Jẹlili to fipa ba iya arugbo lo po n’Ikeja, yoo foju bale-ejo

Spread the love

Ọjọ ọdun tuntun, iyẹn ọjọ kin-in-ni, oṣu yii ni aṣiri ọkunrin dirẹba kan, Jẹlili Lawal, ẹni ọdun mọkanlelogoji, tu sita, nibi to ti n fipa ko ibasun fun iya arugbo kan, ẹni ọdun mejidinlọgọrin laduugbo Adeniji Jones, ni Ikẹja.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ṣalaye pe mama naa, ẹni ti wọn forukọ bo laṣiiri, n beere ọna lọwọ awọn eeyan laduugbo Ketu pe ki wọn juwe bi oun aa ṣe de Maryland, ni Ikẹja, fun oun ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ.

Niṣe ni wọn ni Jẹlili sọ fun iya pe ko ma ṣeyọnu, oun aa gbe e pẹlu ọkọ bọọsi akero oun debẹ lọfẹẹ. Iya naa gba, o si dupẹ lọwọ Jẹlili, lai mọ pe ẹruuku naa lohun mi-in lọkan to fẹẹ ṣe. Lojiji ni wọn ni ọkunrin naa yi ori ọkọ pada, o si mori le abule Oloti, to wa lagbegbe Adeniji Jones, nibi ti wọn lo ti ko ibasun fun mama naa.

Ariwo ti mama yii pa lo ta si awọn araadugbo yii leti, awọn ni wọn si mu ọkunrin naa silẹ de ọlọpaa.

Kọmisanna ọlọpaa, Imohimi Edgal, ṣalaye pe nigba ti awọn agbofinro fi maa debẹ, mama naa ti n ṣẹjẹ loju ara latari ibasun ipa ti Jẹlili ko fun un.

Lẹsẹkẹsẹ lo ni wọn gbe mama lọ si ọsibitu, nibi ti wọn ti ṣetọju rẹ, ti wọn si taari Jẹlili lọ si teṣan.

Iwadii awọn ọlọpaa fihan pe akisa ni ọkunrin yii fi bo ẹnu mama naa ko ma baa pariwo. Ṣugbọn ọkunrin naa sọ pe akoba lasan ni wọn fi ọrọ yii ṣe foun. O ni ọrẹ iyawo oun kan to ri oun ni ko farabalẹ wo nnkan toun n ṣe to fi pariwo, ariwo naa lo si di wahala soun lọrun yii.

Ṣa, Edgal ti ṣeleri pe oun yoo tẹle Jelili de kootu, nibi ti yoo ti le ṣalaye bi gbogbo ọrọ ṣe ṣẹlẹ daadaa fun adajọ, ti wọn yoo si ba awọn ṣe idajọ to yẹ lori ọrọ rẹ.

 

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.