Kin ni iyawo Buhari tun n wi yii o

Spread the love

Aishat, iyawo Aarẹ Buhari, wa ni Kano lọsẹ to kọja lọ yii, oun lo si ba wọn bẹrẹ eto ipolongo ibo fun ọkọ rẹ, o ni ibẹ lawọn obinrin yoo ti bẹrẹ eto naa, ti awọn yoo si kari gbogbo Naijiria pata. Eyi tumọ si pe bi awọn ọkunrin ba n ṣe kampeeni tiwọn lọ, Aishat naa yoo ṣe olori awọn obinrin, awọn naa yoo si maa ṣe kampeeni tiwọn lọ laarin awọn obinrin. Ko si ohun to buru rara ninu ki Aishat ba ọkọ rẹ ṣe ipolongo ibo, ko si sọ pe ki awọn obinrin ba oun dibo fun un. Ṣugbọn obinrin yii ni ọpọlọpọ alaye to gbọdọ ṣe fun araalu, nitori bi ko ba ṣe alaye naa, ko dara. Oun funra rẹ lo ti sọ pe awọn kan wa ninu ijọba Buhari yii ti wọn n ba a jẹ. Ọrọ akọkọ to sọ ni pe awọn kan wa ninu ijọba naa ti oun ko mọ, ti ọkọ oun ko mọ wọn rara, awọn ti wọn ko ba wọn kampeeni fun ibo ti wọn di lọdun 2015, awọn ti wọn ko si mọ eto ti ijọba Buhari fẹẹ ṣe. O ni awọn yii lo pọ ninu ijọba naa, awọn ni wọn si ba a jẹ ti wọn ko jẹ ki ohun gbogbo ṣee ṣe fọkọ oun. Lẹẹkeji to sọrọ, o ni awọn meji kan wa ninu ijọba yii to jẹ awọn gan-an ni aburu inu ijọba naa, awọn ni wọn n dari ọkọ oun sibi to ba wu wọn, ti wọn ko si jẹ ko le ṣiṣẹ ti awọn araalu gbe fun un. Ko ti i pẹ rara to sọ eleyii, iyẹn si ni pe oun naa mọ pe ijọba ọkọ oun ko ṣiṣẹ, nitori awọn to ko tira rẹ ki i ṣe eeyan gidi to le jẹ ki iṣẹ rẹ ṣee ṣe. Ki waa lo de, ki lo si ti yipada, to jẹ ni bayii, Aishat tun jade, o ni ki ọkan awọn eeyan balẹ pe ọkọ oun yoo ṣe daadaa. Ṣe ki i ṣe pe oun naa n tan awọn obinrin Naijiria jẹ bayii, tabi ọkọ rẹ ti le awọn to ni ko jẹ ko ṣejọba kuro ni. O san ki eeyan kuku ma sọrọ ju ko maa purọ, ko si maa tan awọn eeyan jẹ lọ. Bi Aishat ti mọ pe ijọba ọkọ oun ko dara nni, ko yẹ ko tun jade maa tan awọn araalu pe ki wọn jẹ ki ọkọ oun ṣe ọdun mẹrin mi-in si i. Ki lọmọ Naijiria yoo ri gba ninu ijọba naa pẹlu ọrọ ti Aishat funra ẹ ti sọ fun wa. Ọrọ Naijiria yii ma tiẹ waa suuyan o, abi iru awọn eeyan wo l’Ọlọrun ko ti wa yii!

 

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.