Ki l’Amosun tun n duro ṣe ninu APC

Spread the love

Bi Amosun ko ba kuro ninu APC, niṣe lo yẹ ki awọn adari ẹgbẹ naa le e jade. Ko si oore ti yoo ṣe fun ẹgbẹ naa mọ, yoo kan ba ẹgbẹ naa jẹ ni. Gbogbo awọn ọmọ ẹyin rẹ to fa kalẹ pe wọn fẹẹ dupo kan tabi omi-in ni wọn ti kọja sinu ẹgbẹ APM, wọn si fi orukọ ẹgbẹ oṣelu wọn yii silẹ bẹẹ ko le bọ sẹgbẹẹ orukọ APC ninu iwe eto idibo ni. Ibo sẹnetọ ati ti aarẹ ni wọn yoo di sọwọ asiko kan naa, ọjọ kan naa ni ibo awọn mejeeji yii yoo bọ si. Ohun to si jọ pe Amosun fẹẹ ṣe to fi n pariwo pe Akinlade ti oun fa kalẹ to ti wa ninu APM bayii ni yoo wọle ni lati dibo aarẹ tan lorukọ APC, ko si ran Buhari ati ara rẹ lọwọ, ṣugbọn to ba di ibo gomina ati ti awọn aṣofin ipinlẹ Ogun, APM ni yoo dibo fun, nigba to jẹ oun lo ni ẹgbẹ oṣelu naa, tabi ta lo tun gbọ orukọ ẹgbẹ naa nibi kan. Amosun ti fọ ẹgbẹ APC si meji bayii, ọna ti yoo gba fọ ẹgbẹ naa patapata ni ipinlẹ Ogun lo ku to n wa, ti ẹgbẹ naa ko si ni i ni eeyan ni ile aṣofin tabi nipo gomina ipinlẹ wọn. Amosun fẹẹ fi han awọn alaṣẹ APC ati awọn ọmọ Ogun pe alagbara kan ju alagbara mi-in lọ, ohun to fẹẹ ṣe niyẹn. Nigba ti eeyan ba tori pe o fẹẹ jẹ oye idile rẹ ti ko ri i jẹ, to ni ki awọn eeyan waa dana sun ile awọn naa, ki wọn si pa gbogbo awọn ti wọn ba wa nibẹ, ọmọ ọkọ ni wọn yoo pe iru ẹni bẹẹ ninu ẹbi tabi ọmọ ale. Wara ko si loni-in, ṣe iyẹn sọ pe wara ko le si lọla ni. Bi Amosun ba fa awọn eeyan kalẹ lasiko yii ti wọn ko ba wọle, ọjọ meloo ni ọdun mẹrin yoo fi pe ti yoo fa awọn tirẹ kalẹ. Iyẹn yoo ṣee ṣe bi ẹgbẹ oṣelu wọn ba ṣi wa ni, bi ẹgbẹ oṣelu ba ti fọ, ko si aaye fun iyẹn mọ. Iwa ilara, wọbia, a-nikan-jọpọn, emi-ni-mo-jaja-to-bayii, ko-siru-mi-nilẹ-yii ati awọn iwa igberaga bẹẹ ni yoo mu eeyan ṣe iru ohun ti Amosun ṣe yii. Bi ẹgbẹ APC ba fẹran ara wọn, ti wọn si fẹẹ wa alaafia, ẹ tete le Ibikunle Amosun nibẹ, jẹjẹrẹ ti yoo jẹ ẹgbẹ yin run ni o.

 

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.