Iyọnipo awọn alaga kansu: Iwadii ijinlẹ la fẹẹ ṣe—awon asofin Kootu ni yoo pari ija wa—PDP

Spread the love

Bi ile igbimọ aṣofin Ekiti ṣe sọ pe kawọn alaga kansu mẹrindinlogun to wa nipinlẹ naa lọọ sinmi nile ki iwadii ijinlẹ le waye lori awọn ẹsun ti wọn fi kan wọn, ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP), ti sọ pe ile-ẹjọ ni yoo pari ọrọ naa ti wọn ko ba yi ipinnu wọn pada.

 

Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja nile igbimọ aṣofin ṣepade, ti wọn si sọ pe kawọn alaga kansu ati gbogbo kansẹlọ wọọdu lọọ sinmi nile, ki wọn ma baa pakuta si iwadii tawọn fẹẹ ṣe lori awọn ẹsun ipaṣipayọ owo, ṣiṣe awọn iṣẹ akanṣe lọna ti ko ba ofin mu atawọn iwa mi-in ti wọn fi kan wọn.

 

Nigba to n sọrọ lorukọ gbogbo ile ati Ọnarebu Adeniran Alagbada to jẹ abẹnugan, Ọnarebu Gboyega Aribiṣogan ti i ṣe adari igbimọ iroyin ati eto ijọba ṣalaye pe ile naa gbe igbimọ kan dide lati ṣayẹwo bi awọn kansu ṣe na owo, wọn si ri awọn ẹri kan. O ni ṣe lawọn alaga yii ṣe awọn iṣẹ akanṣe ti ko yẹ ki wọn ṣe funra wọn lọna ati ṣe ipaṣipayọ owo, bẹẹ ni wọn tun gbe awọn iṣẹ naa fawọn eeyan wọn.

 

Bakan naa lo ni wọn lo awọn oṣiṣẹ abẹle lati ṣe awọn iṣẹ wọnyi, eyi to tako aṣẹ ti wọn gba, ki wọn si le dari owo to ku sibomi-in ni wọn ṣe huwa yii.

 

O sọ ọ di mimọ pe awọn oluṣiro-owo agba ijọba ibilẹ kọọkan gbọdọ bẹrẹ iwadii ijinlẹ, ninu eyi ti wọn yoo ti lo awọn ẹrọ ati irinṣẹ igbalode lati tana wadii bi awọn alaga naa ṣe na owo.

 

Igbesẹ yii ni Aribiṣọgan sọ pe o ba ofin abala keje ofin ilẹ Naijiria ati abala kejilelọgọrin (82), iwe ilana ile igbimọ aṣofin Ekiti mu, eyi si fun ile naa laṣẹ lati ṣewadii ẹnikẹni. O ni awọn ko le awọn alaga yii, nitori wọn dibo yan wọn ni, ṣugbọn ko sẹni to le wa nipo ko ma wa ọna ti yoo fi yọ ara rẹ ninu ẹsun ti wọn ba fi kan an.

 

Bakan naa lo ni ko si ootọ ninu pe awọn beere tabi gba ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta (500,000), Naira lọwọ awọn alaga wọnyi lasiko iwadii, tabi pe awọn fẹẹ wọ wọn wọ inu ẹgbẹ All Progressives Congress (APC).

 

Igbesẹ yii ni ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP), ti sọ pe ko ba ofin mu rara, wọn ni awọn yoo gba ile-ẹjọ lọ ti wọn ko ba pe awọn alaga yii pada.

 

Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ, Amofin Gboyega Oguntuwaṣe to jẹ alaga PDP l’Ekiti sọ pe APC ati gomina fẹẹ kọju ija si ilana ofin ni, idi niyi to fi lo awọn aṣofin naa lati le awọn alaga kansu, bẹẹ laipẹ yii nile-ẹjọ to ga julọ nilẹ yii sọ pe kawọn gomina yee le awọn alaga kansu.

 

Oguntuwaṣe waa sọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ PDP to laamilaaka ni wọn ti le kuro nipo yii, ẹgbẹ naa ko ni i maa woran, ile-ẹjọ ni yoo pari ọrọ naa.

 

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kejila, ọdun 2017, lawọn alaga yii de ọfiisi lẹyin ti wọn jawe olubori ninu idibo ijọba ibilẹ mẹrẹẹrindinlogun to wa nipinlẹ Ekiti.

 

 

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.