JUNE 12: Buhari fabuku kan Babangida pẹlu Ọbasanjọ

Spread the love

Nigba ti Ibrahim Babangida ṣaaju awọn Sani Abacha, Tunde Idiagbọn, atawọn ọga ṣọja mi-in, loṣu kejila, ọdun 1983, ti wọn gbajọba lọwọ Alaaji Shehu Shagari, ti wọn waa gbejọba naa fun Ọgagun Muhammadu Buhari lọjọ kin-in-ni oṣu kin-in-ni 1984, ti wọn si ni ki Tunde Idiagbọn ṣe igbakeji rẹ, ohun ti ọpọ araalu ro nigba naa ni pe ko le pẹ ti ijọba yoo fi pada sọwọ awọn oloṣelu, nitori ko too di igba naa, awọn ṣọja ti fi ọdun mẹtala ṣejọba. Ṣugbọn nigba ti ijọba bọ si ọwọ Buhari ati Idiagbọn, ko jọ pe wọn fi ọrọ awọn oloṣelu sọkan, tabi pe wọn gbero lati gbejọba fun wọn ni kiakia. Yatọ si eyi, ijọba ti wọn n ṣe nigba naa le koko mọ araalu, eyi to si fa a ti ijọba naa ko fi lo ju ọdun kan ati oṣu diẹ lọ. Ni ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun 1985, Ọgagun Babangida gbajọba Naijiria kuro lọwọ Buhari, oun si di olori ijọba tuntun naa.

Ohun to mu ki awọn eeyan sare gba ti Babangida ni pe gbogbo awọn ti Buhari ati Idiagbọn ju sẹwọn lo ni ki wọn maa ṣi silẹ, bẹẹ lo si dajọ fawọn oloṣelu pe bi oun ti gbajọba lọdun 1985 nni, eto oṣelu yoo bẹrẹ laipẹ, ṣugbọn lọdun 1990 loun yoo da ijọba pada fun awọn oloṣelu, ti wọn yoo si tun maa ṣejọba orilẹ-ede wọn lọ. Eleyii dun mọ awọn oloṣelu ati awọn araalu ninu, nitori nigba naa, awọn orilẹ-ede to laju lagbaaye ti n kuro ninu ijọba ologun, awọn orilẹ-ede ti ko laju daadaa nikan lo ku nidii ẹ, oju ọlaju ati alagbara ni wọn si fi n wo Naijiria, iyẹn lo ṣe jẹ pe ikede ti Babangida ṣe paapaa, inu awọn oyinbo dun si i. Ko si fi ọrọ naa falẹ o, nitori ọdun 1988 ni wọn ti bẹrẹ eto oṣelu naa, ti wọn gbe ilana rẹ kalẹ, ti wọn si sọ fawọn oloṣelu ki wọn maa da ẹgbẹ oṣelu wọn silẹ.

Ṣugbọn gbogbo ẹgbẹ oṣelu oriṣiiriṣii ti wọn gbe kalẹ nigba naa ko tẹ ijọba lọrun, nijọba ba fagile gbogbo wọn lọjọ kan, lẹyin naa ni wọn da ẹgbẹ oṣelu meji pere silẹ, wọn pe ọkan ni National Republican Convention (NRC), wọn si pe ekeji ni Social Democratic Party of Nigeria (SDP). Nigba naa ni wọn fi Tom Ikimi ṣe alaga NRC, wọn si fi Baba Gana Kingibe ṣe ti SDP. Awọn ẹgbẹ mejeeji ni wọn ni awọn ero rẹpẹtẹ lẹyin, nigba to si di asiko lati du ipo aarẹ, kaluku ko awọn eeyan nla nla jade lati di aarẹ Naijiria. Ninu oṣu kẹjọ, 1992, ni wọn fi ibo abẹle si lati yan ẹni ti yoo du ipo aarẹ lorukọ NRC, awọn eeyan mẹtalelogun ni wọn si jade. Ninu wọn ni Adamu Ciroma, Umaru Shinkafi, Bamanga Tukur, Lema Jubrila, Alhaji Saleh, Alhaji Sambo, Alhaji Inna Wanna, Shehu Musa ati Emmanuel Iwuanyanwu.

Ti ẹgbẹ oṣelu SDP lo ju bẹẹ lọ. Ogoji lawọn. Awọn ti wọn lorukọ ninu wọn ni Oluṣọla Saraki, Shehu Musa Yaradua, Olu Falae, Muhammed Waziri, Lateef Jakande, Jerry Gana, Layi Balogun, Arthur Nzeribe, Datti Ahmed, Abel Ubeku, **Biyi Durojaye ati obinrin kan ṣoṣo to wa ninu wọn, Sarah Jubril. Ṣugbọn lẹyin ti ati ẹgbẹ NRC ati SDP dibo abẹle wọn tan, ariwo ojooro le debii pe ibo naa ko ṣee gba wọle. Ni wọn ba ni awọn meji lo ṣe ju ninu ẹgbẹ kọọkan, awọn meji yii ni wọn yoo tun ibo naa di, ti wọn yoo le mu ẹni kan ninu wọn. Ninu ẹgbẹ NRC, Adamu Ciroma ati Umaru Shinkafi lo lero ju, awọn meji naa ni wọn si ni ki wọn jọ koju ara wọn. Ni ti SDP, Shehu Musa Yaradua ati Olu Falae lo lero ju, awọn mejeeji naa si ni wọn ni wọn yoo jọ fa a, ti wọn yoo le pada waa yan ẹni kan ninu wọn.

Amọ ko too di ọjọ idibo mi-in, Babangida fagile gbogbo ibo ti awọn eeyan yii di ninu oṣu kẹwaa, 1992 yii, bẹẹ lo si fofin de gbogbo awọn ti wọn kopa ninu rẹ pata, o ni wọn ko le kopa ninu eto idibo naa mọ, wọn ko le du ipo kankan paapaa, ki wọn lọọ wa iṣẹ mi-in ṣe. Ọrọ naa jo awọn eeyan bii Yaradua ati Falae lara, ati Ciroma pẹlu Shinkafi, nitori awọn yii ti nawo si ọrọ ibo naa kọja wẹrẹwẹrẹ. Ṣugbọn ko si ohun ti wọn yoo ṣe, ijọba ti gbegile e, wọn gbegile e naa niyẹn. Nigba naa ni iyan di atungun, ọbẹ di atunse, lawọn ẹgbẹ oṣelu mejeeji ba tun sare wa ẹni ti yoo du ipo aarẹ lorukọ wọn. Bi ẹgbẹ SDP ti n wa, bẹẹ ni NRC n wa. Yaradua ko jẹ ki ọrọ naa le ju foun, o sare fa ọkan ninu awọn ọmọ ẹyin rẹ, Atiku Abubakar, kalẹ, o ni ko lọọ dupo aarẹ, ṣugbọn Baba Gana Kingibe to jẹ alaga ẹgbẹ naa tẹlẹ ni oun ni ipo naa tọ si.

Awọn Shinkafi ati Ciroma jokoo, awọn si ronu tiwọn wo, wọn ni awọn ko ni i lọ jinna, awọn ko si le fi NRC silẹ ko ma wọle, ni wọn ba mu Bashir Tofa, wọn ni ko tete bẹrẹ iṣẹ, nitori ko sẹni to fi bẹẹ mọ ọn ju pe o ti figba kan jẹ akọwe owo fun ẹgbẹ NPN laye awọn Shagari lọ. Asiko naa lawọn eeyan bẹrẹ si i yọ MKO Abiọla lẹnu, paapaa lati ilẹ Yoruba, wọn ni awọn mọ pe bi SDP yoo ba wọle, afi ki awọn fa eeyan gidi kalẹ, eeyan ti awọn si mọ pe o le ṣe kinni naa fawọn ni Abiọla, ẹni ti ki i ṣe ni Naijiria nikan ni wọn ti mọ ọn, to jẹ kari-aye ni, nitori oore to n ṣe fun gbogbo eeyan. Abiọla gbọn ju bẹẹ lọ. Iroyin ati ariwo to n lọ nigboro nigba naa ni pe Babangida ko fẹẹ gbejọba silẹ ni. Koda, ọkunrin kan ninu awọn ti wọn fagile orukọ wọn, Arthur Nzeribe, ti da ẹgbẹ kan silẹ lojiji, o ni ẹgbẹ ki Babangida ma lọ mọ ni.

Nitori bẹẹ ni Abiọla ṣe lọọ ba ọrẹ rẹ, iyẹn Babangida. Ọrẹ gidi ni wọn, ọrẹ naa si ti lọjọ lori gan-an, lati igba ti Babangida ko ti jẹ nnkan gidi kan ninu iṣẹ ologun, to jẹ ọmọ lẹyin fun awọn Muritala Muhammed, nitori Muhammed yii gan-an lọrẹ Abiọla. Ọrẹ naa le debii pe bi Babangida ba lọ siluu oyinbo, ile Abiọla ni yoo wa titi lati ṣe gbogbo ohun to fẹẹ ṣe, bẹẹ ni ko si bi kinni kan ti le kere to ti Abiọla ba n ṣe nile rẹ ti Babangida ko ni i lọ. Lọjọ ti Zimbiat Abiọla ku ni 1992, Babangida lo da bii baba-isinku, oun lo jokoo ti Abiọla, to n rọ ọ ko ma ronu mọ, to si n sọ fawọn eeyan ohun ti wọn yoo ṣe. Nigba ti Babangida pe ọmọ aadọta ọdun ni 1991, Abiọla lo ko awọn alaafaa jọ, ti gbogbo wọn si wa ni Gbagede Tafawa Balewa, ti wọn ṣe akanṣe adura fun un. Nidii eyi, Abiọla ni oun ko le du ipo aarẹ laisọ fọrẹẹ oun.

Bi Babangida ti gbọ pe Abiọla yoo du ipo aarẹ ni inu rẹ dun, o si sọ pe gbogbo ohun to ba yẹ loun naa yoo fi ṣe atilẹyin fun un. Bi Abiọla ti gbọ bẹẹ lo bẹ jade, o si wọ inu ẹgbẹ SDP, nipolongo ba bẹrẹ pẹrẹwu. Kingibe naa jade, Atiku naa jade, ṣugbọn nigbẹyin, niluu Jos, lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹta, 1993, awọn aṣoju SDP fa MKO Abiọla kalẹ pe ko dupo aarẹ lorukọ wọn. Bẹẹ naa lawọn NRC ṣe fun Bashir Tofa lọjọ yii kan naa. Bayii ni eto bẹrẹ, ti ipolongo n lọ loju mejeeji titi di ọjọ ti wọn fi eto idibo naa si, iyẹn ọjọ kejila, oṣu kẹfa (June 12), ọdun 1993. Awọn eeyan ti ro pe iru nnkan bẹẹ ko dara ninu oṣu Juunu (June) pe ojo le ba ohun ti awọn fẹẹ ṣe jẹ. Ṣugbọn Ọlọrun da bii pe o ya ọjọ naa sọtọ, ojo kan ko rọ lati aarọ titi ti wọn fi dibo naa tan, lati ile idibo lọjọ naa si lawọn eeyan ti mọ pe MKO Abiọla ti wọle.

Ṣugbọn ko too di ọjọ idibo yii lawọn eeyan kan ti n gbọ pe wahala le ṣẹlẹ o, wọn ti n gbọ pe bi Abiọla ba wọle ibo, wọn le ma gbejọba fun un. Ohun to fa a ti awọn eeyan yii fi n sọ bẹẹ ni pe Babangida ati awọn eeyan rẹ ti gbọ gẹgẹ bii iwadii ti wọn ṣe kaakiri ilu pe Abiọla lawọn eeyan rẹ dibo fun o. Nigba ti ọrọ naa yoo si fi ara jọ ootọ, obinrin adajọ kan, Adajọ Bassey Ikpeme, dajọ ni aago mewaa alẹ ọjọ kẹwaa, oṣu kejila, yii pe wọn ko gbọdọ dibo kankan lọjọ naa, bi wọn ba dibo kan, ibo naa ko ni i ba ofin mu. Ẹgbẹ ti Arthur Nzeribe da silẹ ti a mẹnuba, ‘Asssociation for Better Nigeria’ (ABN), lo pe ẹjọ naa, inu wọn si dun nigba ti wọn gbegi le ibo naa. Ṣugbọn awọn Abiọla ati gbogbo aye tẹnubọ ọrọ naa pe nibo ni wọn ti n ṣe eyi ti wọn ṣe yii, ati pe ṣe loootọ ni Babangida ko fẹẹ lọ ni? Nijọba apapọ ba sọ pe ki INEC ma dahun, ki wọn maa ṣeto ibo tiwọn lọ.

Amọ o, ni gbara ti ‘National Electoral Commission’ (NEC), to n ṣeto ibo naa bẹrẹ si i ka ibo, ti wọn si ka a de ori ipinlẹ mẹrinla, ti gbogbo rẹ si han pe Abiọla ati Kingibe lo n wọle, lojiji lawọn ṣọja de, ni wọn gbe alaga NEC, Ọjọgbọn Humphery Nwozu, lọ. Nigba to si pada de lati ibi ti wọn mu un lọ, kan-un kan-un lo ku to n sọ, awọn kan sọ pe awọn ṣọja lo lu u nilukulu bẹẹ. Ni ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kejila yii, naa ile-ẹjọ mi-in ni Abuja tun dajọ pe NEC to ṣeto ibo naa ko gbọdọ kede esi ibo ọhun mọ rara. Ki la o ti ṣe eyi si lawọn eeyan n sọ, afi nigba to di ọjọ kọkanlelogun, oṣu kejila, yẹn naa ti adajọ mi-in tun dajọ pe ibo naa ko lẹsẹ nilẹ rara, nitori ibo ti ko bofin mu ni. NEC ati Nwozu naa pe ẹjọ tiwọn, adajọ kan si n mura lati dajọ naa ni Kaduna lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹfa.

Ijọba ko jẹ ki ọjọ naa pe o, nitori nigba to di ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹfa, ọdun 1993, Ibrahim Babangida funra rẹ jade, o ni awọn ti fagile eto idibo naa nitori awọn adajọ ti wọn n ja laarin ara wọn. N lọrọ ba di rannto. Gbogbo aye binu, wọn si bẹrẹ si i sọrọ ṣakaṣaka si Babangida. Ọkunrin ṣọja naa pe awọn olori ẹgbẹ oṣelu mejeeji jọ, Tony Anenih ati Ahmed Kusamotu, o ni ki wọn lọọ maa ṣeto idibo mi-in, nitori awọn ti fagile eyi ti wọn ṣe kọja. O ni wọn gbọdọ ṣeto naa ki wọn si dibo, nitori awọn yoo gbejọba silẹ nijọ ti wọn ti da gan-an. Ṣugbọn awọn yẹn ni ko ṣee ṣe, ko si bi awọn ṣe tun le ṣeto ibo laarin oṣu meji pere, nibo ni wọn ti n ṣe iru ẹ. Awọn ṣọja bii Joshua Dongoyaro, John Shagaya, Aliyu Muhammed, David Mark, Anthony Ukpo, Chris Garuba, Abdulmumini Aminu, Lawan Gwadabe, John Madaki, awọn ti wọn pe ara wọn lọmọ Babangida ninu ṣọja rogba yi i ka, wọn ni ko le gbejọba silẹ f’Abiọla.

Abiọla lọ si ọdọ Babangida ọrẹ rẹ, ṣugbọn ọrọ to sọ fun un ko lori, ko nidii, ohun to n sọ ni pe awọn ṣọja kan fẹẹ pa oun, wọn ni bi oun ba fi le gbejọba silẹ, awọn yoo pa oun, ẹru si n ba oun nitori ti wọn ba pa oun Babangida, wọn yoo pa Abiọla naa tile-tile. Abiọla figboya sọ fun un pe ko sẹni ti yoo pa a, ko jẹ ki wọn kede esi idibo naa. Nigba to ya ni olobo ta Abiọla pe wọn fẹẹ pa a, n lo ba tẹkọ leti laidagbere fẹnikan, o sa lọ siluu oyinbo lojiji. Ọrọ naa ko ṣee ṣe fun Babangida mọ, gbogbo ohun to ba si ni lero ko gba a. Ọrọ tirẹ naa ti di ile ko gba a, ọna ko gba a, ti i ṣe ewe aragba, ohun gbogbo lo n bọ si lodilodi fun un. Nigba naa lo ronu kan Ernest Shonẹkan. Ṣe ni 1992 ti wọn ni ọkunrin naa jade, to sọ pe ki ijọba oloṣelu le maa mọ awọn eeyan lara, oun ni yoo maa ṣe olori ijọba, to si yan awọn minista sabẹ rẹ.

Ṣonẹkan yii ni Babangida gbe ijọba fun lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹjọ, ọdun 1993, loun ba fitiju gba ile rẹ lọ. Bo tilẹ jẹ pe awọn ṣọja to fi silẹ yii kan dannu fun Ṣonẹkan, ohun to si ṣẹlẹ ni idajọ kan ti Adajọ Dọlapọ Akinsanya da lọjọ***** .. to fi sọ pe ijọba fidi-hẹẹ ti Ṣonẹkan n ṣe olori rẹ, ijọba ti ko bofin mu ni. Ṣe nigba naa, oun naa ti n ṣe bii olori orilẹ-ede tootọ, bo ti le jẹ pe ko sẹni to dibo fun un. Nigba naa, awọn ajijagbara loriṣiiriṣii ti dide, Gani Fawẹhinmi si ti bọ sigboro pẹlu awọn lọọya mi-in bii Alao Aka Baṣọrun, Olu Ọnagoruwa, ati awọn mi-in ti wọn ko si nijọba, wọn ni ijọba Shonẹkan yii ko ye awọn. Awọn Abacha naa ti n wo ijọba Shonẹkan yii horohoro, wọn n wo ibi ti wọn yoo gba mu un. Lojiji ni wọn le e danu, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 1993, ni. Ni Sanni Abacha ba di olori ijọba.

Ohun ti gbogbo eeyan n ro ni pe Sanni Abacha ko fẹran ohun ti Babangida n ṣe, pe ọkunrin naa fẹran dẹmokiresi, o si ti kilọ fun Babangida pe ko gbejọba fẹni to ba wọle. Eyi ni Abiọla paapa naa gbọ, nigba to si tun waa mu Ọladiipọ Diya gẹgẹ bii igbakeji rẹ, awọn eeyan ni ọrọ ti pari. Iyẹn ni wọn ṣe ranṣẹ si Abiọla pe ko maa bọ, ṣugbọn nigba ti Abiọla de, nnkan mi-in ni Abacha n sọ. Nigba ti Abiọla jokoo bii ọdun kan ti ko si kinni kan lo ba binu, lo ba sọ fun gbogbo aye pe ẹlẹtan ni Abacha, o kan n tan oun lasan ni, o n jẹ nibi ti ko ti gbin. O ni asiko ti to ti oun ko ni i gba mọ, nitori awọn gbọdọ ṣe ayẹyẹ ‘June 12’, ki oun si gbajọba oun. Ni June 11, lọdun 1994, Abiọla lọ si ibi kan ni Ẹpẹtẹdo, l’Ekoo, o si kede ara rẹ bii aarẹ Naijiria tootọ. Ẹgbẹ NADECO ti bẹrẹ nigba naa, Adekunle Ajasin lolori wọn, wọn si lọ si ibi ikede to ṣe.

Awọn ṣọja ati ọlọpaa bẹrẹ si i wa Abiọla kiri, wọn ko ri i mu titi di ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹfa, ọdun naa, to jade sita. Ṣugbọn ni alẹ ọjọ naa, awọn ọlọpaa bii ẹgbẹta (600) lọ si ile rẹ ni Ikẹja, wọn si mu un, ni wọn ba gbe e lo si Abuja, ibẹ lo si ba de ọgba ẹwọn tẹnikan ko mọ ibẹ. Bẹẹ ni wọn ti Abiọla mọle, Abacha si bẹrẹ ijọba lile gan-an. Gbogbo ẹni to ba ti sọrọ lori ‘June 12’, ẹwọn lo n lọ, tabi ki wọn pa a.

Nijọ kẹrin, loṣu kẹfa, ọdun 1996, awọn ọmọ Abacha yinbọn pa iyawo Abiọla, Kudirat, ẹni ti o n ja fun ọrọ yii lati igba ti ọkọ rẹ ti wa nitimọle. Bẹẹ naa ni wọn yinbọn pa Alfred Rewane, wọn si ju bọmbu lu awọn mi-in. Ẹwọn kun nigba naa gan-an ni o, wọn mu awọn bii Bọla Ige, Gani Fawẹhinmi, Bẹkọ Ransome Kuti, Biyi Durojaye, Ayọ Ọpadokun, Federick Faṣeun, atawọn mi-in bẹẹ, wọn la wọn mẹwọn nilẹ Hausa.

Niṣe lawọn eeyan bii Adekunle Ajaṣin, Abraham Adesanya, Ganiyu Dawodu, Ṣolankẹ Ọnasanya ati awọn mi-in bii tiwọn n lọ sẹwọn ti wọn n pada, itimọle wọn ko si lonka. Lori ọrọ naa si ni Adekunle Ajaṣin ku si. Awọn ti wọn ribi sa lọ ti tu danu: awọn bii Alani Akinrinade, Wọle Ṣoyinka, Cornelius Adebayọ, Bọla Tinubu, Amos Akingbade, Bọlaji Akinyẹmi, ati awọn mi-in bẹẹ.  Asiko naa ni Abacha sọ pe awọn Oluṣẹgun Ọbasanjọ fẹẹ gbajọba lọwọ oun, lo ba mu un ati igbakeji rẹ, Musa Yar’adua, wọn dajọ iku fun wọn. Ṣugbọn o ni aanu wọn ṣe oun, lo ba ju wọn sẹwọn gbere. Ko pẹ lẹyin naa lo ti igbakeji rẹ mọle, iyẹn Ọladipupọ Diya, o lo pẹlu awọn bii Abdulkareem Adisa, Tajudeen  Ọlanrewaju ati awọn mi-in ti wọn fẹẹ gbajọba lọwọ oun. Ẹjọ iku lo si da fun wọn. Ṣugbọn ọjọ ti wọn yoo pa awọn eeyan naa ko ti i pe nigba ti oun Abacha funra rẹ fo sanlẹ lojiji, to ku, ori aṣẹwo ni wọn si sọ pe o ku si.

N lawọn eeyan ba n yọ, ni wọn n jo, paapaa nigba ti ṣọja mi-in, Abdul Salami Abubakar, ti gbajọba, to si bẹrẹ si i ṣi awọn ti wọn ti wa lọgba ẹwọn silẹ. Awọn eeyan n reti pe wọn yoo fi Abiọla silẹ ko jade, afi bo ṣe di oṣu kan geere ti Abacha ku, ti awọn eeyan deede gbọ iku Abiọla lojiji, lẹyin ti awọn oyinbo kan ni awọn waa ba a sọrọ, o si mu tii loju awọn. Abacha ku ni ọjọ kẹjọ, oṣu kẹfa, ọdun 1998, Abiọla si ku ni ọjọ keje, loṣu keje, ọdun naa. Iku rẹ di wahala rẹpẹtẹ. Eyi ko jẹ ki Abdusalami pẹ lori oye, kia lo ti ronu lati gbe ijọba silẹ fawọn alagbada. Ṣugbọn awọn eeyan agbaye mọ pe irẹjẹ buruku leleyii jẹ fun Yoruba, iyẹn ni wọn ṣe wa ọmọ Yoruba mi-in ti wọn yoo gbejọba fun. Idi ti wọn fi yọ Ọbasanjọ kuro lẹwọn ree, lẹyin ti wọn si dibo, wọn loun lo wọle.

Ṣugbọn ni gbogbo igba ti Ọbasanjọ fi ṣejọba fun ọdun mẹjọ, ko ranti Abiọla fun ọjọ kan bayii, bẹẹ ni ko si ṣe ohunkohun lati fi sọ pe ohun ti wọn ṣe fun ọkunrin naa ati fun iran Yoruba ko dara. Babangida naa ti ro pe oun ti ṣe kinni naa gbe ni, afi lojiji ti Aarẹ Muhammadu Buhari kede ‘June 12’ bii ọjọ ijọba awa-ara-wa (Democracy Day), to si fi oye to ga julọ nile yii da Abiọla lọla. Niṣe lawọn eeyan n sọ kiri pe abuku gidi ni Buhari fi kan Ọbasanjọ ati Babangida yii, ati pe titi aye ni itiju naa yoo maa wa lara wọn.

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.