Kayọde lu jibiti miliọnu mẹfa Naira, wọn ti wọ ọ lọ sile-ẹjọ

Spread the love

Ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu mọku-mọku (EFCC), ti wọ ọkunrin kan, Kayọde Kikiowo, lọ si ile-ẹjọ giga to wa ni Ikẹja, niwaju Onidaajọ Sherifat Ṣolẹbọ, nibi ti wọn ti fi ẹsun marun-un ọtọọtọ, eyi to ni i ṣe pẹlu pipurọ gbowo, ṣiṣe ayederu iwe ati lilo awọn ayederu iwe lati gba owo to to miliọnu mẹfa, o le diẹ Naira (N6,740,000.00).
Gẹgẹ bi atẹjade ti ajọ naa fi sita, wọn ni ṣe ni Kayọde sọ fun Ọgbẹni Izegaegbe Ehikhueme pe oun laṣẹ lọdọ ileeṣẹ Aṣọbode ilẹ yii gẹgẹ bii awọn to maa n ta ọja wọn, (Clearing agent), ati pe oun le baa gbe ọkọ kọntena to gbe awọn ọkọ wọle fun un to wa lọdọ ajọ naa jade to ba le fun oun ni miliọnu marun-un Naira.
Bii miliọnu mẹfa, o le die (N6,740,000.00), ni wọn ni Kayọde gba lọwọ ọkunrin naa. Iwadii ajọ yii fidi ẹ mulẹ pe ayederu ni gbogbo iwe ti olujẹjọ ko fun ọkunrin naa.
Kayọde loun ko jẹbi ẹsun yii, eyi lo si mu Agbẹjọro Ajọ EFCC, Franklin Ofoma, ko awọn ẹlẹrii jade, ti wọn si jẹrii tako olujẹjọ naa.
Adajọ Ṣolẹbọ ti paṣẹ pe ki wọn ṣi fi ọkunrin naa pamọ si ahamọ ọgba ẹwọn, o si sun igbẹjọ mi-in si ọla, Ọjọruu, Wẹsidee.

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.