Ki lo de ti wahala inu APC pọ bayii

Spread the love

O fẹrẹ jẹ pe ko si ibi ti wahala o ti si ninu APC nilẹ Yoruba bayii. Ibo abẹle ti wọn di ninu ẹgbẹ naa lọsẹ to kọja yii fihan pe nnkan ko fararọ, ati pe eyi ti awọn araalu n ri ti wọn n ro pe awọn ri nnkan yii, kekere ni. Nitori ibo abẹle, awọn ọmọ ẹgbẹ kan naa, wọn si ṣa ara wọn ladaa l’Ekoo titi ti wọn fi pa ẹni kan ninu wọn l’Agege, tawọn mi-in si farapa rẹpẹtẹ. Wọn yinbọn pa ọmọ ọlọmọ kan n’Ibadan, nitori ọrọ pe wọn n dibo laarin ara wọn. Aimoye awọn oloogun ni wọn gba mu nibi ibo abẹle ti wọn di ni Ekiti, awọn eeyan wa sibẹ taṣẹtaṣẹ, bẹẹ lawọn mi-in san bantẹ oogun wa. Nitori kin ni? Oyinlọla ti fi wọn silẹ l’Ọṣun, wahala wa laarin awọn ti Ondo, Amosun ati awọn ọmọ Ọṣọba l’Ogun ko ti i ri ibi gbe ọrọ wọn ka daadaa, ohun gbogbo ṣa ri rudurudu. Ṣugbọn ki i ṣe inu APC nikan, beeyan ba ranti daadaa, yoo ri i pe bawọn oloṣelu ṣe n ṣe nigba ti ẹgbẹ PDP wa nijọba naa niyẹn. Ohun to tumọ si ni pe ko si ẹgbẹ oṣelu kan to daa ju ekeji lọ, awọn oloṣelu funra wọn ni wọn n ṣe aye daadaa, tabi ti wọn n ba aye jẹ. Awọn oloṣelu yii gan-an leṣu. Awọn ni wọn n pa ara wọn, awọn naa ni wọn n ṣeto ibọn ati ada fun awọn tọọgi kaakiri. Bi ẹnikan ba sọ pe ẹgbẹ APC daa, o n tan ara rẹ, tabi to ni ẹgbẹ PDP lo daa ju, wahala lo ko ara ẹ si, ko si ẹgbẹ oṣelu ti ko dara, awọn oloṣelu ole nikan ni ko daa. Bẹẹ awọn oloṣelu ole ni wọn pọ ju nilẹ yii o, ole pọnnbele ni wọn. Wọn ko niṣẹ gidi, awọn to si niṣẹ ninu wọn, iṣẹ ọhun ko mowo gidi wọle, iyẹn lo ṣe jẹ pe nitori ipo kan ti wọn ba ni ki wọn waa lọ sibẹ, wọn yoo maa dena de ara wọn ni, wọn kuku ti mọ pe ko si iṣẹ ti awọn n lọọ ṣe lọhun-un, ka nawo ilu lọfẹẹ, ka si ji eyi ta a ba fẹẹ ji ko ko ni. Ohun to n fa ada to n fa ka yọbọn sira ẹni ree, ka si tun maa foogun le ara ẹni kiri nitori ka le di gomina tabi di ọmọ ile igbimọ aṣofin. Ki gbogbo araalu fura, ẹ mọ pe ole lọpọlọpọ awọn oloṣelu yii, ohun ti wọn yoo jẹ ni wọn n wa, wọn ko fẹran yin, owo ti wọn yoo ji ko lo n ti wọn, ki i ṣe ifẹ araalu kankan. Ẹ ma jẹ ki wọn lo yin o, ki ẹ si ma jẹ ki wọn ba tiyin jẹ ju bayii lọ. Ọlọrun yoo foju awọn aṣebi han, yoo gba wa lọwọ awọn jẹgudujẹra oloṣelu ti wọn n ringboro kiri.

 

(49)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.