Ki wọn ṣa tun ma ko owo Abacha yii naa jẹ

Spread the love

Eti nikan lo ku ti a fi n gbọ ọ bayii, ko jọ pe ẹni kan wa to ri owo Abacha lati ọjọ ti wọn ti n gba a tabi ohun ti wọn n fi owo naa ṣe. Eti nikan la fi n gbọ ọ. Ṣe ẹ ranti pe o ti to bii ẹẹmẹta bayii ti Aarẹ Muhammadu Buhari ti n gba lara awọn owo ti olori Naijiria nigba kan tẹlẹ, Ọgagun Sani Abacha, ji ko pamọ sẹyin odi. Ọpọ ijọba awọn orilẹ-ede ti Abacha ko owo Naijiria pamọ si ni wọn ti n da owo naa pada fun wa, bẹẹ ni wọn ko si ti i gba owo naa tan titi di bi a ṣe n sọ. Eyi ti wọn tun ko wa bayii fun ijọba, miliọnu okoolelọọọdunrun ati meji owo dọla ($322milion) ni. Lasiko ti a wa yii ni Naijiria, owo rẹpẹtẹ leleyii jẹ, owo nla ni. Owo naa le ni ọgọrun-un biliọnu owo Naira, owo kekere kọ leleyii rara, owo to to lati ṣe nnkan nla kan fun Naijiria ni. Iyẹn ni ko ṣe yẹ ki owo naa tun bọ ha bii awọn to ku ko yẹ ki owo naa kan tun wọle ko jade kẹnikẹni ma si mọ ibi to wọlẹ si tabi ọhun ti wọn fi owo naa ṣe. Niṣe lo yẹ ki ijọba Buhari ṣe bii ẹni pe wọn ko ri owo naa, nigba to jẹ wọn ko reti rẹ tẹlẹ, ki wọn waa pa a pọ, ki wọn fi ṣe ohun to dara. Boya ina ijọba ni wọn fẹẹ fi i ṣe ni o, boya reluwee ni wọn fẹẹ fi i ṣe ni o, boya titi nla tuntun kan ni wọn fẹẹ la ni o, ohun to ṣa jẹ nnkan nla ti yoo ṣe gbogbo Naijiria lanfaani, ti wọn yoo si maa ri i. Ṣugbọn ẹru n baayan, nitori lati ọjọ ti owo naa ti n wọle, niṣe ni wọn n na an, ko si si kinni kan naa nibẹ ju pe awọn kan n tun owo naa ji ko lọ. Abacha ji owo ko ni, awọn si ri i gba, awọn naa si tun n ji i ko, wọn ko si nibẹru Ọlọrun. Ki Buhari mojuto owo yii funra rẹ o, ko ri i pe owo tuntun ti awọn tun gba yii ko lọ bi awọn ti iṣaaju ti lọ, ko paṣẹ ki wọn lo owo naa fun nnkan to daa, ki gbogbo ilu si foju ri i. Owo Naijiria ni, Abacha lo ji i ko, gbogbo eeyan lo si ranti iku to pa Abacha, ẹni ba tun waa n ji owo ti wọn gba pada nibi to ko o pamọ si mọ awọn ọmọ Naijiria lọwọ, iru iku to pa Abacha ko jinna si oun naa, nitori ori gbogbo ọmọ Naijiria ni yoo mu un.

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.