Kin ni Yoruba fee fi asaaju se gan-an?

Spread the love

Ore mi kan kowe si mi. O be mi ki n ma binu rara bi oro ti oun ba so ba da bii afojudi, o ni ko ye oun ni, ki i se pe oun fee huwa afojudi kankan. O ni ki n ma fi nomba ati oruko oun sita, nitori oro ti oun fee so le ma ye awon mi-in, oun ko si ni i fe ki won bu oun. Bi okunrin yii se wi ni n oo se, n ko ni i binu, bee ni n ko si ni i fi oruko re sita, alaye oro la o jo  se. Ohun ti mo se fee salaye ni pe awon mi-in naa ni iru ibeere okunrin yii lokan, nigba ti oro ko ba si ye won, tabi ti won ko ba reni fun won lesi, won yoo so kinni naa di agidi, won yoo maa binu seni ti ko ye ki won binu si. Ore mi yii ni oun fee beere ni, O ni, “Kin ni Yoruba fee fi asaaju se gan-an? Iru asaaju wo ni Yoruba tun n wa ti Olorun ko ti i se fun won? Se bi Asiwaju ni gbogbo Yoruba n pe Tinubu, asaaju wa lawa mo on si, eyin nikan lo da bii pe e ko feran re!”

Se eyin naa ri i pe o ye ki n binu die, abi nigba ti ore mi yii ni n ko feran Bola, to si je ohun ti mo fi soro lose to koja niyen. Sugbon mo ti jejee pe n ko ni i binu, alaye ko ti i to ni, a oo si tubo se e. Ibeere akoko ti ore mi beere ni n oo dahun saaju, iyen naa ni pe kin ni Yoruba fee fi asaaju se gan-an. Fun eni to ba ni iru eyi lokan, mo fee se apeere kekere kan. E wo maaluu bi won ti maa n da kiri goo goo, ti won le pe ogun ti won le pe ogbon tabi ju bee lo. E je ka fi oju inu wo o bi ko ba si Fulani kan soso ti yoo da won, ti yoo dari won sibi to ye ki won gba, to le ko won lo sibi ti ounje wa, ti yoo si tun fun won lomi. Die lawa eeyan fi yato si maaluu, laakaye tiwa lo kan ju tiwon lo; bo ba je ti agbara, gende meloo lo ni iru agbara ti ako-maalu kan ni. Bi Fulani ti n da maaluu re ti ki i sina yii, bee lasaaju maa n dari iran awon eeyan kan.

Gbogbo ohun to ba sele si iran awon eeyan kan, tabi eya kan, tabi ijoba ilu kan tabi orile-ede, tabi ileese kan, asaaju lo fa a. Eyi ni idi ti orile-ede kan yoo fi dara, ti awon kan ko ni i dara, ti iran kan yoo maa dagba, ti awon kan yoo maa reyin, tabi ti ileese kan yoo dara, ti okan yoo si baje pata. Ohun gbogbo lowo asaaju ni. Bi asaaju ba se fe lawon ti yoo ba a sise yoo se ba a sejoba re, ko sohun teni kan le se. Ohun to daju saka, ti gbogbo awon ojogbon aye si fowo si ni pe ibi kan ko ni i dara bi asaaju won nibe ko ba dara: bo je orile-ede, bo je iran, bo si je ileese nla. Bi oro mi ko ba ye yin, e je ki n tubo se alaye. Nigba ti Olorun da aye ati orun, o fi ara re se asaaju ati oga wa titi doni. Eyi lo se je pe ti oro aye ba si su gbogbo eda, ibi kan naa ti a oo dori ko ni odo Olorun. Bi Olorun si se fe ki aye ri lo ri, bi kaluku si se n to o naa niyen.

E wo awon elesin Kristeni, bi asaaju won, Kristi, se fe ki esin naa ri lo ri: ilana to gbe kale naa lawon ti won n tele n to titi doni yen. Bakan naa ni Anobi Muhammed, bo se fe ki awon musulumi maa kirun, to fe ki won maa sin Olorun, bee naa ni won n se e titi doni yii. Ona ti asaaju kan ba la ni gbogbo awon ti won ba tele yoo to, koda awon ti won ko ba to ona naa, awon ti won ba ku nibe le lu won pa, tabi ki won le won pada leyin won. Bo ba se pe nigba ti Jesu wa saye, to ba so pe ki awon ti won tele oun ma gbadura, ki won kan maa juwo si Olorun loke lasan ni, ohun ti won yoo maa se naa niyen. Bo ba si je Anobi lo so fawon eeyan tire naa pe ki won ma kirun, omi lasan ni ki won maa da sile, o daju pe ko seni kan ti yoo pada de ti yoo ni oun fee se toun loto, afi to ba da esin tire sile nikan lo ku.

E je ka wo awon soja ti won n loo jagun. E wo bi won ti maa n po to, bawo ni yoo ti ri ti won ba waa so pe ki soja kookan maa se ife inu re, ki soja kookan maa se ohun to ba wu u, ko maa pa eni to ba fe. Nitori pe soja kan ko kan le se ohun to ba wu u ni won se maa n ni asaaju kan, asaaju naa ni yoo si maa pase fun gbogbo won, koda ki won je egberun meji loju kan. Ase ti olori awon ologun yii ba pa lawon soja gbogbo yoo tele, ko seni ti yoo se nnkan mi-in ninu won. Olorun lo ti feto si gbogbo aye bee, pe iran kan ko ni i wa ko ma ni asaaju tiwon. Ko si iran tabi eya ti ko nilo asaaju, nitori bi awa omo eniyan ba ti pe meji meta nibi kan, agaga ti a ba n lo si bii ogun tabi ju bee lo, bi a ko ba ni asaaju ti yoo dari wa, ti a oo gboro si lenu, basubau ni a o maa se, regberegbe ni a o si maa rin titi ti a oo fi fese ara wa rin wo ibi ti ko dara.

Gbogbo aburu to wa ni Naijiria loni-in, gbogbo ija to ba n waye laarin Hausa, Ibo ati Yoruba, asaaju akoko lo ti gbin igi oro yii sile, ko si kuro titi doni, nitori ohun to fe nigba naa ni. Ni gbogbo igba ti Yoruba n gba gbogbo ile lawon mi-in, iyen gbogbo agbegbe to waa di ile Yoruba loni-in yii, oruko asaaju kan naa ni won fi n gba a. Oruko Oduduwa ni. Awon kan sa ti wa ni Ife ki Oduduwa too de, awon kan wa ni Abeokuta ki Alake to debe, awon kan wa ni Ilesa ki Owa too de, awon kan wa ni Ijebu ki Awujale too ba won lalejo, awon kan si ti wa ni Remo ki Akarigbo too loọ ba won. Sebi awon eeyan kan lo wa nibi ti a n pe ni Oyo loni-in ki Alaafin too de, sugbon ni gbogbo ibi ti awon omo Oduduwa ba lo, oruko asaaju Yoruba yii ni won n je nibe, ade re ni won n de, idi si niyi ti ko seni to n yo won lenu nibikibi ti won ba de.

Mo ti so o, mo si n tun un so, awon Fulani ni asaaju, awon asaaju won lo si n dari won. Eni to ba n ka awon iwe idagbasoke aye, World Development, yoo maa ri awon ohun to n sele lagbaaye nibe, yoo si mo ohun ti awon ojogbon aye n so nipa awon asaaju Fulani wonyi, ati erongba won. Eyin ko kiyesi ni, nigba ti awon Boko Haram ba ji awon omo olomo gbe nile wa, e ko se beere ibi ti awon olori ijoba Naijiria n lo, ati awon ti won n fun lowo lohun-un ti won fi n tu awon omo ti won ba ji ko yii sile. Awon eeyan ni won sa n gbowo lowo won ki i se eegun, bee ni ki i se oku-orun. Eyi tumo si pe awon kan ni won ran won nise, tabi pe awon kan ni won je olori fun won. Awon olori to n dari won ko wa soju ogun, awon jagunjagun won ni won ko sita, awon olori wa nibi kan. Yoruba ko ni asaaju, iyen loro wa ko se niyanju.

Nje e ri esi idanwo awon omo oniwee-mewaa ti won se koja ti won sese gbe sita, e wo ajoreyin ti ile Yoruba jo ninu eto eko, gbogbo ipo akoko pata, awon ipinle Ibo ni won mu un, ninu awon to si paasi, awon ipinle Osun ati Oyo wa ni ipo kerindinlogbon, awon ni won reyin ju lati ile Yoruba. Bee nigba aye Awolowo, ko si adugbo naa ni Naijiria ti i saaju wa nidii eto eko, ko see se ni. Ni bayii, won fee gba ipo kin-in-ni nidii eto eko iwe ti a n pariwo pe a ni kuro lowo wa; awon Ibo ti gba ise okoowo; awon Hausa ti gba agbara ijoba. Ki leyin ro pe o de ti a fi n dero eyin bayii nibi ti a ti je asaaju tele. Sebi nitori pe a ko ni asaaju rere kan ni. Aguda ko je labe geesi la n ba ka; agufon ko foribale fenikan lorin ti a n ko. Aifagba feni kan ki i je kaye roju, Yoruba fee maa rin kiri lai ni asaaju, abo e naa ree o!

Ma a salaye iru asaaju ti Yoruba fe lose to n bo, ati idi ti iru awon Bola yen o fi ni i se asaaju wa. Awon naa ko tie je sun mobe!

Gbogbo eyin ti e kowe ti e n daruko Ooni, pe awon ni asaaju ti e mu ni mo ri, mo si fee so fun yin pe ohun to see se pelu ase ati atileyin awon oba to ku ni. Ati pelu, ki n so fun yin pe awon agbaagba wa naa ko sinmi, won n ba ise lo loju mejeeji, awon naa si ti fowo si i pe loooto la nilo asaaju gidi kan fun iran wa. A o maa tesiwaju lose to n bo. Mo n reti awon atejise yin lori oro yii, n oo si farabale ka won daadaa.

 

(81)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.