Kin ni wọn fẹẹ fi awọn ibọn ti wọn n ko wọle yii ṣe o

Spread the love

Ọlọrun nikan ni yoo gba wa ni ilẹ Yoruba bayii, nitori ọrọ naa ko yatọ si bii igba ti awọn kan ti mura lati pa ọpọlọpọ ọmọ Yoruba bi wọn ba le da wahala kankan silẹ nibẹ. Ni gbogbo igba ni wọn n ko ibọn ati awọn ọta ibọn ati awọn ohun ija oloro mi-in wọle, Eko ati agbegbe rẹ ni kinni naa si n wọle si, bẹẹ ni ko sẹni to mọ awọn to n ko wọn wa. Ọsẹ to kọja yii lawọn ṣọja tun ri awọn mọto akoyọyọ nla mẹta gba, o kan jẹ pe wọn ko ko yọyọ lọtẹ yii, ibọn ati ọta ibọn lo kun inu wọn fọfọ. Lati ọpọ igba ni wọn ti n ko awọn kinni yii wọlu, bẹẹ ni wọn ki i ri awọn ti wọn n ko wọn. Awọn ti wọn ko mọto terela mẹta yii wọle, awọn ṣọja to da wọn duro ni awọn ko ri wọn, wọn ni gbogbo wọn lo sa wọgbo lọ. Nibi yii ni ki gbogbo ọmọ Yoruba, nibikibi ti wọn ba wa pata ti fura. Ki wọn maa ṣọ ara wọn paapaa, ki wọn si maa wo awọn alejo ti wọn yoo ba gba sile, tabi awọn ti wọn ba n gbe adugbo wọn, tabi awọn ti wọn ba n rin kọ́sẹkọ̀sẹ ni adugbo daadaa. Ko sẹni to mọ ohun ti awọn ti wọn n ko ibọn wọ ilẹ Yoruba yii fẹẹ fi wọn ṣe, ṣugbọn ohun ti gbogbo eeyan mọ naa ni pe ibọn ki i bimọ rere. Bẹẹ ni Yoruba ko si ni ibọn nile, wọn ko ni ọta, koda, wọn ko ni ohun ija, nitori bi ọmọ Yoruba ba n lọ, bi ọbẹ ẹlẹran lasan ba wa lọwọ rẹ, ọlọpaa yoo mu un, wọn yoo ni ọdaran ni, bẹẹ ni mọla yoo maa rin kiri pẹlu ida oloju meji lọwọ rẹ, ọmọ Ibo si mọ bi yoo ṣe tọju ibọn tirẹ naa ti ẹnikẹni ko ni i ri i. Bi ọwọ ba ba Hausa, wọn yoo ni aṣa ilẹ wọn ni ka maa mu ida kaakiri, bo si jẹ Ibo ni wọn ki mọlẹ, ki ọrọ too di ariwo, awọn eeyan rẹ yoo ti gba a jade. Bi ọrọ ti waa ri yii, ki gbogbo ọmọ Yoruba maa fura, nitori oju ni alakan fi n ṣọri o. Awọn ti wọn n ko ibọn wọlu ko ro daadaa si wa, iyẹn lawa naa ko ṣe gbọdọ sun asunpara. Ọlọrun Ọba to ni ọjọ oni, yoo gbe wa leke gbogbo wọn.

 

(56)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.