Kin ni Oluṣẹgun Mimiko n wa kiri gan-an o?

Spread the love

Nigba ti eeyan ba gbọ awon oyinbo bọlugi to n bọ lẹnu gomina ipinlẹ Ondo tẹlẹ, Dokita Oluṣẹgun Mimiko, tọhun yoo ti mọ pe kirakita ko kan ọla, ka ṣiṣẹ bii ẹru ko da nnkan kan. Idi ni pe gbogbo igba ti ọkunrin yii yoo fi ṣe gomina lẹẹmeeji to ṣe, oyinbo rẹ ko to bayii, koda nigba ti yoo fi ṣe minisita, oyinbo rẹ ko pọ to bayii rara. Ṣugbọn ni asiko yii, Mimiko sọ oyinbo, ilẹ kun ni. Ka si sọ tootọ, ẹni to ba iyawo aburo rẹ sun, tọhun yoo rojọ arolaagun, ohun to ṣẹlẹ si Mimiko niyi. Awọn oloṣelu fẹran lati maa pe araalu lọbọ ni, ṣugbọn nigba ti araalu ba si gbọn, awọn naa yoo pada lẹyin wọn. Oloṣelu ko jẹ kinni kan ti wọn ko ba ti si nipo agbara, bi wọn ti n bọ sinu omiigbona ni wọn yoo maa sare ko si tutu, wọn yoo si maa sare kaakiri. Wọn ki i le duro si oju kan, owo ti wọn n wa ko ni i jẹ, agbara ti wọn n wa kiri ko ni i jẹ, arinka n ja bata, awọn oloṣelu ilẹ yii ni wọn n pe bẹẹ. Bi eeyan ba ri Mimiko, ko beere lọwọ rẹ pe ẹgbẹ oṣelu meloo loun nikan fẹẹ ṣe. Ati pe ki loun naa n wa kiri gan-an! Nigba ti ọrọ rẹ bẹrẹ, ẹgbẹ AD lo ba wọle, kọmiṣanna ni labẹ Adefarati. Adefarati ko ti i ku ti Mimiko fi ja kuro lẹyin ẹ, o loun ko ṣe mọ, ẹyin Agagu lo gba lọ ninu PDP, oun si ni akọwe ijọba wọn.  Mimiko ko jẹ ki Agagu ṣejọba ẹẹkeji to fi ni oun naa fẹẹ di gomina, iyẹn l’Ọbasanjọ ṣe pe e lọ s’Abuja, to si n ṣe minisita labẹ PDP. Igba to fẹẹ du gomina lo pada wa, to waa du ipo naa lorukọ Labour.  Labour wọle, wọn ko gbejọba fun un, o si sa lọ sọdọ awọn Tinubu ninu ẹgbẹ AC, diẹ lo si ku ko di ọmọ ẹgbẹ wọn. Nigba ti ijọba bọ si ọwọ rẹ, lẹyin to ti fi orukọ ẹgbẹ naa ṣe gomina lakọọkọ, to tun wọle lẹẹkeji, o sa kuro ninu ẹgbẹ naa, o tun pada si PDP, nibi to ti wa tẹlẹ laaarọ ọjọ. Ninu PDP lo ti tun pada to tun loun n lọ si Labour yii o. Ibeere ti gbogbo eeyan si n beere naa ni pe, kin ni Ọgbẹni Mimiko n wa kiri gan-an?

 

(61)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.