Kin ni ti Wasiu Ayinde ninu ọrọ yii, ẹ jẹ kilọ fun un

Spread the love

Lọjọ ti alaye ti daye ni awọn olorin ti wa nilẹ wa, awọn oṣere ti wọn n kọrin to wulo, ti wọn ku tan ti iṣẹ ọwọ wọn ko parẹ, nitori ọgbọn ati laakaye ti wọn fi kọ orin wọn. O ti n sunmọ ọgọta ọdun ti Sunny Ade ti lorukọ nidii orin nilẹ yii, bẹẹ lo si ri fun Ebenezer Obey naa. Sikiru Ayinde to da ere Fuji ti Wasiu Ayinde Marshall n kọ loni-in yii silẹ naa ṣe iwọnba to le ṣe, bẹẹ si ni Kollington Ayinla wa laye to n ṣe iṣẹ orin rẹ lọ. Meloo meloo lawọn olorin to ti wa niluu ti wọn si ti ṣe oriire rẹpẹtẹ nidii iṣẹ orin. Ṣugbọn niṣe lo jẹ ko si olorin kan to daya de oṣelu bii Wasiu Ayinde Marshall ṣe daya de oṣelu yii, bẹẹ ni ki i ṣe pe awọn olorin wọnyi ko fẹran owo gẹgẹ bo ti jẹ pe Wasiu fẹran owo, wọn fẹran owo daadaa, ṣugbọn wọn lo laakaye, wọn mọ pe awọn owo kan wa to jẹ owo majele ni, olorin to ba lọgbọn lori ki i dedii ẹ rara. Olorin to ba n jẹ iru ounjẹ ijẹkujẹ awọn oloṣelu, to n gba owo lọwọ wọn, tabi to n fi han gbogbo aye pe ẹgbẹ ti oun n ṣe niyẹn, o n gbẹ koto jinjin fun ara rẹ ni, ọjọ kan n bọ ti wọn yoo ti i sinu ẹ, bi wọn ba si ti i si i, yoo ṣoro fun un gan-an lati jade. Oṣere da bii ọba ilu ni, bi ọba ilu ba tilẹ fẹran ẹgbẹ kan ju ẹgbẹ keji lọ, ko gbọdọ fi han, nitori ọmọ rẹ ni gbogbo wọn. Bẹẹ naa ni olorin, bo ba fẹran ẹgbẹ kan ju ẹgbẹ keji lọ, ko gbọdọ fi han, nitori ko mọ ibi ti awọn ololufẹ rẹ (fans) rẹ pọ ju si ninu wọn. Bi Wasiu ba lọ si Ekiti to n ṣepe fun awọn ti wọn ba dibo fun PDP, njẹ oun mọ iye awọn ti wọn jẹ ọmọ PDP ati iye awọn mọlẹbi wọn ti wọn n ra awo orin oun ninu iṣẹ aje ati owo wọn ti wọn ba pa. Bi wọn ko ba riṣe mọ, ti wọn ba ṣofo gẹgẹ bi Wasiu ti ṣepe, ṣe ko ni i kan oun naa bo ba ya ni. Eelo ni awọn APC yoo fun un, iṣẹ kọntiraati (Contract) meloo ni wọn yoo si gbe fun un ti yoo tori rẹ sọ ọpọlọpọ awọn ololufẹ rẹ nu. Tabi Wasiu ro pe titi aye ibi ti agbara wa loni-in yii naa ni yoo wa ni! Rara o, aye ko ri bẹẹ, ki awọn Tinubu yii too de, awọn kan lo ti wa nipo, bi awọn naa si fẹ wọn kọ, wọn yoo lọ ni. Olorin ki i lọ sibi kan, olorin aa maa wa titi aye, koda lẹyin to ba ti ku tan. Tabi ile meloo ni wọn ti n gbọ orin Barrister loni-in, meloo lawọn ti wọn n gbọ orin Ayinla Ọmọwura to ti ku lati bii ogoji ọdun, meloo lawọn ti wọn si n gbọ orin Haruna Iṣọla. Lọjọ ti awọn araalu ba ji dide, ti wọn mọ pe ole lawọn oloṣelu yii, ti wọn si mọ pe wọn n tan awọn ni, ati pe Wasiu Ayinde wa ninu awọn to tan wọn fun wọn, epe ni wọn yoo maa ṣẹ fun oun naa, aburu ti yoo si ba a yoo ju ere to n ri nibi orin oṣelu to n kọ kiri bayii lọ. Tabi lọjọ ti ijọba ba bọ sọwọ awọn alatako to n bu yii, ṣe ko mọ pe ko na wọn ni ọjọ kan lati tẹsẹ bọ gbogbo ohun to ko jọ to n jọ ọ loju yii ni, ẹni to ba mọ aburu awọn oloṣelu ki i fi ọrọ wọn ṣere o. Ẹni to ba mọ oju Wasiu Ayinde ko ba a sọrọ, bi oun naa ba si n gbọ ko kilọ fun ara rẹ, ohun ti olorin kan ki i ṣe loun n ṣe yii o, ohun to si le fa wahala gidi fun un lọjọ iwaju ni.

(2204)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.