu ẹ fawọn araalu. Ki i ṣe ki wọn kan sare maa da a lẹjọ ninu iwe iroyin. Bi ijọba Buhari ṣe n ṣewadii awọn ti wọn fẹsun kan lori kiko owo ilu lo yẹ ki wọn ṣewadii Ọṣinbajo naa, to ba jẹ pe ijọba yii n gbogun ti iwa ibajẹ loootọ. Eyi lo maa fi han pe ijọba apapọ ko maa fa ori apa kan daṣọ bo awọn mi-in.

 

Rẹmi Alalade

Awọn aṣofin yẹn kan n wa nnkan sọ ni. Ọna ẹburu ni wọn fẹẹ gba lati maa sọ pe Ọṣinbajo to n gbogun ti iwa ibajẹ gan-an n huwa ibajẹ.

Gbogbo nnkan ti wọn n ṣe ni lati ba Buhari ati igbakeji ẹ lorukọ jẹ ki idibo 2019 too de. Ajegbodo to n wẹni kunra ni wọn.

 

Adewale Ọlayẹmi

 

Irọ ni gbogbo ẹ, awọn yẹn ti kọja iru nnkan bẹẹ yẹn. Ṣe ẹ mọ pe amofin ni, ti wọn ba tiẹ fẹẹ palẹ owo mọ, wọn aa ṣe e pẹlu ọpọlọ ni, ko ṣeni ti yoo ri ijasa rẹ nilẹ rara. Ahesọ lasan ni.

 

Aarẹ Ganiyu Afọlabi

Ninu ero temi, mo ro pe anfaani wa fun Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Ọṣinbajọ, naa lati waa wi tẹnu rẹ nitori pe awọn agba bọ, wọn ni a ki i ku sibi ta a ba wi si, bẹẹ ni ẹni ti ko ba jẹ gbii, ki i ku gbii. O yẹ ko le yọju sawọn aṣofin lati sọ iha tirẹ lori ẹsun ti wọn fi kan an, ṣe awọ ẹgbẹrun ***salubata jẹ fun olododo.

 

Arie Ilesanmi

Ẹsun lasan ni wọn si fi kan Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajọ, ko si ti i sohun to buru ninu ki wọn fẹsun kan eeyan, ohun to ku ni ki igbakeji aarẹ ti wọn fẹsun kan o gbiyanju lati wẹ ara rẹ mọ lori ẹsun ti wọn fi kan an.

 

Tosin Fawẹhinmi

Nnkan to ṣẹlẹ yii fi han pe ẹgbẹ ẹlẹtan patapata ni ẹgbẹ oṣelu APC. Opurọ pọ ninu awọn oloṣelu to wa nibẹ. Ṣe ẹ ri i, ki wọn yaa ṣewadii rẹ daadaa ni, ki wọn ma tọwọ oṣelu bọ ọ. Gbogbọ ọgbọn ti ẹgbẹ naa n da ni ọna ti wọn aa gba ṣeru ibo lọdun to n bọ, eyi ko si daa.

 

Tunji Ọladunjoye

Mi o le sọ pato boya igbakeji aarẹ kowo jẹ tabi ko kowo jẹ, tori mi o si nibẹ lati ri i, awọn to wa nibẹ naa ni wọn le sọ. Nnkan to dẹ tun wa nibẹ ni pe bi aye ko ba ri, wọn ko ni i wi. Wọn le fi kun un o tabi ki wọn yọ kuro, ṣugbọn o maa ni nnkan ti wọn ri ki wọn too fi ẹsun ikowojẹ kan an. Bo ba jẹ loootọ ni pe ọkan rẹ mọ pe oun ko kowo jẹ, emi wo o pe o yẹ ko na tan fun awọn ti wọn n beere ẹjọ lọwọ ẹ yii, ko fi gbogbo iwe han wọn. O ṣee ṣe ko jẹ wọn kan fẹẹ fi koba a ni, ṣugbọn bi oun naa ko ba rin ni bebe ẹ, wọn ko ni i fi lọ ọ. Tori ẹ lemi ṣe wo o pe o yẹ ko fi gbogbo bi ọrọ ṣe n lọ han awọn ọmọ Naijiria, ko wẹ ara rẹ mọ bi ko ba mọ nipa ẹsun ti wọn fi kan an yii. Ṣugbọn ki emi ti mi o si nile-ijọba maa sọ boya o ko owo jẹ tabi ko ko o jẹ, mi o le sọ aridaju boya ootọ ni o ṣe ohun ti wọn lo ṣe, amọ bi aye o ba ri, wọn ko ni i wi.

 

 

 

 

 

 

 

 

 

 

 

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.