Ki Fayẹmi ma fi iyẹn bẹrẹ o

Spread the love

Ki gomina Ekiti ana, Ayọdele Fayoṣe, too pada de lati yunifasiti awọn EFCC to sare lọ lawọn aṣofin ipinlẹ naa ti n gba ara wọn jọ, wọn ni awọn yoo yẹ ijọba Fayoṣe wo, awọn fẹẹ wadii awọn owo kan to sọnu ati awọn owo kan ti wọn na, pẹlu bi wọn ti ṣe na an. Lọrọ kan, wọn fẹẹ wo bi Fayoṣe ti ṣe ṣejọba si. Gbogbo aṣofin ti ẹ ba ri to ba n sọ bẹẹ, oniranu ni wọn, ẹ ma da wọn lohun o. Awọn aṣofin ti wọn ba Fayoṣe jẹ ti wọn ba a mu naa lo pọ ninu awọn ti wọn fẹẹ wadii ẹ wo yii, ko si si ohun ti wọn fẹẹ wadii ju lati sọ fun Gomina Kayọde Fayẹmi pe tirẹ lawọn n ṣe, awọn wa lẹyin rẹ. Itumọ iyẹn ni pe ki i ṣe ti awọn ara Ekiti lawọn aṣofin yii n ṣe, wọn n ṣe ti gomina to ba wa lori oye, nitori ki owo ati awọn ijẹkujẹ tiwọn le maa lọ lai duro ni. Tabi ki lo de ti wọn ko yẹ ijọba Fayoṣe wo nigba to wa nibẹ, to si jẹ pe wọn jọ n ṣe e ni. O ṣe waa jẹ nigba ti ọkunrin naa kuro tan ni wọn mọ pe awọn yoo yẹ ijọba rẹ wo. Bẹẹ ni wọn royin pe ijọba n wadii ibi ti Fayoṣe kọ ile kan si, wọn fẹẹ wo ile naa tabi ki wọn gba a. Bo ba jẹ ibi ti Fayoṣe kọ ile rẹ si ko daa, tabi bo ba jẹ ilẹ ijọba lo gba to fi kọ ile naa bi wọn ti n wi, bi ijọba ba gba a pada ko ṣe nnkan kan, eleyii yoo si jẹ ẹkọ fun awọn mi-in ti wọn ba n ṣejọba pe bi wọn ba lọ tan, awọn ohun ti wọn ti de mọlẹ, awọn kan n bọ ti wọn yoo tu u. Ṣugbọn ti ki i baa ṣe bẹẹ, to ba jẹ ọrọ oṣelu lasan, ati ki Fayẹmi le fabuku kan Fayoṣe ni wọn ṣe n ṣe gbogbo eleyii, ki Fayẹmi ma fiyẹn bẹrẹ ijọba rẹ o. Lara awọn ohun to gbe e ṣubu lọjọ kin-in-ni ana niyi, lara awọn ẹsun ti awọn olori ẹgbẹ wọn paapaa n fi i kan an naa niwọnyẹn. Bi ẹ ba ri Fayẹmi, ẹ sọ fun un, ko ma fi ọtẹ ati iwa mo-fẹẹ-gbẹsan bẹrẹ ijọba rẹ, bo ba ṣe bẹẹ, igbẹyin rẹ ko le dara, oun naa yoo si pada waa ko ẹsan awọn ohun to ba ṣe lọjọ iwaju. Ki Fayẹmi dojukọ awọn ọmọ Ekiti, ko si ṣejọba rere fun wọn ti wọn ko fi ni i gbagbe orukọ rẹ laye, ohun ti i mu igbẹyin aye ẹni dara niyẹn o.

(63)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.