Kin ni wọn fẹẹ fi Fayoṣe ṣe bayii o

Spread the love

EFCC ki i kuku ṣe ile iku, ẹni ijọba ko ba fẹran ni wọn n ju sibẹ. Iyẹn lo ṣe jẹ nigba ti wọn n mu Ayọ Fayoṣe lọ sibẹ, ẹrin lo n rin, to si tun da aṣọ tuntun fun irin-ajo rẹ, to kọ ọ sibẹ gadagba pe, “EFCC, mo ti de o!” Awọn eeyan sọrọ lori aṣọ ti Fayoṣe da ati yẹyẹ to ṣe lọ si ọdọ awọn EFCC, wọn ni aye ti bajẹ, ẹni ti wọn mu lole to tun n rẹrin-in, to tun n fọlọpaa to mu un ṣe yẹyẹ, wọn ni olori awọn ọdaran ni. Loootọ ka ma tan ara wa o, awọn ti wọn si n sọrọ mọ, wọn mọ pe loootọ ni Fayoṣe jale, o si ti pẹ to ti n ja kinni naa. Lasiko ti wọn yoo ṣe idibo ti wọn ṣe lọ ni 2014 ni ole-jija naa waa le, Ọbanikoro lo n ha owo kiri fun wọn. Bẹẹ ni Fayoṣe ko fi gbogbo owo naa ṣeto ibo tan, ṣekan-ko-mi o tun ṣekan-kora-rẹ lo fi kinni ọhun ṣe. Bo ti fowo ṣeto idibo lo ku eyi to ku na, o ni nibi ti a ti n wo ọlọkun-un-run la ti n wo ara ẹni. Ni orilẹ-ede Naijiria yii la ti n gbe ọrọ gẹgẹ, bi oloṣelu kan ba ṣiṣẹ ijọba, to sin ilu, koda ko jẹ ogun ọdun lo fi sin wọn, bi wọn ba ti ri i pe ole ni, wọn yoo pada mu un ni, iye ẹwọn ọdun to ba si tọ si i ni wọn yoo fi i si. O di ọjọ ti a ba ni iru eto bẹẹ nilẹ yii ki awọn oloṣelu too mọ pe bi awọn ba wa nipo, awọn ko gbọdọ jale, tabi pe ti wọn ba fẹẹ ṣeto idibo, awọn ko gbọdọ lọọ ji owo kankan lati fi ṣe e. Iyẹn ni pe bi EFCC ba ri ẹjọ to dara to mọ Fayoṣe lẹsẹ, to ba ṣẹwọn, ko ṣe kinni kan, iya ẹṣẹ rẹ lo jẹ. Ṣugbọn ta ni yoo sọ Fayoṣe sẹwọn, ṣe awọn EFCC yii naa ṣaa! Awọn to jẹ alaboosi ati oniranu lo pọ ninu wọn, aja lasan ni wọn, ẹni ti ko ba si fẹran Buhari tabi to ba ti bu Buhari nikan ni wọn n gbo mọ. Fayoṣe iba maa rin falala bayii ni, bo ba jẹ nigba to wa nipo, o n sọ pe Buhari ni igbakeji Ọlọrun. Ẹri wo tiẹ ni EFCC yoo lo lati fi ba Fayoṣe ṣẹjọ bayii! Abi ki i ṣe funra wọn ni wọn n ba ẹri ọhun jẹ bayii. Bi ile-ẹjọ ba waa fa a lọ ti wọn fa a bọ, wọn yoo ni ki Fayoṣe maa ba tirẹ lọ, ko lẹjọ kan lati jẹ. Wọn tilẹ le tun ni ki EFCC sanwo wahala fun un. Bẹẹ Bọbọ jale, o kowo mi bii ki-n-la, ṣugbọn EFCC funra wọn ti bẹri jẹ. Ṣiọ, awọn asindẹmade gbogbo!

(33)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.