Ki lawọn EFCC n ṣe bayii si ni tiwọn

Spread the love

 

 

Bi wọn ba n pe eeyan kan ni abifun-radarada, afi ki onitọhun pa ifun rẹ mọ bi ko ba fẹẹ maa kan abuku kaakiri. Bi wọn ba n pe eeyan ni ole, ko yẹ ki tọhun maa gbe ọmọ ẹran jo, bo ba n ṣe bẹẹ, yoo kan di ole gidi ni. Awọn EFCC ko ran iṣẹ Aarẹ Muhammadu Buhari lọwọ, iyẹn bi a ba fẹẹ sọ ootọ ọrọ funra wa. Kaka ki wọn ran iṣẹ Buhari lọwọ, wọn n ba orukọ rẹ jẹ si i ni. Nigba ti ọrọ oṣelu ti fẹju bayii, iṣẹ ti awọn EFCC n ṣe julo ni lati mu awọn alatako, ẹnikẹni to ba ti sọ pe Buhari ko ṣe daadaa, tabi to ba ti jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu mi-in yatọ si APC lawọn EFCC yoo deyin mọ, ti wọn yoo maa wọ ọ lọ. Tabi kin ni Peter Obi ṣe, iyẹn igbakeji Atiku Abubakar ti wọn jọ fẹẹ du ipo aarẹ. Ki lo ṣe? Ki lo ṣe ti EFCC fi ro pe asiko yii lo yẹ ki awọn lọọ gbẹsẹ le gbogbo ile owo rẹ ni banki, ki wọn si ni ko gbọdọ gba kọbọ kan jade, awọn n ṣe iwadii ẹ lọwọ? Ni ọdun 2014 ni Peter Obi ti gbe ijọba silẹ gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Anambra, o si n rin kiri ilẹ yii lati ọjọ naa. Ki lo waa de to jẹ asiko ti wọn yan an gẹgẹ bii igbakeji ondupo aarẹ fun ẹgbẹ PDP lawọn eeyan yii ṣẹṣẹ ranti pe o yẹ ki awọn yẹ iwe Obi wo. Ko sẹni ti yoo ka alaye EFCC si kinni kan lori iru ọrọ bayii, isọkusọ lasan ni yoo jọ. Bakan naa ni wọn le Doyin Okupe wọ inu ile rẹ, wọn lawọn yoo gbe e. Amọ EFCC ti pe Doyin Okupe yii ri ti wọn lo gba owo kan, wọn si ti ṣewadii rẹ ti wọn ni ko maa lọ. O ṣe jẹ nigba to pada di olupolongo ibo fun Atiku ni awọn EFCC pada ranti ẹ, ti wọn si ya lọọ ba a nile laijẹ pe wọn ti pe e tẹlẹ, tabi pe wọn ti kọwe fun un. Iru awọn iwa wo leleyii nitori Ọlọrun! Ṣe gbogbo ẹni ti ko ba ti faramọ Buhari ni EFCC yoo maa mu ni? Awọn eeyan kan yoo ro pe iwa daadaa ni, inu wọn yoo si maa dun, amọ nigba ti ọrọ naa ba kan wọn, wọn yoo kigbe, wọn yoo ṣomi loju, ko ni i si ẹni ti yoo gba wọn ni. Ko sẹni ti yoo sọ pe ki EFCC ma wadii tabi ki wọn ma mu ẹni to ba ji owo ilẹ yii ko, ṣugbọn lati sọ ileeṣẹ naa di irinṣẹ oloṣelu, irinṣẹ ti Buhari yoo maa lo lati fi dẹruba awọn alatako rẹ ni ko dara. Ko dara o, afi ti ẹ ba fẹẹ sọ EFCC ọhun di idakuda, iyẹn ti ko ba ti i didakuda paapaa!

 

 

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.