Kin ni wọn waa n parọ buruku bayii fun wa si

Spread the love

Bi kinni kan ba ṣẹlẹ ni Naijiria yii to ba buru, tabi ti awọn Boko Haram ba jẹ ilẹ Hausa ati apa kan Naijiria run, ko sẹni ti aye yoo mu si i ju awọn eeyan bii Lai Muhammed, awọn eeyan bii Garba Shehu, ati gbogbo awọn ti wọn n ba ijọba yii purọ nla nla faraalu lọ. Wọn yoo mu Yẹmi Ọṣinbajo ti i ṣe Igbakeji Aarẹ ilẹ yii, wọn yoo si mu Aarẹ Muhammadu Buhari. Lara aṣeyọri ti ijọba yii n sọ pe awọn ti ṣe ni ti ogun awọn Boko Haram yii. Ki ẹ too sọrọ kan bayii ni wọn yoo ti ni awọn ti ṣẹgun Boko Haram, awọn ti rẹyin wọn, wọn ko le gberi mọ, wọn ko le ṣe kinni kan mọ, agbara ti bọ lọwọ wọn. Awọn ọga ṣọja ti wọn ko de oju ogun yii naa yoo maa purọ, wọn yoo ni awọn ti lọ sibẹ, awọn si ri awọn Boko Haram ti wọn n sa lọ lai le duro gbe ibọn wọn. Gbogbo ohun ti wọn sọ fun wa, irọ gbuu, irọ nla, ọrọ to le ko ba gbogbo orilẹ-ede yii lo n tẹnu wọn jade. Tabi ki lo wa ninu ki ijọba sọ ootọ ọrọ fun araalu. Ṣebi bi wọn ba sọ ootọ fun wa, kaluku yoo le dide iranlọwọ, kaluku yoo le ṣe gbogbo ohun to ba le ṣe lati ri i pe Boko Haram ko le oun jade lorilẹ-ede baba oun. Bi ijọba ba sọ bi ọrọ yii ti le to, ati bi apa wọn ko ṣe ti i ka a, ọpọ eeyan ni yoo gbe ọrọ oṣelu ti, agaga awọn ti wọn ki i ṣe oloṣelu rara, ti wọn yoo si wa ọna gbogbo lati ran ilẹ yii lọwọ. Amọ nigba ti awọn eeyan ijọba yii ba bẹrẹ irọ buruku, ti wọn ni ko si wahala kankan lati ọdọ awọn Boko Haram mọ, ki waa ni araalu yoo ṣe. Ni gbogbo orilẹ-ede to ba n koju iṣoro bayii, ajọṣepọ to le koko lo maa n wa laarin ijọba pẹlu araalu ati laarin awọn eeyan gbogbo to ba wa lorilẹ-ede naa. Awọn Boko Haram yii ti mọ pe ko si iṣọkan ni Naijiria, ẹsin ati oṣelu ti pin wa niya pata, wọn si ti mọ pe nibi ti ko ba ti si iṣọkan laarin awọn eeyan, ko sẹni to le jagun ko ṣẹgun nibẹ. Eyi ni wọn ṣe fi Naijiria ṣebugbe, ohun ti wọn si ro naa lo n ṣẹlẹ laarin wa yii o. Ṣugbọn ijọba Buhari lo n ba ọrọ yii jẹ, nitori wọn ko sọ ododo faraalu, wọn ko jẹ ki awọn eeyan mọ ohun to n ṣẹlẹ, irọ ojoojumọ ni wọn n pa fun wa. Lọjọ wo l’Ọlọrun yoo gba wa lọwọ awọn opurọ eeyan yii! Gbogbo ẹni to ba fẹẹ ko Naijiria si wahala, to fẹ ki Naijiria di igbagbe nitori irọ pipa ati eke ṣiṣe, afi ki Ọlọrun ba wa dojuti wọn, ko gba gbogbo agbara ti wọn ni pata kuro lọwọ wọn.

 

 

(11)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.