Ki lọna Ọna Abayọ? (3)

Spread the love

Nibi ti ọrọ de duro bayii nilẹ yii, ko si ọna abayọ mi-in to tun wa fun Yoruba ni Naijiria yii ju ka ni aṣaaju tiwa lọ. O kan jẹ pe ọrọ naa ṣoro ju bi mo ti ro o si lọ ni. N o ni i purọ fun yin, iyapa to wa laarin awa Yoruba fẹrẹ ju eyi to wa ni Naijiria funra rẹ lọ. A ko ni adari, a ko ni olori, a kan da bii maalu ti ko ni mọla, to n rin sọgusọgu kaakiri oju titi. Bẹẹ nibi ti ọrọ orilẹ-ede yii de bayii, ẹya ti ko ba ni aṣaaju, ti ko ni adari ti wọn yoo tẹle, bi wahala to n bọ yii ba de, iru ẹya bẹẹ yoo parẹ mọ awọn to ku lara ni. Ko si bi wọn ti le tobi to, ko si si bi wọn ti le lagbara to, nitori alagbara ma mero, baba ọlẹ ni. Ko si si bi a ti le ṣe e, bo ba jẹ bi Naijiria ti wa yii naa lo wa, nnkan yoo ṣẹlẹ, ohun ti yoo ṣẹlẹ ko si ni i dara. Ṣe ẹ mọ pe mo n pariwo lati ọjọ yii, ṣugbọn ẹni tọrọ mi ko ba ye yoo ro pe ariwo eke ni mo n pa, tabi asọdun ni mo n sọ.

Ọrọ ti debii pe igba kan n bọ laipẹ nilẹ yii to jẹ yoo ṣoro fun ẹya mi-in lati ṣe olori ijọba Naijiria ju awọn Hausa-Fulani lọ. Ohun ti awọn Fulani aye fẹ niyẹn, ki wọn fi Naijiria ṣe orirun wọn. Eto ti wọn n to niyi, nitori gbogbo ipo agbara pata ni wọn n fi ara wọn si, awọn ipo to ṣe pe ko si ẹya mi-in ti wọn n jẹ ko debẹ. Bi ẹya mi-in si debẹ, awọn ọmọ Hausa ti wọn yoo ko si i labẹ ko ni i jẹ ko ṣiṣẹ, yoo kan wa nibẹ bii korofo ni. Igba kan n bọ nilẹ yii to jẹ awọn oloṣelu ati ọba nilẹ Hausa ni yoo maa pin ohun tawọn to ku ni Naijiria yoo jẹ le wọn lọwọ, bẹẹ awọn kọ ni wọn ṣiṣẹ owo tabi ohun ti wọn n pin yii, wọn feru gbabukun ni, wọn lọ ni lọwọ gba ni, iṣẹ oniṣẹ, ere elere, ni wọn n jẹ. Ṣugbọn ọrọ naa aa le debii pe ko ni i sẹni ti yoo le mu wọn tabi da wọn duro, afi lọjọ ti ogun gidi ba de nilẹ yii, ti Naijiria si fọ pata.

Gbogbo awọn nnkan wọnyi yoo ṣẹlẹ, iwọsi ati ẹgbin naa yoo si pọ debii pe awọn miiran yoo mura lati binu ku, nitori wọn ko ni i ri iru rẹ ri rara. Awọn eeyan wa ko fura ni, ami ati apẹẹrẹ awọn nnkan wọnyi wa kaakri ilẹ yii bayii, ṣugbọn wọn ti gbe igbekugbee le awọn to yẹ ki wọn dide sọrọ lọwọ, wọn ti fi burẹdi gbigbẹ tan wọn, bẹẹ ni wọn gba igba oyin to wa lọwọ iran Yoruba ati awọn ẹya to ku, wọn gbe igba ata, ati korofo igba lasan, le wọn lọwọ. Oṣelu ti a n ṣe yii ko gbe wa, boya ti APC tabi ti PDP, ohun to wa nilẹ bayii ju ọrọ oṣelu lọ. Oṣelu ti a n ṣe to gbe iru awọn eeyan bii Buhari yii wa sori wa, to fi wọn ṣe olori ijọba, to si fawọn opurọ ati alagabagebe ọmọ Yoruba yi wọn ka yii ki i ṣe iru oṣelu ti yoo gbe iran Yoruba tabi ẹya mi-in ni Naijiria, oṣelu ti yoo lu Naijira fọ ni.

Nigba ti wọn bẹrẹ oṣelu naa nijọsi, mo sọ fun yin pe ko si kinni kan nibẹ fun Yoruba, mo wi fun yin daadaa. Ṣugbọn emi naa ko mọ nigba naa pe nnkan naa yoo buru to bayii rara. N ko mọ. Bi mo ba mọ pe yoo buru to bayii, ko sohun ti mo le ṣe naa, ṣugbọn o ṣee ṣe ki n pariwo ju eyi ti mo pa yẹn lọ. Iwọnba ariwo ti mo pa nigba naa paapaa, eebu lawọn kan n bu mi. Wọn ni irọ ni mo n pa, wọn ni PDP lo fun mi lowo, ati awọn ọrọ ti ko mu laakaye dani mi-in. Ki lo de ti wọn n bu mi? Wọn ni Bọla atawọn Bisi ni wọn ni APC, ko sẹni to le gba a lọwọ wọn bi mo ṣe wi yẹn. Wọn ni Yẹmi ni igbakeji Buhari, ko sohun to le ṣe ti ko ba sigbakeji ẹ nibẹ. Nigba to ya, wọn ni ki la tun n fẹ, ṣebi Yoruba ni minista oniṣẹ mẹta, iyẹn Tunde (Faṣọla), Yoruba si ni minisita fun eto inawo, pe ko sohun ti Buhari le ṣe lẹyin awọn yii rara.

Ẹrin ni mo rin, nitori aimọkan to n yọ awọn eeyan naa lẹnu. Oju gbogbo wa ti ja a bayii, afi ẹni to ba kuku wa ti ko gbọn rara, ti ọrọ oṣelu ilẹ yii ko si le ye e laelae. Oju wa ti ja a pe ko si alagbara mi-in to ju aarẹ lọ ninu ijọba ati oṣelu Naijiria, paapaa ti aarẹ bẹẹ ba jẹ ẹni to wa lati ilẹ Hausa. Aarẹ ilẹ Hausa lo maa n ṣe ohun tawọn aarẹ to wa lati ẹya mi-in o le ṣe, wọn yoo si wa gbogbo agbara mọ ara wọn lọwọ debii pe ko sẹlomi-in ti yoo le ṣe kinni kan lẹyin wọn. Bi ẹ ko ba mọ, ẹyin naa yoo ṣa ti gbọ ọrọ ti iyawo Buhari funra ẹ sọ. O ni awọn eeyan meji pere ni wọn wa ninu ijọba yii ti wọn lagbara ju, ti wọn ko jẹ ki ọkọ oun le ṣe ijọba naa daadaa. Awọn alagbara meji wo lobinrin yii n sọ. Awọn meji to n wi yii ki i ṣe minista, bẹẹ ni wọn ko joye rẹpẹtẹ nibẹ, awọn meji ti Buhari ko sẹgbẹẹ ara rẹ ni, gbogbo aṣẹ ti wọn si n lo pata, Buhari lo fun wọn. 

Ko si minista kan to lagbara to ju awọn yii lọ, nitori awọn nikan ni ilẹkun to ṣi sinu, to ṣi sode, awọn ni wọn n ri Buhari, ohun ti wọn ba si sọ fun un ni yoo ṣe. Buhari funra rẹ ti ṣe eto naa daadaa funra ẹ, awọn araale wọn, awọn ẹbi rẹ, lo wa nipo mejeeji yii, awọn ni ọkunrin Fulani naa si n lo lati ṣe gbogbo ohun to ba fẹẹ ṣe. Bẹẹ lo jẹ pe ninu ijọba yii, bi a ba fẹẹ tẹle ohun ti Aisha ti i ṣe aya Buhari wi, ko sẹni kankan to lagbara kan bayii, Buhari nikan ni, a si fi awọn meji to fa iṣẹ le lọwọ yii. Ninu oṣelu Naijiria, ẹni to ba ni ṣọja lo lagbara ju. Awọn Hausa ni wọn ni ṣọja, wọn si ti ṣe bii ere bii ere, wọn ti ko gbogbo awọn ọmọ ogun to ku si abẹ wọn, boya ọmọ ogun oju omi ni, tabi ti ofurufu, tabi ti ọlọpaa, tabi awọn SSS ti ko tilẹ yẹ ki awọn da si ọrọ oṣelu rara.

Awọn meji ti Buhari n lo yii ni wọn n fi gbogbo awọn eeyan sipo, awọn ni wọn si n ri i daju pe ko si ipo kankan to ṣi silẹ nilẹ yii, ọmọ Hausa-Fulani ni wọn yoo gbe sibẹ, a si tun fi awọn eeyan ti wọn ba ti ṣetan lati la idi fun wọn, ti wọn ṣetan lati ko igbẹ ati itọ wọn, to jẹ pẹlu gbogbo iwe ti wọn ka ati iriri ti wọn ni, wọn ti ṣetan lati ṣe ẹru wọn, ti wọn ko si ni i le da aṣẹ kan pa, tabi da ironu kankan ro, afi ohun ti awọn eeyan yii ba sọ fun wọn. Iba dara daadaa to ba jẹ awọn eeyan yii mọ iṣẹ, ti wọn ni ọgbọn ju awa to ku lọ, ti imọ wọn si tayọ tiwa nidii ijọba ṣiṣe. Ṣugbọn wọn ko lọgbọn eto ijọba ati akoso ọrọ aje bii awa to ku, bẹẹ ni wọn ko ni ifẹ Naijiria rara, ifẹ iran wọn ti wọn n pe ni Fulani tabi Hausa ni wọn fẹ. Agbara ijọba Buhari ni wọn n lo bayii lati fi awọn ọmọ Hausa yii wa ka ni ilẹ Yoruba, to fi jẹ pe awọn ọdọ ti wọn  jẹ ọmọ Hausa ti wọn n wa ọkada, ti wọn n ṣe sikiọriti ati awọn iṣẹ lebira pọ ju awọn ọmọ tiwa lọ.

Ewu nla ni eleyii lọjọ iwaju, paapaa fun awọn ara Eko, nitori Hausa ti yi wọn ka pata. Mo n wo aafin Ọba Fulani l’Ekoo ninu fọto lori ẹrọ ayelujara, inu mi si bajẹ. Awọn ohun ti Hausa ko le gba nilẹ wọn ni wọn n ṣe nibi ti ẹ dẹ n ri yii, nigba ti ọmọ ti wọn fa kalẹ l’Ekoo si fẹẹ pari iṣẹ, o lọ sọdọ Ọba Fulani yii lati bẹ ẹ pe bi wọn ba fẹẹ dibo, ki wọn dibo fawọn. Akiyesi ti mo ṣe nibẹ ni pe ọba yii ko sọ pe oun ọba Hausa, o ni oun Sarkin Fulani of Lagos, iyẹn Ọba Fulani Eko. Ni eto to wa ni Naijiria loni-in, Ọba Fulani ti ẹ ri yii lagbara ju Ọba Eko funra rẹ lọ, nitori bi kinni kan ba ṣẹlẹ, oun ni ọmọ ogun, awọn ọmọ Hausa-Fulani ti wọn le ja, ti wọn si le paayan pẹlu ọbẹ ati ida ti wọn n mu kiri, bẹẹ ni ko sọmọ Yoruba ti i mu ida rin, Ọba Eko ko si ni ọmọ ogun kan nibi kan. Bi ọrọ ba si dija, to dariwo, ẹyin Sarkin Fulani ni ijọba ati awọn ṣọja ati agbofinro ni Naijiria yoo wa.

Ohun to n su mi ti mo si ṣe n pariwo yii ni pe ija yoo ṣẹlẹ. Ija nla n bọ. Ṣugbọn bi ija yii ba de, ta ni aṣaaju Yoruba ti yoo ko wa lọ soju ogun. Bi ọmọ-ale oloṣelu kan ba muti yo, to ni ko ni i si ija ni Naijiria, ẹ fi gbogbo ẹnu sọ fun un pe dindinrin ni. Ija n bọ, ki Ọlọrun ma jẹ ki Fulani pẹlu Hausa ṣẹgun wa nilẹ baba wa ni. Bẹẹ, bawo ni wọn ko ṣe ni i ṣẹgun wa, nigba ti a ko ni aṣaaju kan  bayii, ti awa ko si gbaradi fun ohunkohun. Faaji ati ọrọ oṣelu nikan la n ba kiri, Ọlọrun ko ni i jẹ ko pẹ ko too ye wa. Kin ni iṣoro ti mo sọ pe o wa ninu ọrọ aṣaaju yii? N oo sọ iṣoro ibẹ lọsẹ to n bọ yii, ṣugbọn ni ṣoki, awọn oloṣelu ilẹ Yoruba ni o!

 

(22)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.