Iyẹn ni pe Sai Baba mọ pe ọpọlọ awọn yii o ṣiṣẹ

Spread the love

Aarẹ Muhammadu Buhari sọ lọsẹ to kọja yii pe bi wọn ti n paayan kiri ni awọn ipinlẹ gbogbo ni Naijiria yii, ti awọn Fulani onimaaluu si ti di apamọlẹkunjaye ti wọn n kaakiri ilu, awọn olori ologun oun wa nibi kan ti wọn jokoo, ti wọn n ha agbari wọn, ti wọn si jọ n fọwọ gba ọpọlọ wọn pẹpẹ lati mọ ohun ti wọn yoo ṣe si iṣoro naa. O ni nigba ti wọn ba pe ọpọlọ naa wale, ti awọn ọpọlọ wọn yii bẹrẹ iṣẹ, nigba naa ni wọn yoo mọ bi wọn yoo ti koju awọn ọmọ apaayan yii, ọrọ wọn yoo si yanju pata. Ohun ti eeyan ko waa mọ ni iye ọdun ti awọn eeyan yii yoo fi fọwọ gba ọpọlọ wọn titi ti yoo fi tun bẹrẹ iṣẹ pada, tabi iye akoko ti wọn yoo fi jokoo si kọrọ ti wọn yoo maa ronu titi ti wọn yoo fi mọ ohun ti wọn yoo ṣe si ọrọ awọn Fulani ti wọn n paayan kiri. Nitori bi a ma ti n sọrọ yii, eeyan tawọn Fulani yii pa ni Taraba ma tun le ni aadọta. Bo tilẹ jẹ pe awọn ọlọpaa jade pe eeyan ti wọn pa nibẹ ko to bẹẹ, ko sẹni kan ti yoo gba wọn gbọ nitori bi awọn ti n purọ faraalu lojoojumọ ti iru iṣẹlẹ bayii ba ti ṣẹlẹ niyẹn. Bo ba jẹ wọn n sọ ootọ tẹlẹ ni, araalu yoo gba wọn gbọ, ṣugbọn awọn eeyan ti mọ pe irọ ni wọn yoo pa fawọn bo ba ti di ọrọ pe oku ku bayii, nitori bẹẹ ni wọn ko si ṣe n ka ọrọ wọn si. Wọn leeyan mẹtadinlogun lawọn Fulani pa, ṣugbọn awọn araalu ni o le ni aadọrin ti wọn pa. Eyi o tiẹ waa wu ko jẹ, awọn ti wọn n fi ojoojumọ ku ni Naijiria yii ki i ṣe ẹran, eeyan ni wọn. Bi wọn si ti n paayan yii, awọn olori ologun wa ko ri nnkan kan ṣe si i. Iyẹn ni inu awọn ti wọn gbọ ọrọ ti Aarẹ Buhari sọ funra rẹ yii ṣe dun, pe awọn eeyan naa n fọwọ gba ara wọn lori ki ọpọlọ wọn le ṣiṣẹ daadaa. O han gbangba pe Buhari mọ pe ọpọlọ awọn eeyan naa ni ko ṣiṣẹ to, iyẹn ni wọn ko ṣe mọ ohun ti wọn yoo ṣe si ọrọ awọn Fulani apaayan. Ṣugbọn diẹ lọwọ ole, diẹ lọwọ oni-nnkan ni o. Bi Buhari ba mọ pe ọpọlọ wọn ko ṣiṣẹ, ki lo ko wọn sibẹ si, ki lo de ti ko yọ wọn kuro nipo naa ko fi awọn to ba mọ pe ọpọlọ wọn pe si i. Ati pe o, iru aṣẹ wo gan-an ni Buhari gẹgẹ bii Aarẹ Naijiira pa fun awọn olori ologun yii. Ṣe o ṣe ofin ki wọn pa Fulani to ba paayan ni abi o ni ki wọn kan mu wọn ki wọn ti wọn mọle, ki wọn maa waa wadii ọrọ ti ko ni itumọ kiri titi ti wọn yoo fi tun fi awọn yẹn silẹ. Ṣe Buhari paṣẹ fun wọn pe ki wọn pa Fulani to ba paayan! Kin ni Buhari sọ fawọn to ni ọpọlọ wọn ko ṣiṣẹ yii gan-an! Ọrọ naa wa lọwọ Buhari ju awọn olori ologun rẹ lọ. Ọwọ Buhari ni gbogbo ọrọ wa. Buhari laraalu dibo fun, Buhari lolori ijọba, ohun to ba fẹ ni gbogbo eeyan yoo ṣe. Oun ni ko gba wa lọwọ awọn Fulani apaayan, ko yee fiwa rubọ fun wọn. Họwu, ko sẹni ti ko mọ ọgbọn ka fi ẹran sẹnu ka wa a ti, ẹ yee purọ fun wa mọ jare!

(47)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.