Kin ni Oshiomhole ṣe fun wọn gan-an

Spread the love

Awọn kan n gbe igbekugbee kan jade bayii pe Adams Oshiomhole, alaga ẹgbẹ APC, ko gbọdọ wọ ibikibi ni ipinlẹ Zamfara, wọn ni bo ba debẹ, awọn yoo ṣe e jatijati ni. Awọn ti wọn n sọrọ yii ko sọ pe gomina ibẹ, Abdul-aziz Yari Abubakar, funra rẹ lo sọ bẹẹ, ṣugbọn nigba ti awọn eeyan ibẹ sọ pe ki i ṣe oun lo sọrọ yii, wọn ni awọn oloṣelu APC ti inu n bi ni. Inu n bi wọn pe Zamfara ko ri ẹni fa kalẹ ninu ibo abẹle ẹgbẹ naa to kọja lọ, nitori ẹni ti gomina naa fẹ ko wọle nibẹ ko raaye wọle. Zamfara nikan kọ ni eleyii ti ṣẹlẹ, awọn oniroyin ti sọ nigba kan pe Aishat, iyawo Aarẹ Muhammadu Buhari, ti sọ pe oun ko gbọdọ ri Oshiomhole ni Aso Rock, nitori pe aburo tiẹ naa to fẹ ko ṣe gomina ni Adamawa ko wọle. Bakan naa lo ri l’Ogun, o ri bẹẹ ni Imo, nibi ti wọn ti ni ki ọkunrin yii mu ori wa ko fi ọrun silẹ. Kinni kan lohun to ṣẹlẹ yii fihan, iyẹn naa ni pe ko si ẹgbẹ oṣelu gidi mọ. Nigba ti ẹgbẹ oṣelu n jẹ ẹgbẹ oṣelu, aṣẹ yoowu to ba ti ọdọ alaga ẹgbẹ jade, bẹẹ naa ni yoo ri, ẹnikẹni ki i yi i pada, awọn alaga ẹgbẹ si da bii Ọlọrun fun gbogbo ọmọ ẹgbẹ wọn. Awọn kan le sọ pe ko yẹ ko ri bẹẹ, ṣugbọn ohun ti eyi mu wa ni pe ẹgbẹ oṣelu maa n ni iṣọkan nigba naa ju bi a ti wa yii lọ, ẹgbẹ maa n fi gbogbo ara ṣiṣẹ fun araalu ju bo ṣe ri bayii lọ. Ohun to ba wu kaluku lasiko yii lo n ṣe, wọn le bu iya alaga ẹgbẹ, wọn le pe e ni ole ni gbangba, kaluku yoo si maa lo agbara tirẹ le e lori, wọn ko bọwọ fun ipo alaga ẹgbẹ wọn. Lasiko yii, eleyii ko tilẹ dara fun ẹgbẹ APC, bo ba jẹ loootọ lẹgbẹ naa n mura lati ṣe aṣeyori lasiko ibo to n bọ yii. Awọn ti wọn n ro pe ibo to n bọ yii ko to nnkan, orukọ Buhari yoo gbe ẹgbẹ APC wọle, o jọ pe wọn ko mọ ohun to n lọ, wọn ko si mọ iru ara ti awọn alatako n mu. Bẹẹ ni ko si ohun to yara fun alatako lagbara, ti yoo si fọ ẹgbẹ oṣelu to lagbara, bii ainiṣọkan awọn ọmọ ẹgbẹ naa, pẹlu awọn aṣaaju wọn. Bi awọn gomina ti wọn n binu yii ko ba ṣiṣẹ fun APC, nnkan le bajẹ mọ Buhari lọwọ. Bi awọn aṣaaju APC wọnyi ba fẹ aṣeyọri ẹgbẹ wọn ni tootọ, dandan ni ki wọn tẹle Oshiomhole ti wọn fi ṣe alaga ẹgbẹ wọn, eyi ti wọn n ṣe yii ko dara rara, ohun to le ko ba ẹgbẹ wọn ni. Oṣelu ko tilẹ yẹ ko le to bayii bo ba jẹ iṣẹ ilu naa la fẹẹ ṣe loootọ. Ko yẹ ko le to bẹẹ rara o. Tabi iru oṣelu wo la n ṣe! Iru oṣelu wo ni wọn n ṣe ni Zamfara ti wọn ni wọn ko gbọdọ ri Oshiomhole nibẹ? Ṣe ki i ṣe ọmọ Naijiria ni? Tabi ṣe awọn ni ọlọpaa ni? Iru oṣelu jakujaku wo leleyii na!

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.