Ki lọna abayọ? (1)

Spread the love

Inu a maa bi mi nigba mi-in ,sugbon mi o ki i lee binu to bi mo ṣe fẹẹ binu to, nitori asiko yii ki i ṣe akoko ibinu, asiko ti a gbọdọ ni ọpọlọpọ suuru funra wa ni. Ọrọ ko ye awọn eeyan wa rara, paapaa awọn Yoruba tiwa, pupọ ninu wọn o mohun to n lọ. Bi Inu a maa bi mi nigba mi-in, ṣugbọn mi o ki i lee binu to bi mo o ba si fẹ lati fi ohun to n lọ han wọn, wọn yoo bẹrẹ ija, wọn aa bẹrẹ si i bu ọ, tabi ki wọn ko agidi bolẹ pe tawọn ti awọn mọ yẹn naa lo dara ju. Ẹyin lẹ beere ọrọ lọwọ mi lori ohun ti ẹ n gbọ nipa Buhari, n ko si fọrọ ṣegbe, ohun ti mo mọ naa ni mo sọ jade. Ṣugbọn awọn mi-in tun ka ọrọ naa si ibinu, wọn ni alaye ti mo ṣe lori ẹ ti pọ ju, ṣe emi naa ki i siiki ni, abi okuta ni mi. Ṣe ti mo ba siiki, n ko ni i sọ fawọn to wa lẹgbẹẹ mi atawọn ti wọn gba mi siṣẹ pe ara mi ko ya, ati pe ohun to n ṣe mi leleyii. Ṣebi ohun to yẹ ki Buhari ṣe ti ko ṣe to fi da gbogbo ariwo yii silẹ niyẹn.

Ko sohun meji to ye ọpọlọpọ ọmọ Naijiria loni-in yii mọ ju APC ati PDP lọ. Wọn ko tilẹ mọ pe ẹgbẹ oṣelu mi-in tun pọ rẹpẹtẹ nilẹ wa yii, wọn ko si mọ pe awọn kan wa ti ko ṣe oṣelu rara. Nibi yii lo ti yẹ ka yẹ ọrọ ara wa wo, ka beere lọwọ ara wa pe kin ni idi tawọn eeyan wa fi fẹran ẹgbẹ oṣelu meji yii, to jẹ awọn nikan ni wọn n darukọ. Ọmọyẹle Ṣoworẹ to ni ileeṣẹ iroyin Sahara Reporters lo n kaakiri lorukọ ẹgbẹ mi-in yẹn, ko sẹni to ṣe bii ẹni pe oun ri i. Oby Ezekwesile, obinrin to ṣe gudugudu meje ninu ijọba Ẹgbọn Ṣẹgun nijọsi, lo gbe ara rẹ kalẹ pe oun fẹẹ dupo aarẹ yii, gbogbo wa la kọyin si i. Donald Duke lati Cross River lo ti jade yii, orukọ ẹgbẹ oṣelu mi-in loun naa fi jade, ṣugbọn ko sọmọ Naijiria to sọrọ ẹ. Ki lo waa de to jẹ ẹgbẹ oṣelu meji yii la n darukọ. Ki lo de to jẹ APC ati PDP yii saa ni.

Mo kan fẹ ka ronu, ka yẹ ara wa wo ni. Ki lo de to jẹ awọn ẹgbẹ meji yii la n darukọ, ibẹ la si fẹẹ wa. Bi ẹ ba pe PDP jale, awọn APC tuntun naa n ji owo ko, ki lo waa de ti a ko doju kọ ẹgbẹ mi-in, ki gbogbo ọmọ Naijiria si sọ pe ẹgbẹ tuntun yii lawọn yoo dibo fun, awọn ko fẹ APC, awọn ko fẹ PDP. Ki lo de ta a ṣe n tẹle ẹgbẹ meji pere! Ohun ti a ṣe n ṣe bẹẹ ni pe ole lo pọ ninu awa naa, ole ni ọpọ ọmọ Naijiria, ibi ti kaluku yoo ti ri jẹ ni wọn n wa kiri. Ibi meji naa lowo wa, bi o ba wa ninu APC, owo ni; bi o si wa ninu PDP, owo ni. Ibi ti kaluku yoo ti rowo kiakia, tabi ti ẹnikan yoo ti fa a kalẹ gẹgẹ bii kọmisanna, tabi minista, tabi kansẹlọ, tabi alaga ijọba ibilẹ, agaga ko waa jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin kekere tabi tagba. Ibẹ ni kaluku n wa kiri. Ọpọlọpọ wa ko wa iṣọkan tabi ilọsiwaju Naijiria, ohun ti awa funra wa fẹẹ jẹ la n wa.

Ẹyin naa ẹ yẹ inu ọkan yin wo, nigba naa lọrọ ti mo n sọ aa nitumọ si yin. Oṣelu ti a n ṣe yii ki i jẹ ka wadii ododo. Bi a si ri ododo bayii, tẹnikan ba ṣiṣẹ lori ẹ to si fi han wa pe bayii lọrọ ri, nitori pe ki i ṣe ododo la n wa, ẹtan la n wa, ohun ta a o jẹ la n wa, kia la oo gba ododo naa ti sẹgbẹẹ kan. Ati pe nitori pe ole lo  pọ ninu wa, gbogbo ẹni ti awa naa ba ti ri, ole la oo ka a si, ṣe ohun ti akata ba n jẹ nigbo ni yoo fi lọ ẹranko ẹgbẹ ẹ. Iba diẹ awa ti a n ja fun Yoruba, tabi ti a n sọrọ fun Naijiria, ti a si n sọ awọn ohun ti a n sọ yii, nitori awọn ohun ti a ti ri ni. Ki i ṣe ohun ti ọpọ yoo jẹ ni wọn n wa bayii, ẹlomiiran ti kọle, bẹẹ ni ko lọ kaakiri mọ debii pe aa maa ko mọto bii mẹwaa kiri lẹẹkan; bẹẹ lo ti tọ awọn ọmọ ẹ nileewe debii pe ko si eyi to n yọ ọ lẹnu mọ; ko fẹẹ ṣe kọmisanna tabi minista. Iru ọrọ ti ẹni bẹẹ ba sọ, afi ka kiyesi i.

Ṣe ẹ ri i, ti a ba fẹẹ sọ ọrọ sibi ti ọrọ wa, ko si ẹgbẹ oṣelu ni Naijiria, awọn ẹgbẹ ole lo wa. Awọn ọrẹ tabi alajọṣe ti wọn ko ara wọn jọ lati mọ bi awọn yoo ti ṣe pin owo ati ohun-ini Naijiria mọ ara wọn lọwọ, tabi ti wọn yoo jokoo le e lori, ti wọn yoo maa pin in fawọn to ku bi wọn ba ṣe fẹ. Awọn ọrẹ wonyi ni wọn kun inu APC, awọn naa ni wọn wa ninu PDP. Eyi lo ṣe rọrun fun wọn lati bẹ jade ninu ẹgbẹ kan ki wọn bẹ sinu ẹgbẹ mi-in, bi wọn ba si ti wọnu ẹgbẹ mi-in ti wọn yoo maa rẹrin-in sira wọn, ti wọn yoo si maa jọ ṣe. Iyẹn fihan pe ọrẹ naa ni wọn tẹlẹ, wọn ti ile bọ sile ni. Ṣugbọn awa ọmọ Naijiria ko gbọn, wọn ti ri wa bẹẹ ki wọn too maa mu wa lọbọ. Abi nigba ti eeyan kan lo ọdun mẹrindinlogun ninu PDP, to waa sa wa sinu APC lojiji, to ni ẹgbẹ PDP yẹn, ẹgbẹ ole ni. Ṣe ẹyin ko mọ pe ọga awọn ole loun naa ni.

Ni ilu oyinbo, awọn oloṣelu ibẹ ki i kuro ninu ẹgbẹ ti wọn ba n ṣe. Tabi o di ọjọ wo ti ẹ gbọ pe Tories, ni UK, kuro lojiji, lọjọ kẹta ti ẹ o si gburoo rẹ, o ti wọ inu ẹgbẹ Labour. Iyẹn o ṣee ṣe. Ẹgbẹ to o ba ti wa naa lo wa, awọn mi-in si n ṣe ẹgbẹ oṣelu to jẹ ẹgbẹ ti baba baba wọn ti ṣe, ti baba wọn ti se, lawọn naa wọ inu ẹ, ẹgbẹ naa si ti diran. Ohun to fa eyi ni pe igbagbọ meji lo wa nidii eto oṣelu. Awọn kan gba pe mẹkunnu lo nilu, pe ijọba mẹkunnu lawọn fẹẹ ṣe. Ohun ti iru ijọba bẹẹ yoo maa ṣe ni eto ti yoo jẹ ki agbara wa fun mẹkunu ati awọn oṣiṣẹ, ti wọn yoo maa ri owo na, ti wọn yoo si ni awọn ohun amayedẹrun to pọ lọfẹẹ, tabi ni owo pọọku. Iyẹn lawọn oloyinbo n pe ni Socialism. Awọn oloṣelu keji gbagbọ pe awọn olowo ati ọlọla lo nilu, pe awọn olowo ni wọn le pese ọja fun mẹkunnu lowo pọọku, ohun ti ijọba bẹẹ si gbọdọ ṣe ni lati ran awọn olowo lọwọ ki wọn maa lowo si i.

Igbagbọ eto oṣelu yii ni pe bi awọn olowo yii ba n lowo si i, wọn yoo maa da ileeṣẹ silẹ, wọn yoo maa gba awọn eeyan siṣẹ si i, bi iṣẹ wọn ba si ti n dagba ni wọn yoo le maa pese ọja ati awọn ohun amayedẹrun lowo pọọku. Ati pe iru eto oṣelu bẹẹ aa faaye gba ifigagbaga, nibi ti kaluku yoo ti maa sare lati da iṣẹ silẹ, tabi lati ni imọ to dara gan-an ti awọn ileeṣẹ yoo fẹẹ maa lo. Capitalism lawọn oloyinbo n pe e. Bi o ba waa fẹẹ ṣe oṣelu ilu oyinbo, o ti gbọdọ gbe iwe ati eto ilana oṣelu mejeeji yẹ wo, ki o mọ eyi ti o fẹẹ duro le lori, boya awọn ti wọn n ja fun mẹkunnu ni o, tabi awọn ti wọn n ja fawọn olowo, tabi awọn ti wọn duro laarin, ti wọn ko ja fu mẹkunnu, ti wọn ko si ja fun olowo, tabi to jẹ bi wọn ti n ja fun mẹkunnu, niṣe ni wọn n ja fun olowo, Liberalism ni wọn n pe awọn yẹn.

Mo fẹ kẹ ẹ jokoo daadaa, ki ẹ mi kanlẹ, ki ẹ si beere lọwọ ara yin pe loni-in yii, eto oṣelu wo lawọn ti Naijiria yii n ṣe o. Eto oṣelu wo ni wọn n ṣe ninu APC? Iru eto oṣelu wo ni wọn n ṣe ninu PDP? Iyatọ wo lo wa laarin gbogbo wọn. Awọn ẹgbẹ mejeeji ti ẹ n gbọ orukọ wọn yii, ẹ n gbọ orukọ wọn nitori pe awọn olowo lo ko ara wọn jọ sinu wọn ni. Ṣe PDP ni ko solowo ni abi inu APC? Awọn olowo yii lowo lati ṣe ipolongo. Wọn lowo lati ra awọn oniroyin pa, wọn lowo lati ra awọn majesin laarin ilu, wọn lowo lati ra ọlọpaa atawọn agbofinro gbogbo. Nitori ẹ lo ṣe jẹ ọrọ awọn olowo oloṣelu yii lawọn oniroyin yoo gbe jade, wọn ki i ni ero ọkan tiwọn, tabi ki wọn sọ ero bẹẹ jade. Ọrọ yii kan naa lawọn ọlọpaa yoo tẹle, awọn olowo yii si ni gbogbo agbofinro atawọn oṣiṣẹ ijọba yoo maa ba lọ.

Ewu, adanwo ati adanu to wa ninu eleyii ni pe awọn olowo ti ẹ ri yii, gẹgẹ bi mo ṣe ṣalaye lati ilẹ, oniṣowo ni wọn. Ijọba olowo ni wọn fẹẹ ṣe, ki wọn baa maa lowo lọ si i ni. Ohun ti tiwọn ni ni pe bi wọn ba gbajọba tan, wọn ki i wa ọna idẹrun fun mẹkunnu, bi wọn aa ṣe tubọ fi ara ni wọn si i, ti wọn aa le maa lowo lọ si i ni wọn yoo maa wa. Iyẹn ni mo ṣe n sọ fun yin pe ko si ẹgbẹ oṣelu ni Nairjiria, ẹgbẹ awọn ọrẹ pupọ ati ẹgbẹ awọn oniṣowo la ni, iyẹn si ni ija orogun ṣe le laarin wọn, nitori ija orogun owo ni wọn n ja, eyi si le ju ija orogun ile-ọkọ lọ. O daa, ki lo de to jẹ awọn ti wọn ṣejọba lati ọdun 1960 naa ni wọn n ṣejọba titi doni? Ki lo de to fi ri bẹẹ?  Ẹ jẹ ka maa sọ ọ lọ lọsẹ to n bọ.

 

 

 

 

 

 

 

 

(38)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.