Kantankantan wo ni Faṣọla n sọ lẹnu yii

Spread the love

Awọn oloṣelu ko le ṣe ki wọn ma ṣe oṣelu, wọn ko si le ṣe ki wọn ma tan awọn eeyan wọn jẹ. Ohun to ba wọn jẹ ree, nitori ko si bi o ṣe le ni oloṣelu kan n ṣe daadaa lasiko ti a wa yii to, irọ ni yoo gbẹyin rẹ, yoo si pẹlu awọn ti wọn n tan araalu jẹ ni. Babatunde Raji Faṣọla to n ṣe minisita fun Buhari l’Abuja bayii ni dandan ni ka dibo fun Buhari nilẹ Yoruba, nitori ti a ba dibo fun un ni ijọba Naijiria yoo fi le pada sọwọ awọn Yoruba ni 2023. Ọrọ naa si da bii igba ti eeyan ba mu ọti yo, ti ọti ọhun gbodi, tabi to jẹ ọti lile to n pa a nipakupa. Ta lo sọ fun Faṣọla pe awọn Buhari yoo gbejọba fun Yoruba ni 2023, ninu iwe wo lo ti ka a jare. Ki lo ṣẹlẹ si awọn Ibo, ṣe awọn Ibo ko ni i ṣejọba ilẹ yii rara ni, Buhari tabi awọn Hausa yoo si wo sunsun, wọn yoo waa gbejọba fun Yoruba, lẹyin ti Ọbasanjọ ti ṣe tirẹ ni ọdun mẹjọ. O jọ pe lara awọn ti wọn n tan Aṣiwaju Bọla Tinubu jẹ ree, ti iyẹn fi n tẹle Buhari, to n purọ fun Yoruba pe ko si iru ọkunrin naa laye ati lọrun, to si mọ pe irọ loun n pa fun wa, nitori ẹtan pe yoo di aarẹ lọdun 2023 yii naa ni. Ki lo de ti Faṣọla ko fi ọrọ ibo ọdun 2023 silẹ, nigba ti ko sẹni to mọ iye awa ti a oo wa laye nigba naa, ati awọn ti wọn n ṣejọba, ati awa ti wọn n ṣe e fun. Ọrọ ti gbogbo aye n reti lẹnu rẹ ni idi to ṣe ṣoro foun lati pari ọna Eko si Ibadan, ọna marosẹ ti awọn Jonathan ti ṣe debi kan ki awọn too de rara. Lati igba ti Faṣọla ti di minisita, maili meloo ni wọn ti ṣe loju ọna yii o, ati kin ni idi ti ọna ti wọn fẹẹ fi ọdun kan si meji ṣe ko ṣe nilọsiwaju kan. Kin ni idi ti ọrọ ina NEPA ko ṣe yanju naa titi doni yii, awọn ohun wo ni Faṣọla si le tọka si pe awọn ti ṣe ninu ijọba yii to tẹ oun gan-an alara lọrun, bi a ba ti yọwọ ọrọ oṣelu kuro. Bo ba jẹ Faṣọla to ṣiṣẹ l’Ekoo ti gbogbo eeyan mọ ni, o daju pe ọna Eko si Ibadan yii yoo ti pari, bẹẹ ni ina ijọba yoo si ti wa kaakiri. Ṣugbọn ki lo waa de ti ko ṣe le ṣe awọn ohun to ṣe l’Ekoo daadaa lọdọ ijọba apapọ. Ohun to fa a ti ko fi le ṣe iṣẹ rẹ bo ṣe fẹẹ ṣe e gẹgẹ bii minisita naa ni ko ni i jẹ ko ṣee ṣe fun awọn ọga rẹ lati gbejọba fun Yoruba lọdun 2023, bi ọrọ naa ba ye e daadaa. Ko sẹni ti yoo dibo fun Buhari nilẹ Yoruba bi ko ba ṣe daadaa fun Yoruba, ki Faṣọla jokoo ẹ jẹẹ bi ko ba ni nnkan gidi ti yoo sọ. Abi iru kati-kati wo leleyii!

(39)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.