Kin ni Sai Baba funra ẹ n wa kiri

Spread the love

Lọsẹ to kọja, lojiji niroyin naa jade, wọn ni Aarẹ Muhammadu Buhari n sare lọ si London. Ki lo tun n lọọ ṣe, wọn ni awọn dokita to n tọju ẹ ni ko wa, ko sare wa fun ayẹwo, boya ko si waa gba itọju kan ni. Awọn eeyan binu gan-an ni, ọrọ naa si ka wọn lara. Awọn kan tilẹ sọ ọrọ naa di yẹyẹ, wọn ni batiri ti wọn fi gbe ẹmi baba naa duro lo ti wiiki, wọn ni batiri ti lọọlẹ, o fẹẹ pafuka, iyẹn ni baba ṣe sare lọ. Iyẹn tiẹ le jẹ ọrọ awada, ṣugbọn eeyan ko le ba awọn ọmọ Naijiria wi pe inu ṣe n bi wọn pe Buhari ti tun sare lọ siluu oyinbo lati lọọ ri dokita. Awọn eeyan kan le ro pe awọn ti wọn n binu yii daju ni, pe ṣe wọn ko fẹ ki Buhari gbadun ni. Ṣugbọn ki i ṣe bẹẹ, apẹẹrẹ pe bi Buhari ba wọle ibo ọdun 2019, ọpọlọpọ asiko to yẹ ko fi ṣejọba, ilu oyinbo ni yoo tun maa paara pe oun n lọọ gba itọju niyẹn. Idi ni pe arun to n ṣe e ki i kuku i ṣe arun kan pato, arun agba ni. Ko sohun to yẹ ki Buhari tun maa wa kiri bayii, eyi to ṣe lọrọ ijọba Naijiria to, ko pa ẹnikẹni lara bi baba naa ba jokoo sile rẹ, to n gba owo ifẹyinti rẹ, to si n tọju awọn ọmọ ọmọ rẹ nile. Buhari n paara ilu oyinbo bayii, ṣebi nitori pe owo ọfẹ lo n na lọ na bọ ni, owo ijọba lo n na, ki i ṣe owo ara tiẹ. Abi ẹẹmeloo lo lọ si London lọọ gba itọju nigba ti ko ṣe olori ijọba Naijiria. Ṣugbọn eyi to bi awọn eeyan ninu ju ni pe ọsẹ to lọ lọhun-un, Buhari wa ni London, o si ri dọkitọ yii nigba naa, ki lo de ti wọn ko ṣe gbogbo ohun ti wọn fẹẹ ṣe fun un nigba naa, kin ni wọn n fi owo awọn ọmọ Naijiria ṣofo si. Bi ara rẹ ko ba ya, ki wọn tọju rẹ, ko si maa pada bọ, ewo ni ko maa lọ ko maa bọ. Bo ti n lọ yii, oun ati awọn ero lẹyin ni, iye ọjọ to ba si lo ni ẹronpileeni Naijiria yoo fi duro ti i niluu oyinbo nibẹ, owo nla ni wọn yoo si maa san lojoojumọ nibi ti wọn ba gbe e si. Bẹẹ titi di bi a ti n wi yii, ko si ọmọ Naijiria to le sọ pato pe aarun bayii lo n ṣe aarẹ wọn, bẹẹ ni wọn ko si mọ iye owo to n na lori aiya ara yii.  Ko yẹ ko ri bayii rara, nitori bẹẹ kọ ni wọn n ṣe lawọn orilẹ-ede agbaye gbogbo. Bi ara Purẹsidẹnti oyinbo ko ba ya, funra rẹ ni yoo kede, ti yoo si ṣalaye ohun to n ṣe e, awọn eeyan rẹ yoo si sọ nibi to ba ti nawo ijọba pe iye bayii lo na si i. Ṣugbọn tiwa kọ niyẹn nilẹ yii, aye ṣenji yii tilẹ waa le. Ohun to n bi awọn ọmọ Naijiria ninu niyẹn. Bo ba ya, wọn yoo ni wọn fẹẹ ri bii Amẹrika, wọn fẹẹ ri bii London, wọn ko si niwa Amẹrika tabi ti London, iwa bii ti alailaju lo kun ọwọ wọn. Ki Buhari sọ arun to n ṣe e fun gbogbo ọmọ Naijiria, ko sọ iye owo wa to ti na lori arun yii, ko si ṣalaye ohun ti awọn dokita rẹ wi fun wa. Ki Buhari ma fowo wa ṣofo mọ, ohun ti ko daa ko lorukọ meji, ko daa ni.

Bẹẹ lawọn ti wọn n tẹle e ko yee purọ

Bẹẹ lawọn ti wọn n tẹle e kiri ko yee purọ, wọn yoo ṣa maa pa irọ oriṣiiriṣii ni. Bi gbogbo eeyan ba ri nnkan dudu bayii, ki ilẹ si too mọ, awọn eeyan naa yoo si sọ ọ di funfun, wọn yoo si maa ṣepe, wọn yoo maa bura, wọn yoo ni nnkan funfun ni, o da awọn loju. Bẹẹ irọ ni wọn n pa. Lasiko ti wọn n ṣe kampeeni lọdun 2015, Buhari lọ si London lati ba wọn sọrọ nibẹ, wọn si bi i leere pe bawo ni yoo ṣe ṣe eto ilera ati eto ẹkọ si bo ba wọle. Ni Buhari ba dahun bayii pe: “Kin ni iyatọ laarin emi ati awọn ti wọn yan mi sipo? Ko siyatọ kankan. Ki lo de ti aarẹ Naijiria ko le wọ ẹronpileeni pẹlu awọn ọmọ Naijiria to ku? Ki lo de ti mo maa maa kiri ilu oyinbo pẹlu ero rẹpẹtẹ lẹyin mi, ti a maa maa nawo araalu danu? Kin ni mo fẹẹ wa lọ siluu oyinbo lati lọọ gbatọju nigba ti awa o ba ṣe awọn ileewosan tiwa ko dara? Kin ni mo fẹẹ wa lọ? Kin ni awa ti a n ṣejọba fẹẹ maa ran awọn ọmọ tiwa niluu oyinbo si nigba ti a ko ba le ṣe awọn yunifasiti tiwa ko dara?” Bi Buhari ṣe da awọn ti wọn n beere ọrọ lọwọ rẹ lohun ni London ninu oṣu keji, ọdun 2015, niyẹn. Bo ti n sọ bẹẹ lawọn eeyan n pariwo, ti wọn n sọ pe iru aarẹ ti awọn n fẹ ree, oun nikan lo le tun Naijiria ṣe. Ṣugbọn nigba ti Buhari de ti awọn ọmọ rẹ bẹrẹ si i jade ni yunifasiti ilu oyinbo, awọn eeyan mi kanlẹ. Paripari rẹ si ni nigba ti aiya ara rẹ bẹrẹ, to jẹ lati igba naa, ko nibi meji to n lọ ju ilu oyinbo lọ. Nigba naa lawọn eeyan ranti awọn ọrọ rẹ, wọn si bẹrẹ si i gbe e jade. Kia lawọn ti wọn n ba a ṣiṣẹ, awọn Garba Sheu ati Fẹmi Adeṣina, ti jade, wọn ni ko sigba ti Buhari sọ bẹẹ, bii pe ki i ṣe loju gbogbo aye lo ti sọ ọ, ti wọn si gba ohun rẹ silẹ. Buhari ko ṣe oore funra rẹ, awọn ti wọn n tẹle e ko ṣe oore fun un. Ounjẹ ti awọn n jẹ lẹnu lọwọ ti wọn ko fẹ ko bọ ni wọn ko ṣe le ba a sọ ootọ ọrọ, wọn kan fẹẹ tan baba onibaba pa ni. Eleyii o daa. Ṣugbọn ki baba onibaba paapaa ronu ara rẹ wo, ko sohun to yara fabuku kan eeyan bii aṣeju, ki Buhari ma ṣe aṣeju, nitori agbalagba to ba wẹwu aṣeju, ẹtẹ ni yoo fi ri o.

 

(35)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.