Kin ni Atiku naa tun n wa kiri o

Spread the love

Ọlọrun ma tun jẹ ka daran o. Adura gidi ti ki gbogbo ọmọ Naijiria maa ṣe niyẹn. Buhari ati Atiku nikan naa ni awọn eeyan meji ti wọn lorukọ ati agbara ju lasiko ibo ọdun to n bọ yii, iyẹn ni pe bi Buhari ko ba wọle, Atiku ni yoo wọle. Lara iṣoro to koju ijọba Buhari, ti iṣoro naa si n ba a ja titi di asiko yii ni ti aiyaara to kọlu baba naa, to si fi ọpọlọpọ oṣu jokoo si London, nibi ti wọn ti n wo o, ti ko tete san. Owo ijọba Naijiria lo n na, bẹẹ ni ko ṣe iṣẹ kan fun wọn lori aisan to wa. Eleyii pẹlu ohun to ba iṣẹ ijọba rẹ jẹ, nitori awọn to fi sile kan n ṣe ohun ti wọn fẹ ni. Adura la n gba bayii pe bo ba tun wọle lẹẹkeji, ki kinni naa ma tun pada si i lara lẹyin wahala to ba ṣe lati ṣe kampeeni. Ṣugbọn bo ba jẹ Atiku naa lo waa wọle, afi ka wadii oun naa daadaa ka too dibo fun un o. Lati igba ti wọn ti ṣeto idibo abẹle PDP tan loun naa ti kọja si Dubai, ibẹ lo si wa bayii to ti n paṣẹ ranṣẹ sile, ọpọ awọn ti wọn ba fẹẹ ba a ṣiṣẹ ni wọn si ti n lọọ ba a lọhun-un, nibẹ ni wọn fi ṣe ile eto ati ti ẹgbẹ wọn. Loootọ wọn lo n sinmi ni, ṣugbọn isinmi wo naa leeyan n fi odidi oṣu kan ṣe lasiko to yẹ ko maa rin sọtun-un sosi nitori ibo to ku oṣu meji pere yii. Bi ọrọ ba ti di a n sinmi rẹpẹtẹ bayii, afi ki araalu fura. Ohun to ṣẹlẹ si wa lori ọrọ Buhari ko tun gbọdọ ṣẹlẹ, ẹni to ba fẹẹ ṣejọba Naijiria ni 2019 gbọdọ pe lara, ki ara rẹ si da ṣemuṣemu. Ẹ pe Atiku wa si gbangba ko waa ṣalaye o, ki loun naa tun n wa kiri?

(33)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.