Kẹlẹnu ṣẹnu ẹ, awọn ọlọpaa Buhari n bọ

Spread the love

Ẹni to ba leti ko gbọ o, ki gbogbo yin ma sọ pe ẹ ko gbọ. Ẹni to ba sọ ọrọ buruku kan, tabi to ba sọ ọrọ ikoriira, Aarẹ Muhammed Buhari ti sọ pe awọn agbofinro yoo gbe e o. Bi wọn ba si gbe iru ẹni bẹẹ, keremọnje lo n lọ yẹn. Eyi to si le ninu ọrọ naa ni pe ko sẹni to mọ iru ọrọ ti eeyan yoo sọ ti yoo pada di ọrọ buruku, tabi ti yoo di ọrọ ikoriira. “Hate speech”, ọrọ ikoriira ni Buhari funra rẹ pe e, o ni ẹni to ba ti sọ ọ, awọn agbofinro yoo gbe e. Ni Yunifasiti Uyo ni Buhari ti sọrọ yii nigba to ranṣẹ si wọn lasiko ti awọn yẹn n ṣe ikẹkọọjade wọn lọsẹ to kọja yii. O ni ijọba oun ko ni i fi aaye gba ọrọ ikoriira mọ, bẹẹ ni ẹni to ba sọrọ buruku yoo ba ara rẹ nibi ti ko fẹ, o ni lati asiko yii lọ, awọn agbofinro yoo maa ṣa gbogbo wọn ni. Loootọ awọn ọrọ kan wa to jẹ isọkusọ pọnnbele ati ahesọ ti ko nitumọ, iru ẹni to ba si sọrọ bẹẹ gbọdọ jade ko waa ṣalaye ohun to fa a to fi sọ bẹẹ, tabi ko fi ootọ ọrọ to sọ mulẹ. Ṣugbọn ni awọn orilẹ-ede to ti laju daadaa, ko si ẹni to n mu ni pe eeyan ṣe fi ẹnu ara rẹ sọrọ, bi ọrọ ti tọhun ba sọ ko ba jẹ ododo, tabi to ba purọ mọ ẹnikan, tabi to ba pe ẹnikan ni orukọ ti ki i ṣe tirẹ, to ba a lorukọ jẹ boya ninu ọrọ ẹnu tabi ninu akọsilẹ, ile-ẹjọ ni tọhun yoo gba lọ, nigba ti awọn adajọ ba si bu owo ti tọhun ko le san tan laye fun un, ti wọn gba gbogbo dukia rẹ ti ko ba ri gbese san, kia ni iru ẹni bẹẹ yoo sinmi ikọkukọ tabi isọkusọ. Ibẹru eyi gan-an ki i jẹ ki awọn eeyan tilẹ purọ mọ ẹnikan tabi ki wọn ba awọn eeyan lorukọ jẹ. Ṣugbọn ko si orilẹ-ede ti wọn ti n fi ọlọpaa tabi SSS gbe ni nitori eeyan sọ ọrọ ẹnu rẹ, ijọba ologun lo maa n ṣe bẹẹ, asiko si niyi ki Buhari mọ pe a ko si ni aye ologun ni Naijiria, aye Dẹmokiresi la wa, nibi ti kaluku yoo ti sọ ohun to ba wa ninu rẹ jade. Bi eeyan ba si mọ ijọba Buhari yii, ati awọn iwa ti wọn hu lati ọjọ yii wa, tọhun yoo mọ pe ki i ṣe ẹni to ba sọrọ buruku tabi ọrọ ikoriira ni wọn yoo maa wa kiri, ẹni to ba bu Buhari tabi to ba sọ pe o ṣe ohun ti ko dara ni wọn yoo maa mu, ti wọn yoo si maa ti wọn mọle. Ofin eleyii ki i ṣe ofin gidi, ọgbọn lati maa ko awọn alatako tabi awọn ti wọn ba sọ ootọ ọrọ ti mọle ni. Ṣugbọn ete ati abuku ni yoo gbẹyin iru eyi, nitori nigba to ba su awọn ọmọ Naijiria, oko ati epe nla kan ni wọn yoo fi le Buhari funra rẹ jade, yoo si kuro ni ọrọ buruku tabi ọrọ ikoriira. Bi Buhari ti ṣe lọdun 1984 ree ti wọn bẹrẹ si i ko awọn oniroyin ti mọle, ti wọn fẹẹ pa ẹnu awọn to ba sọ ododo mọ tipatipa, ki wọn le maa ṣe ohun to ba wu wọn laarin igboro. Ṣugbọn ki lo gbẹyin ẹ, ọjọ meloo ni wọn fi ṣe e ki wọn too le wọn danu. Oko iru ẹ naa ni Buhari tun n ro yii, bi ko ba si ṣọra, bo ti ṣẹlẹ si i lọjọsi naa ni yoo pada ṣẹlẹ si i lasiko yii, nitori aye ti laju kọja ibi ti ijọba kan yoo sọ pe ki araalu ma sọrọ, ẹni to ba sọ ohun ti ko daa, ile-ẹjọ ni wọn n gbe iru wọn lọ, ọrọ ti ko lọwọ ọlọpaa tabi agbofinro kankan ninu ni. Bi wọn ba purọ mọ Buhari, bo si jẹ awọn ti wọn n ba a ṣiṣẹ ni wọn ba lorukọ jẹ, ile-ẹjọ wa nibẹ, ki wọn pe ẹjọ ki awọn adajọ si ba wọn da a. Ṣugbọn bi ijọba yii ba fẹẹ sọ ara rẹ di ijọba pakaleke, ijọba aninilara, awọn ọmọ Naijiria ko ni i gba fun un. Ohun to buru ni pe ko sẹni to ro gbogbo iru eleyii to n ṣẹlẹ yii ro Buhari rara, ṣugbọn a ti ko sinu ẹ bayii, bi Ọlọrun yoo ti ṣe yọ wa lo ku ka maa tọrọ.

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.