Kilọọbu Tunisia ṣafihan aṣọ to jọ ti Super Eagles

Spread the love

Kilọọbu Etoile Olympique de SidiBouzidilẹ Tunisia ti ṣafihan aṣọ tuntun tawọn agbabọọlu kilọọbu naa yoo maa lo bayii, eyi to jọ tẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ilẹ Naijiria.

Lopin ọsẹ to kọja lẹgbẹ naa gbe igbesẹ yii lati kede awọn ayipada to waye fun saa tuntun.

Aṣọ Super Eagles nileeṣẹ Nike ṣe ṣaaju idije agbaye ọdun 2018, eyi to di aṣọ olokiki laarin awọn ololufẹ bọọlu, gbogbo ibi ti wọn si ti ta a kaakiri agbaye lawọn eeyan ti ya bo o.

Ni bayii ti Etoile Olympique de SidiBouzid ti ni eyi to jọ ọ, ireti wa pe awọn ololufẹ wọn atawọn ololufẹ bọọlu lapapọ yoo tẹwọ gba a.

Ọdun 1959 ni wọn da Club Olympique de SidiBouzid silẹ niluu Sidi Bouzid, nilẹ Tunisia, ọdun 2003 ni wọn si darapọ pẹlu l’Étoile Sportive de Gammouda, lati di kilọọbu kan ṣoṣo, eyi to fa bi wọn ṣe pa orukọ pọ to fi di Etoile Olympique de SidiBouzid.

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.