Kayeefi kan ree o! Ojo fun ọmọ iyawo ẹ loyun n’Ibadan Lori bẹẹdi ti oun ati iya re n sun naa lo ti n ba a lo po

Spread the love

Iyawo ti bimọ obinrin kan fun ọkunrin mi-in ṣaaju igbeyawo wọn. Inu yara kan ṣoṣo ti tọkọ-tiyawo yii n gbe laduugbo Odińjó, n’Ibadan, pẹlu ọmọ meji ti wọn bi lọmọdebinrin ti iyawo ti bi tẹlẹ ọhun naa n gbe pẹlu wọn, iyawo ko si mọ nnkan kan titi ti Ojo Afisi Raimi ti i ṣe ọkọ fi fun ọmọ iyawo ẹ loyun.

 

Kayeefi inu ọrọ yii ni pe lasiko ti gbogbo wọn ba jọ n sun lọwọ ninu yara naa ni Ojo ati Aanu Adedokun ti i ṣe ọmọ iyawo ẹ maa n ba ara wọn laṣepọ, Ọpẹyẹmi Adedokun to jẹ iyawo ko si fi igba kan bayii mọ pe iru nnkan bẹẹ n ṣẹlẹ lẹgbẹẹ oun, nibi ti oorun àsùnpiyè ba a jẹ de.

 

Ọmọọdun mẹtala lọmọ ti wọn fun loyun yii, iya ẹ jẹ ẹni ọdun mẹrinlelogun, iyẹn ni pe ọmọọdun mejila l’Ọpẹyẹmi paaapaa wa nigba to bi Aanu.

 

Nigba to n royin itan bo ṣe bi Aanu, Ọpẹyẹmi sọ pe ọmọkunrin kan to n jẹ Friday Thomas loun bi i fun. O ni lati Kutọnu, nilẹ Binin, lo ti waa kawe nilẹ yii, ṣugbọn bo ṣe fun oun loyun lo pada siluu wọn. Bẹẹ loun dẹni to n ṣe iya ṣe baba fun ọmọ naa nitori oun ko gburoo baba ẹ mọ lati igba ti oun ti loyun ẹ.

 

Ni nnkan bii ọdun marun-un sẹyin ni Ojo ati Ọpẹyẹmi fẹra, ṣugbọn ko ti i ju ọdun mẹta lọ ti ***Aina bẹrẹ si i gbe ọdọ wọn. Lati igba naa ni ẹwa ọmọdebinrin naa si ti wọ ọkọ iya ẹ loju, ṣugbọn to n pa a mọra titi ti kinni ọhun fi kọja afarada fun un.

 

Ojo to jẹ báábà, ṣugbọn ti ko ri ṣọọbu ṣiṣẹ ọhun, fidi ẹ mulẹ, o ni “mi o mọ nnkan to de ti mo fi n ba ọmọ yẹn sun. Nnkan ti mo ṣaa mọ ni pe nnkan kan ti n ṣẹlẹ ninu ile wa. Koda, mo sọ fun iyawo mi lọjọ kan pe nnkan kan n ṣẹlẹ ninu ile yii o, o ni ki lo n ṣẹlẹ, ṣugbọn emi gan-an ko le ṣalaye ẹ.

 

“Inu nẹẹti lemi ati iya ẹ maa n sun, ìgbásẹ̀ wa loun maa n sun. Lọjọ ti mo kọkọ bẹrẹ, emi ni mo lọọ ba a. Mi o mọ ohun to ṣe mi. Oju oorun lo wa. Mi o sọrọ, oun naa ko si sọ nnkan kan titi ti mo fi ṣe e tan. O wọṣọ sun lọjọ yẹn, emi ni mo fọwọ fa sikẹẹti rẹ walẹ. Nigba ti mo ṣe e tan loju mi waa la pe iru aṣiṣe wo ree.

 

“Mi o le sọ nnkan to ṣẹlẹ. Ani emi gan-an ni mo n sọ fun iya ẹ pe ko beere nnkan to ba n ṣe e lọwọ ẹ. Iya ẹ gan-an ti sọ pe oun ko ni i ya si i mọ nitori oun paapaa ki i loogun. Emi ni mo tun fi dandan le e pe a ni lati tọju ẹ ni. Aṣe ara mi ni iso ti n run, nigba ti wọn ṣe ayẹwo fun un ni wọn sọ pe ko si nnkan to ṣe e, oyun lo ti duro si i lara.”

 

Igbagbọ ọkunrin tawọn eeyan saaba maa n pe ni OJ laduugbo wọn yii ni pe ki i ṣe oun nikan loun jẹ gbogbo ẹbi ọrọ to wa nilẹ yii, ọmọ iyawo oun paapaa ní lọwọ, ati pe ibalopọ wulẹ ti mọ oun funra rẹ lara daadaa ko tilẹ too di pe oun bẹrẹ si i wọle tọ ọ rara.

 

O fi alaye gbe awijare ẹ yii lẹsẹ, o ni, “lọjọ kan ti mo tibi iṣẹ de lasiko ti ojo n rọ lọwọ, mo ba a (Aina) nibi ẹyinkule ile wa, mo ni ki lo n ṣe ninu ookun yii, o lọkunrin kan lo n kọnu ifẹ si oun nibẹ. Nigba ti mo le mọ ọn, o jẹwọ pe awọn n kíìsì ara awọn ni. Mo sọ fun iya rẹ naa nigba to de, mo si kilọ fun un pe ko gbọdọ ran an jade mọ.

 

“Oju oorun lo maa n wa ni gbogbo igba ti mo maa n ba a laṣepọ. Ẹẹkan ti mo kọkọ ṣe e ta a jọ ri ara wa lojukoju bayii ṣẹlẹ lọjọ ti iya ẹ ko si nile, oun ati iya mi ni wọn jọ lọ sibi inawo kan lọjọ yẹn. Lẹyin wakati kan aabọ si wakati meji ta a jẹun alẹ tan ni mo ji i dide, ti mo si ba a sun.

 

Nigba ta a jọ ni aṣepọ tan, mo ni ***Aanu, ma sọ fun mi pe o ko ti i mọ ọkunrin kankan tẹlẹ. O ni oun maa jẹwọ, ki n ma na oun. O ni alakọọkọ, oun n fẹ ẹnikan to n ṣe baaba, awọn mẹta kan si tun reepu oun lọna Mọdina lọjọ kan, ṣugbọn ẹni kan ṣoṣo lo ba oun sun ninu wọn. Mo ni bawo ni ẹni yẹn ṣe ṣe e, o ni bawo ni wọn o ṣe le ṣe e. Bo ṣe fun mi lesi naa niyẹn.”

 

Ki i ṣe Iya ***Aina nikan niyawo Ojo, ọmọ mẹta ti iyaale ẹ si ti bi lo sọ apapọ ọmọ rẹ di marun-un, ṣugbọn ọtọ nibi tawọn ọmọ iyaale n gbe. Ilu Abuja ni iya wọn wa bayii, aajo jijẹ mimu lo ba lọ nigba ti ọkọ ko niṣẹ lọwọ debi ti yoo rowo gbọ bukaata oun atawọn ọmọ ẹ.

 

Ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn (27), to niyawo meji fidi ẹ mulẹ fakọroyin wa pe, “ọdun kẹjọ ree ti mo fẹ iyawo akọko, o si ti bimọ mẹta. Asiko ti oun bimọ ẹlẹẹkeji niyawo bimọ akọkọ, awọn mejeeji jọ n ṣabiamọ papọ ni. Mo ti n fẹ Iya ***Aina ko too di pe o bi **Aina. Nigba ti ko si owo kankan lọwọ mi ni mo wa iṣẹ lọ s’Ekoo, ti iyaale mi naa si ṣe aajo aje lọ si Abuja, ko too di pe emi pada s’Ibadan ni temi.”

 

Ni ibamu pẹlu ibeere akọroyin wa, Ojo sọ pe, “mi o muti mọ. Igba ti mo wa l’Ekoo nikan ni mo maa n muti. Mo mọ pe ohun ti mo ṣe yii ko daa. Ti eeyan ba ṣeru ẹ fun ọmọ mi, mi o le sọ nnkan ti mo maa ṣe fun onitọhun, nitori inu temi naa ko le dun. Iranlọwọ ti mo fẹ ki awọn ẹbi iyawo mi ṣe fun mi lori ọrọ yii ni pe ki wọn dariji mi.”

 

Ojuṣe baba si ọmọ ni Ojo n ṣe si **Aina, oun lo n sanwo ileewe ẹ, ileewe aladaani paapaa lo si fi i si. Bẹẹ lo tun fi i si ẹnu ẹkọṣẹ telọ, eyi to n lọ nirọlẹ irọlẹ, lopin ọsẹ ati ni gbogbo igba ti wọn ba wa lẹnu isinmi nileewe. Dadi, Dadi naa si ni ***Aina pe e, ṣugbọn loju iya ẹ ati loju gbogbo aye nikan lo ti maa n pe e bẹẹ bo ba ku awọn mejeeji nikan, OJ ti gbogbo araadugbo maa n pe ọkọ iya ẹ yii loun naa maa n pe e, iyẹn naa ko si jẹ fi ṣe ibinu.

 

Yatọ si pe oju **Aina paapaa ti la si ibalopọ, ibẹru ti ọkọ iya ẹ ti gbìn si i lọkan ko jẹ ko le ṣalaye iṣekuṣe ti oun pẹlu baba ẹ jọ n ṣe fun iya ẹ.

 

Ọmọọdun mẹtala yii ṣalaye fakọroyin wa pe, “oru ni wọn (ọkọ iya ẹ) maa n ba mi sun. Mi o si le sọ iye igba ti wọn ti ṣe e lati kekere ti mo ti n gbe pẹlu wọn. Lati igba ti mo ti de ni wọn ti n ṣe awọn alaye ti ko ye mi, aṣe wọn fẹẹ maa ba mi sun ni wọn ko mọ bi wọn ṣe maa sọ ọ.

 

“Mo n fọṣọ lọwọ lọjọ yẹn, awọn de lati ibi iṣẹ ni wọn sọ pe kinni kan n bẹ ti mo maa fun awọn, gbogbo nnkan ti mo ba si fẹ lawọn aa fun mi. Nnkan ti wọn n sọ yẹn ko waa ye mi. Nigba to waa di oru ọjọ yẹn, mi o mọ igba ti wọn bọ aṣọ ti wọn fi ba mi laṣepọ. Wọn maa n ba mi ṣe e ti mo ba ti sun, mi o waa ni i mọ igba ti wọn ba n ṣe e.

 

“Inu yara kan naa ni gbogbo wa n sun pẹlu ọmọ meji ti iya mi bi. Inu nẹẹti ni iya mi maa n sun ni tiwọn, wọn ki i si i mọgba ti wọn ba n ba mi laṣepọ. Mi o le ka iye igba ti wọn ti ṣe e. Mi o ki i pariwo nitori wọn ti sọ fun mi pe ti mo ba ti pariwo, nnkan ti oju mi ba ri ki n maa fara mọ ọn.

 

“OJ, iyẹn ọkọ iya mi, ti fun mi loyun bayii, oyun si ti di oṣu mẹta si mi lara. Mo fẹ ki wọn ba mi ṣẹ ẹ ni, nitori mo ṣi wa nileewe, iwe kin-in-ni ni mo wa nileewe girama, bẹẹ ni mi o ti i pari iṣẹ telọ ti mo n kọ lọwọ”.

 

***Aina ni ko mọ pe ewu wa ninu oyun ṣiṣẹ, iya ẹ to mọ bẹẹ ti sọ pe bi oun ati ọkọ oun ṣe maa mojuto ọmọ naa pẹlu oyun inu ẹ lo jẹ oun logun.

 

“ Ko ye emi naa bi ọkọ mi ṣe fun ọmọ mi loyun. Ti emi ba ti sun, mi o ki i mọ nnkan kan mọ. Latigba ti ọrọ yii ti ṣẹlẹ ni mo ti kuro nile ti a n gbe laduugbo Odinjo, ti mo ti wa lọdọ baba mi ni Oje (n’Ibadan). Mo fẹ ka jọ mọ ba a ṣe maa mojuto ọmọ to loyun atawọn keekeeke ti mo n tọju lọwọ”, bẹẹ lobinrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn yii sọ.

 

Ni ti Baba Ojo, Alagba Asimiyu Raimi, ẹni to ba ṣe ohun ti ẹni kan ko ṣe ri ni, dandan ni ki oju ẹ ri ohun tẹnikan o ri ri. Baba to n ṣiṣẹ ọdẹ naa faraya nigba to gbọ nipa iṣẹlẹ yii, afi bii ẹni pe oun gan-an lo bi Aina ti wọn fun loyun idojuti yii ni. Oun funra ẹ lo si fa ọmọ ẹ le awọn agbofinro lọwọ ni teṣan ọlọpaa to wa laduugbo Idi-Aro, n’Ibadan, o loun fẹ ki awọn agbofinro ti i mọle ko le kọgbọn.

 

Iwadii ALAROYE fidi ẹ mulẹ pe lọjọ kẹta ni wọn gba beeli ẹ kuro ninu ahamọ awọn ọlọpaa. Bẹẹ lafurasi ọdaran naa iba mu ọran yii jẹ bi ko ṣe pe awọn ajafẹtọọ-ọmọde kan ti wọn n pe ni Child Right Initiative gbọ si i lẹyin ti afurasi ọdaran yii kuro latimọle awọn agbofinro.

 

Nigba ti ọwọ oludari agba ajọ ọhun, Ọgbẹni Kẹhinde Akinyẹmi, tẹ Ojo, ko gbe e duro ni sakaani awọn ọlọpaaa mọ, ọdọ awọn ẹṣọ alaabo ilu, NSCDC ta a mọ si Sifu Difẹnsi lo gbe e lọ taara.

 

Gẹgẹ bi Ọgbẹni Akinyẹmi ṣe sọ, “a ti fi iṣẹlẹ yii to ẹka to n mojuto ọrọ awọn obinrin nileeṣẹ ijọba ipinlẹ Ọyọ leti lati ri i pe amojuto to peye wa fun ọmọbinrin yẹn ati oyun inu ẹ. Gbogbo igbesẹ to ba si yẹ ki ijọba gbe lati fiya to ba tọ si Ojo jẹ ẹ la fẹ ki wọn gbe, nitori pẹlu ohun to ṣe yii, o ti tẹ ẹtọ ọmọdebinrin yẹn loju, o si ti tapa si ofin orileede yii.

 

Oṣiṣẹ Sifu Difẹnsi to n ṣewadii ọran naa, Ọgbẹni Ọgbẹni Afẹ Olurotimi, sọ pe iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii, ati pe o ṣee ṣe ki awọn gbe afurasi ọdaran naa lọ si kootu ki ọsẹ yii too pari.

 

 

(24)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.