Kin ni Fayẹmi fẹẹ fi ero rẹpẹtẹ bayii ṣe l’Ekiti

Spread the love

Nigba ti eeyan fẹẹ dibo l’Ekiti, to ko ọga ṣọja pata sinu kọmiti, to kọkọ mu gomina lati Zamfara, to mu sẹnetọ lati Ṣokoto, to mu minisita lati ilẹ Ibo, to si ṣe bẹẹ ko awọn gomina mẹrinla, awọn sẹnetọ aimọye, awọn aṣofin ti ko lonka, ati awọn oriṣiiriṣii eeyan ti wọn ko ba Ekiti tan, ti wọn ko wọn sinu kọmiti kan ṣoṣo. Awọn eeyan mẹtadinlọgọrin! Ọpọ awọn eeyan yii ki i ṣe ara Ekiti, koda wọn ko ba Ekiti tan. Abuja ni wọn n gbe, nibẹ ni wọn ti jọ wa ninu ẹgbẹ awọn ijọba. Oore ti awọn eeyan ti APC ti Fayẹmi ko jọ yii fẹẹ ṣe fawọn ara Ekiti ni ẹnikan ko mọ, ohun to fẹ ki wọn ṣe, ati ipa to fẹ ki wọn ko. Ṣe owo ni yoo gba lọwọ wọn lati fi ṣeto ibo yii ni, abi awọn ọlọpaa ni wọn yoo lo ipo wọn lati ba a wa, tabi awọn ṣọja, tabi awọn SSS. Bo ba jẹ nibi ti nnkan ti daa ni, eyi ti APC ati Fayẹmi ṣe yii to lati ja a kulẹ ninu idibo naa, ki wọn fofin de e ko wa iṣẹ mi-in ṣe. Ṣugbọn ta ni yoo so pe ki ọmọ oninaawo ma jo lagbo, o mọ ọn jo ko mọ ọn jo, ṣebi iya rẹ lo pe onilu, ta ni yoo waa le e lagbo. Ẹgbẹ APC lo n ṣejọba, ara to ba si wu wọn ni wọn le da. Koda bi awọn oloṣelu mi-in ba ti n ṣe iru rẹ tẹlẹ, asiko to yẹ ki ẹgbẹ APC fofin si iru iwa palapala ati iwa ole bẹẹ ree, bi awọn ba fẹẹ fi ara wọn han bii ẹgbẹ to mọ ohun to n ṣe, ẹgbẹ to dara, to si niwa to ba ti ọmọluabi mu. Ta ni ko mọ pe ati sẹnetọ, ati gomina, ati minisita ti wọn ba ko jọ bayii, wọn yoo lo agbara wọn ati ipo wọn lati fi ran ẹni ti wọn ba fẹ lọwọ ni, lati fi ṣojooro, tabi lati fi doju ibo naa ru bi kinni ọhun ko ba lọ bi wọn ti ṣe n fẹ. Idẹrubani leleyii, ati ihalẹ mọ awọn ara Ekiti, awọn aṣaaju APC naa si mọ pe ohun ti awọn n ṣe niyẹn. Bẹẹ naa ni Fayẹmi mọ. Bi ọkunrin yii ba da ara rẹ loju, ewo ni lati maa ko awọn ti wọn ko loore fawọn ara Ekiti jọ ju agbara oṣelu to wa lọwọ wọn lọ, ki lo de ti ko ṣa awọn ara Ekiti ni origun mẹrẹẹrin ipinlẹ naa, nigba to jẹ awọn ni wọn ni ipinlẹ wọn. Iru kọmiti bẹẹ iba ni oore ninu fun awọn araalu yii ju kọmiti fian-fian bayii lọ. Ki awọn ara Ekiti wo oju ilẹ daadaa o, ki wọn mọ ẹni ti wọn yoo dibo wọn fun, ki wọn mọ ẹni to le ṣe oore fun wọn bo ba wọle.

 

(64)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.