Ki l’Atiku n kilolo si, ta lo mu un lohun lọ

Spread the love

Ṣe ẹyin naa wo ohun ti obinrin kan foju Alaaji Abubakar Atiku ri lori tẹlifiṣan lọsẹ to kọja yii, ti wọn gbo o jigijigi, to n laagun tagbara-tagbara. Nibi eto ti wọn ṣe ni Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja yii ni, ti obinrin kan ti wọn n pe ni Kadaria Ahmed ti n fọrọ wa awọn ti wọn ba fẹẹ dupo aarẹ lẹnu wo, ki wọn le sọ ohun ti wọn ba fẹẹ ṣe fun araalu gbogbo. Awọn ibeere buruku kan wa ti wọn beere lọwọ Atiku, paapaa lori ohun ti ọga rẹ, Ọbasanjọ kọ nipa rẹ, nibi ti Ọbasanjọ ti sọ ninu awọn ọrọ rẹ pe ole gidi ni Atiku, beeyan ba fi i si ile owo, yoo sọ ibẹ dahoro, nitori gbogbo owo ibẹ ni yoo ji ko. Diẹ lo ku ki Atiku bẹrẹ si i ṣepe fun Ọbasanjọ to kọ iru ọrọ bẹẹ, ṣugbọn o kan n sọ pe kinni naa ki i ṣe ootọ, ki i ṣe ootọ ni. Wọn beere lọwọ Atiku pe kin ni iwa ibajẹ, kin ni ikowo-ijọba-jẹ, idahun oun naa ko fi taratara tẹẹyan lọrun, nitori gbogbo ohun to ba sọ, ara rẹ ni ọrọ naa ba wi, ara rẹ ni iso ti n run. Igba kan wa ti ọkunrin naa n kilolo, to jẹ igbakeji rẹ, Peter Obi, lo n gba a silẹ, nitori ko ni i mọ ohun ti yoo sọ. Kin ni itumọ gbogbo eyi, itumọ rẹ naa ni pe nigba ti a ba wa ni ipo kan, tabi ti a ba ni anfaani lati ṣe iṣẹ ijọba, ka ṣe e daadaa, ka si fi ọkan si ohun ti a n ṣe. O daju pe ki i ṣe owo nikan ni araalu fi n fẹran eeyan, ẹni to ba ṣejọba daadaa, tabi to ba ṣe iṣẹ ilu daadaa, awọn araalu yoo fẹran rẹ gbẹyin naa ni, wọn yoo si ṣe ojuṣe wọn lasiko ti ọkunrin tabi obinrin bẹẹ ba nilo wọn. Nigba to jẹ Ọbasanjọ ni Atiku ba ṣiṣẹ, wọn jọ ṣiṣẹ ni ọdun mẹjọ ni, Ọbasanjọ si kọ ọ sinu iwe rẹ pe ole ni igbakeji oun, ole taara, ta lo waa ku ti yoo gba a gbọ. Bẹẹ ko daju pe Ọbasanjọ yoo kan deede dide wuya ti yoo maa purọ mọ Atiku, ti yoo si maa pe e ni ole ni gbangba ati kaakiri aye, o daju pe ohun ti Atiku ṣe nigba ti wọn jọ n ṣiṣẹ lo n sọ. Gbogbo ẹni to ba dibo fun Atiku, ọrọ Atiku to sọ pe oun ti yipada lẹ gbagbọ niyẹn, Ọlọrun yoo si jẹ ko jẹ ootọ lo ti yipada, nitori oun naa ki i ṣe ọmọde mọ. Ṣugbọn ju gbogbo rẹ lọ, ẹbẹ la oo bẹ Atiku to ba jẹ oun lo wọle ibo nilẹ yii, gbogbo iwa ti ko daa latijọ, ko wawọ ẹ bọlẹ, ko ma tun ko Naijiria sinu iyọnu. Bẹẹ ni ki eleyii jẹ ẹkọ fun gbogbo ẹni ti yoo pada waa di ipo pataki mu ni Naijiria, ipo kekere ti ẹ ba wa loni-in, ẹ ṣe e daadaa, ẹ ṣe ootọ nibẹ ki awọn ti ẹ ba ba ṣiṣẹ le sọrọ yin daadaa lọla. Bi Atiku ba ṣe daadaa ni, bi Ọbasanjọ ti n sọrọ rẹ laidaa yii naa ni yoo maa sọ ọ, ti yoo si maa fi ye gbogbo eeyan pe daadaa ni igbakeji oun ṣe nigba ti awọn jọ n ṣejọba. Ko si bi Atiku yoo ṣe ṣe e, ẹni to jale lẹẹkan ni, bo ba pada waa da aṣọ aran bori, wọn yoo ni aṣọ ole lo da bora ni. Ko si ohun ti Atiku yii ni ti wọn ko ni i ni ole lo ja, abawọn naa ṣi wa lara rẹ, oun lo n ba a kiri bayii, oun naa si ni awọn to ṣeto lori tẹlifiṣan fi n bu u. Ki gbogbo oloṣelu ati oṣiṣẹ ijọba fi kọgbọn, nitori ọjọ n bọ ti wọn yoo beere ohun ti kaluku ṣe lọwọ rẹ o. Ajẹgbe kan ko si ladiẹ irana, adiẹ irana ki i ṣe ajẹgbe o.

 

(10)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.