KẸMI ADEỌṢUN: IDAAMU MINISITA BUHARI YII MA N PỌ SI I NI O

Spread the love

Wẹrẹ ni ọrọ naa bẹrẹ, ṣugbọn ọrọ naa ti fẹju bayii o, afaimọ ki kinni naa ma gbe ọkan ninu awọn minista Buhari yii mi, nitori ibi ti ọrọ naa fẹẹ jalẹ si ko jọ ilẹ ire. Arabinrin Kẹmi Adeọṣun ni o, obinrin ti Aarẹ Muhammadu Buhari yan gẹgẹ bii minista fun eto inawo lọdun 2015. Ko sẹni ti ko royin pe iṣẹ obinrin naa daa, wọn lo mọwe, o si mọ nipa eto ọrọ aje yii pupọ, Buhari si fẹran rẹ gẹgẹ bi a ti gbọ. Afi bo ṣe di ọsẹ to kọja lọhun-un ti ariwo ta pe obinrin naa ko ni sabukeeti kan to yẹ ko ti gba sọwọ tipẹtipẹ, bẹẹ bi ko ba ni sabukeeti yii, ko yẹ ko ṣiṣẹ ni Naijiria rara, ofin orilẹ-ede wa lo si sọ bẹẹ, ki i ṣe ẹnikan. Ṣugbọn Kẹmi Adeọṣun mu sabukeeti naa silẹ nigba to fẹẹ gba iṣẹ, eyi ni ko si sẹni to di i lọwọ pe ko le di minista tabi ṣiṣẹ ijọba, afi bi wọn ṣe waa wadii sabukeeti yii wo ti wọn ni ayederu ni.

Sabukeeti awọn agunbanirọ ni, iyẹn NYSC. Bi gbogbo ọmọ ba lọ si ile-ẹkọ giga, bo jẹ yunifasti, bo si se poli, nigba to ba ti jade, ko too bẹrẹ iṣẹ, yoo lọọ sin orilẹ-ede baba rẹ, nigba naa ni wọn maa n ko kaki bọ wọn lọrun bii ti ṣọja, ti wọn yoo si gbe wọn lọ si ipinlẹ mi-in ti ki ṣe tiwọn, wọn yoo ṣiṣẹ nibẹ fun ọdun kan. Iyẹn ni wọn n pe ni NYSC, tabi iṣẹ agunbanirọ.

Nigba ti wọn ba ṣiṣẹ naa tan ni wọn yoo too fun wọn ni sabukeeti, sabukeeti naa yoo si fi han pe loootọ ni wọn ti ṣiṣẹ sin ilẹ baba wọn. Bi wọn ba ti ni sabukeeti naa lọwọ, ko si ibi ti wọn ko ti le ṣiṣẹ ni Naijiria, bẹẹ ni ko si iṣẹ ijọba ti wọn ko le se, tabi ipo pataki ti wọn ko le di mu. Gbogbo ọmọ Naijiria pata lo gbọdọ ṣe e, ẹni yoowu to ba ti jade ni yunifasiti tabi ile ẹkọ giga yoowu lai ti i pe ọmọ ọgbọn ọdun.

Bẹẹ ni. Bi eeyan ba kawe jade ni ile-ẹkọ giga, to jẹ ọmọ Naijiria, ibi yoowu to ba ti kawe ẹ, ti ko si ti i pe ọmọ ọgbọn ọdun to fi jade, o gbọdọ lọọ ṣiṣẹ sin Naijiria ilẹ baba rẹ, koda ko jẹ ilu oyinbo lo wa, o gbọdọ pada wale lati wa a ṣe e. Bẹni bẹẹ ko ba ṣe e, ko gbọdọ ṣiṣẹ kan ni Naijiria, nitori o lodi sofin pe ẹnikan jade yunifasti ko ṣe e, ijiya si wa fun un. Bo ba lọọ gba iṣẹ yoowu lai ṣe agunbanirọ, ẹwọn ọdun meji ni yoo lọ. Ẹni to gba a siṣẹ naa yoo jiya, yoo sanwo itanran, onileeṣẹ naa le ṣẹwọn, nitori ẹni to gba siṣẹ ti ko ni sabukeeti yii. Iyẹn lo ṣe jẹ dandan fun gbogbo ẹni to ba fẹẹ gbaayan siṣẹ kankan ni Naijiria yii lati beere iwe agunbanirọ ẹni to fẹẹ gba siṣẹ. Ṣugbọn bi eeyan ba ti pe ọgbọn ọdun, to ba kọwe si NYSC pe oun ko ṣe e, wọn yoo gba, wọn yoo si fun un ni sabukeeti ọtọ.

Sabukeeti wa ti wọn maa n fun ẹni to ba ti pe ọgbọn ọdun ti ko si fẹẹ ṣe agunbanirọ yii, wọn yoo ya a sọtọ pe ko ṣiṣẹ sinlu nitori pe o ti le ni ọmọ ọgbọn ọdun bi ofin ti sọ. Iru sabukeeti iyasọtọ yii ni wọn fun Kẹmi Adeọṣun, oun naa lo si pada waa di ariwo. Bo ṣe jẹ ni pe ilu oyinbo ni wọn bi Kẹmi Adeọṣun si, nibẹ lo si ti kawe, to jade ni East London Polytechnic. Ọdun 1989 lo ṣetan nibẹ nigba to wa ni ọmọ ọdun mejilelogun, nitori ọdun 1967 ni wọn bi i. Gẹgẹ bi ofin Naijiria, lasiko to jade yii, dandan ni fun un lati waa ṣiṣẹ sin ilẹ baba rẹ, ko si pada sibi to ti wa. Ṣugbọn Kẹmi ko wa, nitori gbogbo igba naa, boya lo ro pe kinni kan wa ti yoo gbe oun wa si Naijiria lati waa ṣiṣẹ, nitori o mọwe gan-an, awọn ileeṣẹ oriṣiiriṣii ni wọn si n du u mọ ara wọn lọwọ niluu oyinbo.

Ṣugbọn nigba to ṣiṣẹ de ibi kan, awọn ileeṣẹ kan gba a si Naijiria yii lati waa ṣe ọga nibẹ, bo tilẹ jẹ niluu oyinbo naa ni wọn ti mu un wa. Lọdun 2002 leyi, awọn yii ko si le maa beere iwe agunbanirọ lọwọ rẹ nigba ti ki i ṣe Naijiria ni wọn ti gba a siṣẹ, to jẹ niluu oyinbo ni, iru ofin ti Naijiria yii kọ ni wọn si n lo lọdọ tiwọn. Obinrin yii n ṣiṣẹ ni Naijiria, ṣugbọn ko ni iwe ẹri awọn agunbanirọ, bi ọwọ ba si tẹ ẹ nigba naa, ẹgbẹrun marun-un owo itanran ni yoo san, tabi ko lọ ṣẹwọn fun ọdun meji. Ni ọdun 2009, o jọ pe nnkan yipada, obinrin naa n wo o pe afaimọ ki oun ma ri iṣẹ to lagbara, tabi to lorukọ gba ni Naijiria ju eyi to gbe oun wa lọ. Igba naa lo ṣeto, boya awọn kan ni wọn si ba a ṣeto iwe agunbanirọ naa, ni wọn ba gbe sabukeeti Oluwọle le e lọwọ, ẹbu tabi goje ni wọn n pe e, ayederu pata ni.

Loootọ ẹni to ba ri i ko ni i tete mọ pe ayederu ni, nitori bi sabukeeti awọn NYSC ti i ri naa lo ri, iyẹn sabukeeti pe oun ti dagba kọja ẹni ti i ṣe agunbanirọ. Ṣugbọn awọn ti wọn mọ itan ileeṣẹ naa mọ pe ẹbu ni. Idi ni pe ẹni to sain sabukeeti naa ninu oṣu kẹsan-an, ọdun 2009, Ọgagun Yusuf Bomoi, ti kuro ni ileeṣẹ naa lati Januari, oṣu kin-in-ni, ọdun naa. Bawo waa ni ẹni to kuro nileeṣẹ lati inu oṣu kin-in-ni yoo ṣe pada waa fọwọ siwee ninu oṣu kẹsan-an, ohun to jẹ ki ọrọ naa di ariwo ree nigba ti iwe-iroyin ori-intanẹẹti ti wọn n pe ni ‘Premium Times’ ru kinni ọhun jade. Ohun to jẹ ki aṣiri ọrọ yii tete tu ko ju ajọṣe buruku to wa laarin Kẹmi Adeọṣun to ti di minista fun Buhari ati awọn aṣofin lọ. O jọ pe awọn aṣofin kan mọ pe ayederu sabukeeti NYSC lo wa lọwọ Kẹmi, wọn si fi n gba owo lọwọ rẹ. Owo buruku!

Kọmisanna ni obinrin yii kọkọ ṣe nipinlẹ Ogun, ko si too di igba naa, ko sẹni to gbọ orukọ rẹ ri rara. Ṣugbọn iṣẹ to ṣe tẹ ọga rẹ, Ibikunle Amosun, lọrun debii pe nigba ti wọn yan Buhari ni 2015, ko ṣiyemeji lati sọ pe oun mọ pe obinrin yii yoo dara ju nidii eto inawo fun Aarẹ, nitori ohun to ti fi ọpọlọpọ ọdun ṣe niyẹn. Asiko to fẹẹ gba iṣẹ yii lawọn aṣofin kan ti wọn jẹ ọga nibẹ ti ri i pe ara ilu oyinbo ni, ibẹ lo ti ṣe kekere ẹ, wọn si ti mọ pe ko ṣe agunbanirọ. Awọn kan ti wọn ti mọ aṣiri yii lati ipinlẹ Ogun lati asiko to ti fẹẹ ṣe kọmisanna nibẹ ni wọn gbe kinni ọhun fun awọn ọga aṣofin ni Abuja, iyẹn lawọn naa si mu sọwọ. Niṣe ni wọn pe e sẹyin ti wọn sọ fun un pe awọn mọ pe ko ṣe agunbanirọ, iru ọrọ bẹẹ ko si gbọdọ jade sita, ṣugbọn awọn yoo bo o laṣiiri, awọn ko ni i tu u sita.

Bẹẹ ni wọn bo o laṣiiri, o si bẹrẹ iṣẹ rẹ bii minista, gbogbo aye si n royin rẹ pe akọni obinrin kan ni nidii eto inawo, ki i kowo jẹ, bẹẹ ni ki i gba riba, o si mọ kinni ọhun kọja wẹrẹwẹrẹ. Ṣugbọn iṣoro kan to ni naa lawọn aṣofin, bi wọn ba ti fẹ owo kan, tabi to ba ti fẹẹ wadii owo inakunaa kan ti wọn na, wọn yoo sare fa a sẹyin pe ko ranti o, aṣiri ẹ n bẹ lọwọ awọn. Ni Kẹmi naa yoo ba farabalẹ, yoo si ṣe ohun ti wọn ba fẹ fun wọn. Ọrọ naa di nnkan to n ya awọn ti wọn n ba Buhari ṣiṣẹ lẹnu, pe Adeọṣun ti ki i gba gbẹrẹ, ki lo waa de to n gba regberegbe bayii fawọn aṣofin. Eleyii ni wọn n sọ lọwọ laṣiiri fi tu, ti wọn ni Kẹmi ko ṣe NYSC, sabukeeti ẹ-ya-mi-sọtọ to si n gbe kiri, ayederu ni. Nigba naa lariwo ọrọ yii ti bẹrẹ.

Loootọ NYSC ti gbe iwe jade lori ọrọ yii, wọn ni ayederu ni iwe-ẹri yii loootọ, awọn si n ṣewadii lọwọ lori ibi ti sabukeeti naa ti jade, awọn eeyan mọ pe irọ ni, ko si iwadii kankan ti wọn yoo ṣe lori ẹ ju pe wọn fẹẹ bo o mọlẹ lọ. Alaaji Lai Muhammed ti i ṣe Minista fun eto iroyin naa ti sọrọ pe ibi ti NYSC wa lawọn naa wa, iwadii n lọ lọwọ, ṣugbọn awọn eeyan ko gba Lai paapaa gbọ, wọn ni bo ba jẹ ti Lai ni, ki wọn tete yaa mu ọrọ mi-in sọ. Ṣugbọn awọn ajijagbara ti n ṣa ara wọn jọ bayii, bẹẹ ni awọn ẹgbẹ ti wọn n gbogun ti iwa ibajẹ ati awọn ẹgbẹ alatako, wọn ni afi ki Buhari le Adeọṣun lọ. Wọn ni ko si iwadii kankan ti wọn n ṣe lori ọrọ yii, ootọ ibẹ ti farahan pe ayederu iwe ni Kẹmi n gbe kiri. Kẹmi funrarẹ ko ti i sọrọ lati ọjọ ti wahala yii ti bẹrẹ, ko sẹni to mọ ohun to wa ninu rẹ tabi ohun to fẹẹ wi, nitori oun gan-an ko mọ ohun ti yoo gbẹyin ọrọ yii, awọn ọga rẹ paapaa ko si mọ ohun to le ti idi rẹ yọ.

 

 

 

 

(47)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.