Ki lo de tọkunrin onifila gogoro yii fẹẹ fori sọlẹ ni titi ọlọda

Spread the love

Afi ki awọn ti wọn n wadii itan jokoo daadaa, ki wọn le mọ ohun to n ṣẹlẹ si Gomina Ibikunle Amosun ti yoo pa ara rẹ sijọba lọrun nitori pe ẹni to fẹ ko ṣe gomina Ogun ko raaye wọle. Amosun ṣe ohun ti eeyan gidi kan ko gbọdọ ṣe. O fi ọba ilu rẹ wọlẹ debii pe gbogbo eeyan lo n bu ọba naa, ti wọn ni ọba to n jẹjẹkujẹ ni, ko fi ara rẹ sipo agba bii Awujalẹ ilẹ Ijẹbu. Ki lo de ti Amosun mu Alake lọ si ọdọ Buhari? Ki lo de ti ko mu Akarigbo ti i ṣe olori awọn ọba Rẹmọ lọ! Ki lo de ti ko mu Awujalẹ lọ? Ki lo kan Alake ninu ọrọ oṣelu to wa nilẹ yii, ti Alake waa n fi ori ade tẹ wọrọkọ fun olori ijọba Naijiria, ohun ti Sultan ilẹ Sokoto ko ni i ṣe, ti ọba Kano ko ni i da lara, ti ọba Katsina ko ni i ṣe laye. Ki lo de ti awọn oloṣelu onijẹkujẹ alailojuti yii maa n ṣe bayii fun awọn ọba ilẹ Yoruba. O ṣe jẹ awọn ọba ilẹ Yoruba lawọn eeyan yii n ri fin, ti wọn si n fi wọn ṣe yẹyẹ loju aye. Njẹ Ọlọrun ko ni i pada waa fi ẹyin naa ṣe yẹyẹ bayii! Amosun n sunkun kiri, o n lami loju bii egbere, o ni Yewa loun fẹẹ gbejọba fun, ko sọdi to fi fẹẹ gbejọba fun Yewa. Ṣe nitori awọn ara Yewa ni, abi nitori tara tirẹ, ṣebi nitori lati ri ẹni ti yoo le kọnturoolu ni, ẹni ti yoo le kapa, ti iyẹn yoo maa gbọrọ si i lẹnu, ti yoo si le ba a bo gbogbo aṣiri awọn iwa ibajẹ to ba hu. Ṣebi nitori awọn aṣiri Adekunle Akanbi Akinlade to wa lọwọ rẹ ni, tabi ọkunrin yii ro pe gbogbo araalu naa lo kuku ponu. Awọn aṣiri yii ni yoo maa fi halẹ mọ Akinlade lọjọ iwaju, iyẹn ko si ni i le ṣe awọn ohun mi-in ju ohun ti Amosun ba fẹ lọ. O fẹẹ sọ ara rẹ di Jagaban sawọn ara ipinlẹ Ogun lọrun, awọn eeyan ti ko tokan ti wọn yoo maa pe ara wọn ni mejila, nigba ti oṣelu ijẹkujẹ ti a n ṣe nilẹ yii ba ti sọ wọn soke tan, iwa ibajẹ lo ku ti wọn yoo maa hu kiri. Wọn ti ko gbogbo awọn oye aṣofin fun un, wọn ko gbogbo awọn oye nla inu ẹgbẹ fun un, sibẹ ko tẹ ọkunrin yii lọrun, o fẹẹ ni gbogbo ipinlẹ Ogun ni. Idi niyi to fi n tẹ nile to n tẹ loko. Ṣugbọn ko ti i tẹ o, inu ẹgbẹ DPP to n ko awọn eeyan rẹ lọ yẹn ni ko tete niṣo, nigba naa ni abuku olorombo yoo ṣẹṣẹ waa kan ọrẹ wa. Awọn oniyẹyẹ dede nẹẹ!

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.